Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Màá Sin Jèhófà Tọkàntọkàn

Màá Sin Jèhófà Tọkàntọkàn

Wà á jáde:

  1. 1. Baba mi ọ̀run tọkàntọkàn ni mo fẹ́ sìn ọ́.

    Ó wù mí kí n máa fayé mi ṣohun tó o fẹ́ Ọlọ́run mi.

    Màá máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ ọ́.

    Iṣẹ́ ìwàásù tí mò ń ṣe máa ń fún mi láyọ̀ gan-an.

    (ÀSOPỌ̀)

    Bí mo ṣe ń yin Jèhófà, ìgbàgbọ́ mi ń lágbára sí i.

    Mo ti ṣèlérí pé ìwọ ni màá fayé mi sìn.

    (ÈGBÈ)

    Mo yìn ọ́ Jèhófà Baba mi ọ̀run,

    Mo ṣe tán láti ṣohunkóhun tó o fẹ́.

    Màá fayọ̀ ṣe iṣẹ́ tó o bá gbé fún mi.

    Jèhófà mo fẹ́ ọ, màá sìn ọ́ tọkàntọkàn.

  2. 2. Mò ń sin Jèhófà, mo sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ará.

    Gbogbo ipá mi ni mò ń sà lẹ́nuuṣẹ́ Jèhófà.

    Inú mi máa ń dùn gan-an tí n bá ṣoore fáwọn èèyàn,

    Mo máa ń sapá láti ran àwọn aláìní lọ́wọ́.

    (ÀSOPỌ̀)

    Bí mo ṣe ń yin Jèhófà, ìgbàgbọ́ mi ń lágbára sí i.

    Mo ti ṣèlérí pé ìwọ ni màá fayé mi sìn.

    (ÈGBÈ)

    Mo yìn ọ́ Jèhófà Baba mi ọ̀run,

    Mo ṣe tán láti ṣohunkóhun tó o fẹ́.

    Màá fayọ̀ ṣe iṣẹ́ tó o bá gbé fún mi.

    Jèhófà mo fẹ́ ọ, màá sìn ọ́ tọkàntọkàn.

    (ÈGBÈ)

    Mo yìn ọ́ Jèhófà Baba mi ọ̀run,

    Mo ṣe tán láti ṣohunkóhun tó o fẹ́.

    Màá fayọ̀ ṣe iṣẹ́ tó o bá gbé fún mi.

    Jèhófà mo fẹ́ ọ, màá sìn ọ́ tọkàntọkàn.