Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Ní Ìgbàgbọ́

Mo Ní Ìgbàgbọ́

(Sáàmù 27:13)

Wà á jáde:

  1. 1. Ọkàn mi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀

    Bí ọ̀tá tilẹ̀ ń gbógun.

    Jèhófà wà lẹ́yìn mi,

    Èmi kò ní bẹ̀rù.

    Atófaratì ni Baba.

    (ÈGBÈ)

    Ó dá mi lójú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.

    Kò sí ìbẹ̀rù kankan lọ́rọ̀ mi.

    Jèhófà Ọlọ́run ni

    Alátìlẹ́yìn mi.

    Mo mọ̀ pé kò ní já mi kulẹ̀;

    Mo nígbàgbọ́.

  2. 2. Àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà

    Tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn;

    Wọ́n máa gba èrè wọn

    Torí ìgbàgbọ́ wọn.

    Jèhófà máa jí wọn dìde.

    (ÈGBÈ)

    Ó dá mi lójú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.

    Kò sí ìbẹ̀rù kankan lọ́rọ̀ mi.

    Jèhófà Ọlọ́run ni

    Alátìlẹ́yìn mi.

    Mo mọ̀ pé kò ní já mi kulẹ̀;

    Mo nígbàgbọ́.

    (ÀSOPỌ̀)

    Ìgbàgbọ́ ló jẹ́ kí n ṣọkàn akin.

    Mo nírètí tó dájú gan-an.

    Ìgbàgbọ́ mi

    Ló jẹ́ kí n máa fara dà á lọ

    Bí ìṣòro tilẹ̀ pọ̀ gan-an.

  3. 3. Jèhófà ló ṣèlérí

    Pé ayé tuntun ń bọ̀.

    Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán.

    Jèhófà kì í parọ́.

    Baba, jọ̀ọ́ ràn mí lọ́wọ́ dópin.

    (ÈGBÈ)

    Ó dá mi lójú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.

    Kò sí ìbẹ̀rù kankan lọ́rọ̀ mi.

    Jèhófà Ọlọ́run ni

    Alátìlẹ́yìn mi.

    Mo mọ̀ pé kò ní já mi kulẹ̀;

    Mo nígbàgbọ́,

    Mo nígbàgbọ́.

(Tún wo Héb. 11:1-40.)