Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Ló So Wá Pọ̀

Jèhófà Ló So Wá Pọ̀

Wà á jáde:

  1. 1. Ìdààmú pọ̀ láyé, kò sí ‘ṣọ̀kan.

    Tí a bá wọ̀tún-wòsì, ìjà ni.

    Ìyà ń j’àwọn èèyàn, ó ti sú wọn.

    Jèhófà Ọlọ́run, làwa gbẹ́kẹ̀ lé.

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Ti Jèhófà ni a ó máa ṣe

    A kò ní fara wé ayé.

    ((ÈGBÈ)

    Ìfẹ́ la máa ń fi ṣe ohun gbogbo,

    Ìfẹ́ la fi ń ṣiṣẹ́ ‘wàásù

    Ìfẹ́ ẹgbẹ́ ará wa jinlẹ̀ gan-an!

    A kì í fara wé ayé,

    Jèhófà ló so wá pọ̀.

  2. 2. Ibi yòówù ká lọ, kárí ayé,

    Ṣe ni a máa ń ṣe bí ọmọ ìyá.

    Bí ‘ṣòro tiẹ̀ pọ̀, a nírètí​—

    Párádísè dé tán; ìgbà ọ̀tun!

    (ṢÁÁJÚ-ÈGBÈ)

    Ti Jèhófà ni a ó máa ṣe

    A kò ní fara wé ayé

    (ÈGBÈ)

    Ìfẹ́ la máa ń fi ṣe ohun gbogbo,

    Ìfẹ́ la fi ń ṣiṣẹ́ ‘wàásù.

    Ìfẹ́ ẹgbẹ́ ará wa jinlẹ̀ gan-an!

    A kì í fara wé ayé,

    Jèhófà ló so wá pọ̀.

    Ó so wá pọ̀.

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Ká jólóòótọ́, ká fara dà á

    Ká má ṣe fara wé ayé.

    (ÈGBÈ)

    Ìfẹ́ la máa ń fi ṣe ohun gbogbo,

    Ìfẹ́ la fi ń ṣiṣẹ́ ‘wàásù.

    Ìfẹ́ ẹgbẹ́ ará wa jinlẹ̀ gan-an!

    Ti Jèhófà la jẹ́,

    A yàtọ̀ sáyé.

    (ÈGBÈ)

    Ìfẹ́ la máa ń fi ṣe ohun gbogbo,

    Ìfẹ́ la fi ń ṣiṣẹ́ ‘wàásù

    Ìfẹ́ ẹgbẹ́ ará wa jinlẹ̀ gan-an!

    A kì í fara wé ayé,

    Jèhófà ló so wá pọ̀. So wá pọ̀.