Jèhófà Máa Ń Dúró Tì Wà
Wà á jáde:
1. Ìṣòro pọ̀ gan-an láyé,
Ó sì máa ń tojú sú mi gan-an.
Ẹ̀rù máa ń bà mí nígbà míì
Ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà
Kò dá mi dá ìṣòro mi
Òun l’Olùgbèjà mi
Mo mọ̀ pó nífẹ̀ẹ́ mi.
(ÈGBÈ)
Ọlọ́run mi,
Ojú rẹ nìkan ni mò ń wò.
Ìwọ lo fún mi lókun
Lásìkò tíṣòro dé.
O ń fún mi nígboyà
Kí n lè máa fára dà á,
Baba, mo gbọ́kàn mi lé ọ.
Jèhófà ló dúró tì mí.
O dì mí mú
Kí n má ṣubú.
Ò ń fọ̀rọ̀ rẹ̀ kọ́ mi.
Ò ń darí mi,
Ò ń tọ́ mi sọ́nà.
Tìrẹ ni màá máa ṣe.
2. Táwọn èèyàn rẹ
Bá tiẹ̀ ń gbógun tì ẹ́,
Yóò tọ́jú ẹ.
Yóò fà ẹ́ mọ́-ra,
Yóò sì tún fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀
Yóò sì fún ẹ lọ́gbọ́n.
(ÈGBÈ)
Fọkàn balẹ̀,
Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́
Ó sì máa fún ẹ́ lókùn
Nígbà tíṣòro bá dé.
Yóò fún ẹ nígboyà
Kó o lè máa fara dà á.
Gbẹ́kẹ̀ lé e, kó o fọkàn balẹ̀.
Jèhófà máa ń dúró tì wá.
Ó nífẹ̀ẹ́ wa.
Jèhófà máa ń dúró tì wá.
Ó ń dì wá lọ́wọ́ mú
Ká má ṣubú.
Ó ń fọ̀rọ̀ rẹ̀ kọ́ wa.
Jèhófà máa ń dúró tì wá.
Ó ń darí wa,
Ó ń tọ́ wa sọ́nà.
Tirẹ̀ ni a ó máa ṣe.
(ÈGBÈ)
Baba mi,
Ojú rẹ nìkan ni mò ń wò.
Ìwọ lo fún mi lókun
Lásìkò tíṣòro dé.
O fún mi ní-gboyà
Kí n lè máa fára dà á.
Baba, mo gbọ́kàn mi lé ọ.
Jèhófà máa ń dúró tì wá.
Ó nífẹ̀ẹ́ wa.
Jèhófà máa ń dúró tì wá.
Ó ní-fẹ̀ẹ́ wa.
Jèhófà máa ń dúró tì wá.