Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Dáa Jù Ni Mo Fún Ọ

Ohun Tó Dáa Jù Ni Mo Fún Ọ

Wà á jáde:

  1. 1. Ọkùnrin la bí,

    O fún wa pé ká kẹ́ ẹ, ká tọ́ ọ.

    Ṣe ló dà bí

    Pé àná ni.

    Inú wa ń dùn

    Fóhun tó yàn,

    Wàhálà wa kò já sásán.

    (ÈGBÈ)

    Kò wù mí kó lọ;

    Àmọ́ lọ́kàn mi mo

    Gbà pé ọ̀dọ́ rẹ ló ti lè

    Rí ààbò tó péye lónìí

    Àti títí láéláé.

    Láwọn ọdún tó ń bọ̀,

    Mo mọ̀ pọ́kàn mi máa balẹ̀.

    Ohun tó dáa jù ni mo fún ọ;

    Ohun tó sì yẹ ọ́ nìyẹn.

  2. 2. Ọmọbìnrin rèé,

    Ẹ̀bùn táa fẹ́ràn láti kẹ́.

    Nígbà ‘ṣòro,

    Nígbà ‘dùnnú,

    Àrídunnú

    Wa ti wá di

    Obìnrin tá a lè fi yangàn.

    (ÈGBÈ)

    Kò wù mí kó lọ;

    Àmọ́ lọ́kàn mi mo

    Gbà pé ọ̀dọ́ rẹ ló ti lè

    Rí ààbò tó péye lónìí

    Àti títí láéláé.

    Láwọn ọdún tó ń bọ̀,

    Mo mọ̀ pọ́kàn mi máa balẹ̀.

    Ohun tó dáa jù ni mo fún ọ;

    Ohun tó sì yẹ ọ nìyẹn.