Iṣẹ́ Tí Mò Ń Ṣe
Wà á jáde:
1. Àwọn èèyàn máa ń fi mí pàtẹ ìwé—
Mo sì ní táyà, wọ́n ń fà mí.
Iṣẹ́ ‘wàásù ni wọ́n sì máa ń fi mí ṣe.
Ìyẹn mà dá o.
Jẹ́ n sọ bó ṣe ń rí fún ẹ.
(ÈGBÈ)
Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ni mò ń ṣe,
Ọ̀pọ̀ àdúgbò ni wọ́n sì máa ń gbé mi lọ,
Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń rí mi
Oríṣiríṣi ni àwọn tó máa ń yà sọ́dọ̀ mi,
(ÈGBÈ)
Ẹnu máa ń ya àwọn míì
Tí wọ́n bá rí àwọn ohun tí wọn kò mọ̀,
Tí wọ́n bá sì kúrò níbẹ̀
Wọn kì í gbàgbé ohun tí wọ́n rí.
(ÀSOPỌ̀)
Wo táyà àtìwé,
Oríṣiríṣi ni wọ́n.
A fi ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run.
Téèyàn bá ń kọjá lọ,
Ó máa ń fojú wọn mọ́ra.
Ó dájú pé ẹ máa rí mi níbi térò pọ̀ sí.
(ÈGBÈ)
Tó o bá ń ṣohun tí mò ń ṣe,
Inú rẹ á máa dùn lójoojúmọ́ ayé.
Inú mi ń dùn, ayọ̀ mi ń kún,
Pé wọ́n ń fi mí wàásù níbi térò wà.