Jẹ́ Onígboyà àti Alágbára
Wà á Jáde:
1. Kílẹ̀ tó mọ́
Ló ti dìde,
Ó máa ń gbàdúrà fún
Àwọn ọmọ rẹ̀
Àtàwọn ará:
“Bàbá, jẹ́ ká jólóòótọ́”
Nígbà tíṣòro bá dé.
Kò jẹ́ sọ ìrètí nù láé,
Ó sì tún máa ń ṣoore,
Ó sì máa ń rántí orin kan:
(ÈGBÈ)
‘Mo wà pẹ̀lú rẹ.
Má bẹ̀rù rárá.
Wàá dalágbára.
Màá tọ́ ẹ sọ́nà.’
Má fòyà, má ṣojo.
Ṣáà fọkàn ẹ balẹ̀.
Yóò “fẹsẹ̀ rẹ múlẹ̀,
Yóò fún ọ lágbára.”
(ÀSOPỌ̀)
Ó máa ń ṣiṣẹ́ kára
Ní ojoojúmọ́
Kó lè wá jíjẹ-mímu
Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ
Tòótọ́ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an,
Ọkàn rẹ̀ máa ń balẹ̀ gan-an.
2. Bíi ti ẹyẹ idì
Ló ń ṣe,
Tó máa ń na ìyẹ́ rẹ̀.
Táá fò sókè gan-an.
Ọwọ́ rẹ̀ máa ń dí gan-an.
Tó bá di pó fẹ́ rẹ̀wẹ̀sì
Ó máa ń fọkàn gbàdúrà,
Ó máa ń sa gbogbo ipá rẹ̀.
Ohun kan wà tó máa ń
Fún un lókun. Ṣe ló máa ń kọrin pé:
(ÈGBÈ)
‘Mo wà pẹ̀lú rẹ.
Má bẹ̀rù rárá.
Wàá dalágbára.
Màá tọ́ ẹ sọ́nà.’
Má fòyà, má ṣojo.
Ṣáà fọkàn ẹ balẹ̀.
Yóò “fẹsẹ̀ rẹ múlẹ̀,
Yóò fún ọ lágbára.”
Yóò “fẹsẹ̀ rẹ múlẹ̀,
Yóò fún ọ lágbára.”