A Ò Ní Wẹ̀yìn
Wà á jáde:
1. Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́
Nípa Jèhófà àti ayé tuntun,
Ó wọ̀ mí lọ́kàn, ó múnú mi dùn.
Àmọ́ kò rọrùn láti ṣohun tó tọ́.
(ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)
Mo ti pinnu pé
Ohun tó tọ́ ni màá ṣe.
(ÈGBÈ)
Mo fẹ́ kígbàgbọ́ mi máa lágbára sí i
Kí n lè máa ṣèfẹ́ Ọlọ́run.
Màá fi Bíbélì ṣe atọ́nà mi,
Màá sì tẹra mọ́ àdúrà.
Mo gbẹ́kẹ̀ lé Bàbá; mi ò ní wẹ̀yìn.
2. Àwa ti pinnu lọ́kàn wa pé,
Ìfẹ́ Jèhófà la ó fayé wa ṣe.
Àmọ́ aráyé ń ṣe bó ṣe wù wọ́n;
Àfi ká máa ṣọ́ra ká má dà bíi wọn.
(ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)
A mọ òtítọ́,
A sì ní ìrètí.
(ÈGBÈ)
Ká jẹ́ kígbàgbọ́ wa máa lágbára sí i
Ká lè máa ṣèfẹ́ Ọlọ́run.
Ká fi Bíbélì ṣe atọ́nà wa,
Ká sì tẹra mọ́ àdúrà.
A gbẹ́kẹ̀ lé Bàbá; a ò ní wẹ̀yìn.
(ÈGBÈ)
Ká jẹ́ kígbàgbọ́ wa máa lágbára sí i
Ká lè máa ṣèfẹ́ Ọlọ́run.
Ká fi Bíbélì ṣe atọ́nà wa,
Ká sì tẹra mọ́ àdúrà.
A gbẹ́kẹ̀ lé Bàbá; a ò ní wẹ̀yìn.
A ò ní wẹ̀yìn;
A ò ní wẹ̀yìn!