Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdílé Jèhófà

Ìdílé Jèhófà

Wà a Jáde:

  1. 1. Láyé yìí, ọ̀rẹ́ gidi ṣọ̀wọ́n​—⁠

    Alábàárò gidi, elétí gbáròyé.

    Mo fẹ́ lọ́rẹ̀ẹ́ tó máa dà bí ọmọ ìyá.

    Àwọn ọ̀rẹ́ tó máa ń dúró tini gan-an.

  2. 2. Ó yà mí lẹ́nu páwọn kan wà

    Tí ìfẹ́ wọn jinlẹ̀ púpọ̀; Wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi dénú.

    Ọkàn mi ti wá balẹ̀ gan-an ní báyìí.

    Baba wa ọ̀run ló fìfẹ́ so gbogbo wa pọ̀.

    (ÀSOPỌ̀)

    Mo ti wá láwọn tí mo lè pè lọ́mọ ìyá mi.

    Bílùú wa tilẹ̀ yàtọ̀, àti àwọ̀ wa,

    Ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn la ní, irú ẹ̀ sì ṣọ̀wọ́n.

    A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó so wá pọ̀.

  3. 3. Ìyanu ni ìṣọ̀kan yìí jẹ́.

    Kò síbòmíì láyé yìí, tá a ti lè rí èyí.

    Jèhófà ló dá wa lọ́lá, a dúpẹ́.

    Ọmọ Jèhófà Ọlọ́run ni gbogbo wa.

    (ÀSOPỌ̀)

    Ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn la ní, irú ẹ̀ sì ṣọ̀wọ́n.

    A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó so wá pọ̀.

  4. 4. Ìdílé kan ni gbogbo wa pátá.

    A ò ní gba Èṣù láyé láti dàárín wa rú.

    Tí gbogbo ìfẹ́ Jèhófà bá ti ṣẹ.

    Gbogbo ayé máa jẹ́ ìdílé kan ṣoṣo​—⁠

    Ìdílé Jèhófà Ọlọ́run.

    Títí láé,

    Títí láé.