Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Fi Ayé Mi Fún Ọ

Mo Fi Ayé Mi Fún Ọ

Wà á Jáde:

  1. 1. Mo jí lọ́gànjọ́ òru,

    Ìràwọ̀ pọ̀ salalu,

    Mo ronú nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ,

    Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ Baba.

  2. 2. Mo fi ayé mi fún ọ,

    Baba, jọ̀ọ́, tọ́ mi sọ́nà.

    Mo ṣèlérí pé títí ayé mi,

    Ìwọ nìkan ni màá sìn.

    (ÈGBÈ)

    Mo dúpẹ́ Jèhófà,

    Tó o ṣàánú mi,

    Tó o tún ayé mi ṣe,

    Ọmọ rẹ sì tún kú,

    Nítorí mi,

    Mo fayé mi fún ọ;

    Tìrẹ ni màá ṣe láé.

  3. 3. Oòrùn tó ń tàn wúlò gan-an,

    Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ mà ni!

    Ojoojúmọ́ là ń rí i pó o nífẹ̀ẹ́ wa,

    Jọ̀wọ́, tẹ́wọ́ gbọpẹ́ wa!

    (ÈGBÈ)

    Mo dúpẹ́ Jèhófà,

    Tó o ṣàánú mi

    Tó o tún ayé mi ṣe,

    Ọmọ rẹ sì tún kú

    Nítorí mi,

    Mo fayé mi fún ọ;

    Tìrẹ ni màá ṣe láé.

    (ÈGBÈ)

    Mo dúpẹ́ Jèhófà,

    Tó o ṣàánú mi

    Tó o tún ayé mi ṣe,

    Ọmọ rẹ sì tún kú

    Nítorí mi,

    Mo fayé mi fún ọ;

    Tìrẹ ni màá ṣe láé.