Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Wà Níṣọ̀kan

A Wà Níṣọ̀kan

Wà á jáde:

  1. 1. Ọjọ́ pẹ́ táwọn ọ̀tá

    Ti ń ṣe àtakò sí wa.

    Wọ́n fẹ́ kíjọsìn mímọ́

    Di àwátì ní ayé.

    Àmọ́ àwa kò ní bẹ̀rù;

    Jèhófà wà lẹ́yìn wa.

    Ọ̀nà yòówù kí wọ́n gbé e gbà,

    Wọn kò ní lè borí wa!

    (ÈGBÈ)

    Ìdílé kan ni gbogbo wa;

    Kò sóhun tó lè yà wá.

    Bó ti wù kádàánwò le tó,

    Jèhófà yóò dì wá mú;

    Jèhófà yóò dì wá mú.

  2. 2. Ọkàn wa balẹ̀ torí

    Jèhófà wà lẹ́yìn wa.

    O ṣèlérí fún wa pé

    Ìfẹ́ rẹ kò ní yẹ̀.

    Bàbá jọ̀ọ́, má fi wá sílẹ̀.

    Fẹ̀mí rẹ ràn wá lọ́wọ́.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ ká lè jẹ́ olóòótọ́;

    Kójú ti àwọn ọ̀tá!

    (ÈGBÈ)

    Ìdílé kan ni gbogbo wa;

    Kò sóhun tó lè yà wá.

    Bó ti wù kádàánwò le tó,

    Jèhófà yóò dì wá mú.

    (ÀSOPỌ̀)

    Àwọn ọ̀tá ń halẹ̀,

    Àmọ́ ẹ̀rù kò bà wá.

    A ti pinnu lọ́kàn wa pé

    Ti Jèhófà la ó máa ṣe.

    (ÈGBÈ)

    Ìdílé kan ni gbogbo wa;

    Kò sóhun tó lè yà wá.

    Bó ti wù kádàánwò le tó,

    Jèhófà yóò dì wá mú;

    Jèhófà yóò dì wá mú.