Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fara Balẹ̀ Yan Ẹni Tó O Máa Fẹ́

Fara Balẹ̀ Yan Ẹni Tó O Máa Fẹ́

Wà á jáde:

  1. 1. Ó ṣì máa dáa, àmọ́ mò ń rò ó,

    ‘Ta ni màá fẹ́?’

    Àmọ́ mo pinnu pé, mi ò ní kánjú rárá o.

    Torí ‘pinnu mi lè mẹ́kún wá tàbí máyọ̀ wá.

    Ìmọ̀lára ìgbà èwe òní lè pòórá bó bá dọ̀la.

    (ÈGBÈ)

    Ní sùúrù, fara balẹ̀ o.

    Dúró, wàá rí i.

    Jọ́lọgbọ́n, má ṣe kánjú rárá o,

    Rò ó wo ‘Ṣẹ́ni tó yẹ mí rèé?’

    Ní sùúrù, ṣáà fara balẹ̀ o.

    Má ṣe kánjú.

  2. 2. Mò ń wá ẹni tó máa fẹ́ràn mi dénú, tó sì tún máa ṣìkẹ́ mi.

    Mo mọ̀ lọ́kàn mi pé ìfẹ́ òtítọ́ kọ́ lèyí.

    Ìfẹ́ Jèhófà ni mo sì fẹ́ ṣe.

    K’Ọ́rọ̀ rẹ̀ tọ́ mi.

    Mó máa dúró dẹni tó mọ̀ òtítọ́, kó lè dẹnìkejì mi.

    (ÈGBÈ)

    Ní sùúrù, fara balẹ̀ o.

    Dúró, wàá rí i.

    Jọ́lọgbọ́n, má ṣe kánjú rárá o,

    Rò ó wo ‘Ṣẹ́ni tó yẹ mí rèé?’

    Ní sùúrù, ṣáà fara balẹ̀ o.

    Ṣáà fara balẹ̀.

    Má ṣe kánjú.