Ọmọbìnrin Mi Ọ̀wọ́n
Wà á jáde:
1. Lát’ọmọ jòjòló,
Ó ń tọ́jú rẹ̀.
Bó sì ṣe ń dàgbà sí i
Ló máa ń tọ́ ọ sọ́nà.
Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe
Ohun tó dára;
Ó múnú bàbá rẹ̀ dùn.
(ÈGBÈ)
Ọmọbìnrin, Ó fẹ́ràn rẹ gan-an.
Fọkàn balẹ̀, Ó nífẹ̀ẹ́ rẹ.
2. Ó máa ń hùwà rere
Lójoojúmọ́.
Ó máa ń rántí ohun
Tí bàbá rẹ̀ kọ́ ọ.
Ọkàn rẹ̀ máa ń balẹ̀,
Inú rẹ̀ máa ń dùn,
Tí bàbá rẹ̀ bá sọ fún un pé:
(ÈGBÈ)
“Mo fẹ́ràn rẹ, ọmọbìnrin mi.
Fọkàn balẹ̀, mo nífẹ̀ẹ́ rẹ.”
(ÀSOPỌ̀)
Jèhófà máa ń rí
Gbogbo iṣẹ́ rẹ,
Ó sì tún máa ń rí
Bó o ṣe nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀.
Kò ní jẹ́ gbàgbé
Bó o ṣe ń fayé rẹ
Ṣe ìfẹ́ Rẹ̀.
(ÈGBÈ)
Ọmọbìnrin, Ó fẹ́ràn rẹ gan-an.
Fọkàn balẹ̀, yóò dúró tì ọ́.
Ọmọbìnrin, yóò máa ṣìkẹ́ rẹ.
Fọkàn balẹ̀, Ó fẹ́ ọ.