Mo Dúpẹ́ fún Ìṣẹ̀dá Ọlọ́run
Wà á jáde:
1. Òdòdó tó rẹwà máa ń dùn-ún wò gan-an,
Àwọn òkè tó ga, afẹ́fẹ́ tó tura,
Oòrùn tó ń tàn tún wúlò fún wa gan-an,
Àwọn ẹyẹ ń fò ní ojú ọ̀run—
(ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)
Ọlọ́run mi
Oníṣẹ́ àrà
Kí ni mo lè ṣe
Láti fọpẹ́ mi hàn?
(ÈGBÈ)
Màá dúpẹ́ oore rẹ
Màá sọ fún Baba pé
Mo dúpẹ́ gan-an
Torí o nífẹ̀ẹ́ wa
Màá kíyè sí
Àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run
Mi ò ní yéé dúpẹ́ fún oore rẹ.
Mo dúpẹ́ oore rẹ.
Mo dúpẹ́ oore rẹ.
2. Ojú ọ̀run dára, ó sì rẹwà gan-an
Oníṣẹ́ àrà ni ọ, tẹ́wọ́ gba ìyìn mi!
Ìró odò tó ń ṣàn máa ń tuni lára gan-an,
Ìràwọ̀ àti òṣùpá ń tàn yòò—
(ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)
Ọlọ́run mi,
Oníṣẹ́ àrà
Mo mohun ti màá ṣe
Láti fọpẹ́ mi hàn.
(ÈGBÈ)
Màá dúpẹ́ oore rẹ
Màá sọ fún Baba pé
Mo dúpẹ́ gan-an
Torí o nífẹ̀ẹ́ wa
Màá kíyè sí
Àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà Ọ-lọ́-run
Mi ò ní yéé dúpẹ́ fún oore rẹ.
Mo dúpẹ́ oore rẹ.
(ÀSOPỌ̀)
Agbára àtọgbọ́n rẹ pọ̀,
Olóore ni ọ́ Baba,
O sì nífẹ̀ẹ́ wa.
Mo dúpẹ́ Baba;
O ṣeun gan-an Baba.
(ÈGBÈ)
Màá dúpẹ́ oore rẹ,
Màá sọ fún Baba pé
Mo dúpẹ́ gan-an
Torí o nífẹ̀ẹ́ wa
Màá kíyè sí
Àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà Ọlọ́run
Mi ò ní yéé dúpẹ́ fún oore rẹ.
Mo dúpẹ́ oore rẹ.
Mo dúpẹ́ oore rẹ.
A dúpẹ́ oore rẹ.