Máa Bá a Lọ
Wà á jáde:
1. Ìrísí ayé ń yí pa dà;
Mo gbọ́dọ̀ máa bá a lọ.
Ràn mí lọ́wọ́ kí ń máa bá a lọ
Bá a ṣe ń sáré náà.
Tá a bá pàdé àtakò
Tí wọn kò fẹ́ gbọ́ wa,
Ká tẹ̀lọ́nà tuntun tó dáa,
Ká wẹ́ni tó máa gbọ́.
(ÈGBÈ)
Ká máa bá a lọ.
Di ọwọ́ mi mú.
Ká lè jọ ṣẹ́gun.
Ká máa bá a lọ, láìrẹ̀wẹ̀sì.
Ká rókun gbà
Ká baa lè ṣáṣeyọrí.
Máa bá a lọ.
2. Èrò rere ni mo ní
Lójoojúmọ́ ayé,
Kìí fìgbà gbogbo rọrùn
Láti ṣohun tó yẹ.
Bíṣòro bá dìde,
Bí nǹkàn bá fẹ́ yíwọ́.
A ní ọ̀pọ̀ àrànṣe gan-an ni,
Kẹ́sẹ̀ wa lè múlẹ̀.
(ÈGBÈ)
Ká máa bá a lọ.
Di ọwọ́ mi mú.
Ká lè jọ ṣẹ́gun.
Ká máa bá a lọ, láìrẹ̀wẹ̀sì.
Ka rókun gbà,
Ká baa lè ṣáṣeyọrí.
Máa bá a lọ.
(ÀSOPỌ̀)
Ìsapá ń mú ‘bùkún wá
Bá a bá fi kún ‘sapá wa.
Gba ìtọ́ni, wàá rí i
Wàá múnú Ọlọ́run dùn.
A ní ‘rètí;
Tó dájú.
Tá ò lè pá mọ́ra—
Párádísè, kò sẹ́kún.
Mo ń fayọ̀ sapá
(ÈGBÈ)
Kí ń máa bá a lọ.
Di ọwọ́ mi mú.
Ká lè jọ ṣẹ́gun.
Ká máa bá a lọ, láìrẹ̀wẹ̀sì.
Ká rókun gbà,
Ká baa lè ṣáṣeyọrí.
Máa bá a lọ.
Ká máa bá a lọ.
Di ọwọ́ mi mú.
Ká lè jọ ṣẹ́gun.
Ká máa bá a lọ, láìrẹ̀wẹ̀sì.
Ká rókun gbà,
Ká baa lè ṣáṣeyọrí.
Máa bá a lọ.
Ká máa bá a lọ.