Fìgbàgbọ́ Ṣohun Tó Tọ́
Wà á jáde:
1. A fẹ́ túbọ̀
Ṣe púpọ̀ sí i
Lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn
Ọlọ́run wa.
Àkókò yìí
La lè ṣe bẹ́ẹ̀,
Torí tó bá dọ̀la,
Ó lè pẹ́ jù.
(ÈGBÈ)
Ká fìgbàgbọ́
Ṣohun tó tọ́.
Ká má ṣiyèméjì,
Ká má bẹ̀rù.
Ká nígbàgbọ́,
Jèhófà yóò tọ́jú wa.
Fọkàn balẹ̀;
A ó ṣe é yọrí.
2. Jèhófà mọ
Èrò ọkàn.
Ó mohun tá a nílò
Ká tó béèrè.
Bó tiẹ̀ dà bíi
Pé kò ṣeé ṣe,
Ẹ jẹ́ ká gbọ́kàn lé e,
Ká nígbàgbọ́.
(ÈGBÈ)
Ká fìgbàgbọ́
Ṣohun tó tọ́.
Ká má ṣiyèméjì,
Ká má bẹ̀rù.
Ká nígbàgbọ́,
Jèhófà yóò tọ́jú wa.
Fọkàn balẹ̀;
A ó ṣe é yọrí.
3. Ó yá, ká lọ.
Ká má wẹ̀yìn.
Jáà rí gbogbo ohun
Tí a pa tì.
Yóò tọ́jú wa;
Ìbùkún ń dúró dè wá
Láyé tuntun,
Párádísè.
(ÈGBÈ)
Ká fìgbàgbọ́
Ṣohun tó tọ́.
Ká má ṣiyèméjì,
Ká má bẹ̀rù.
Ká nígbàgbọ́,
Jèhófà yóò sì tọ́jú wa.
Fọkàn balẹ̀;
A ó ṣe é yọrí.
Ká fìgbàgbọ́
Ṣohun tó tọ́.
Ká má ṣiyèméjì,
Ká má bẹ̀rù.
Ká nígbàgbọ́,
Jèhófà yóò sì tọ́jú wa.
Fọkàn balẹ̀;
A ó ṣe é yọrí.
Ká nígbàgbọ́.