Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tẹra Mọ́ Iṣẹ́ Jèhófà

Tẹra Mọ́ Iṣẹ́ Jèhófà

Wà á jáde:

  1. 1. O mọ Jèhófà láti kékeré,

    O sì fẹ́ fi ayé rẹ sìn ín.

    O máa ń wàásù òtítọ́ Bíbélì,

    O sì tún máa ń gbàdúrà gan an.

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Àmọ́ nígbà tó yá, o kojú àwọn ìṣòro

    Tó wá fẹ́ ba ayọ̀ rẹ jẹ́, gbogbo nǹkan sì tojú sú ẹ.

    Bó ti wù kó le tó, fọkàn balẹ̀, má ṣe bẹ̀rù.

    Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́;

    Ṣáà ti jẹ́ olóòótọ́.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà mọyì rẹ, ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ;

    Yóò bù kún rẹ.

    Bó o ṣe ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ Jèhófà,

    Jèhófà rọ́kàn rẹ,

    Ó sì mọyì rẹ.

  2. 2. Bó o ṣe ń dàgbà sí i ni àdánwò ń yọjú

    Láti ṣe ohun tí kò dára.

    Ohun kan wà tó máa ṣèrànwọ́:

    Gbàdúrà sí Bàbá lókè.

    (ṢÁÁJÚ ÈGBÈ)

    Rí i dájú pé ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ ń lágbára sí i

    Pinnu láti fayé rẹ sin Jèhófà.

    Bó ti wù kó le tó, fọkàn balẹ̀, má ṣe bẹ̀rù.

    Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́;

    Ṣáà ti jẹ́ olóòótọ́.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà mọyì rẹ, ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ;

    Yóò bù kún rẹ.

    Bó o ṣe ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ Jèhófà,

    Jèhófà rọ́kàn rẹ,

    Ó sì mọyì rẹ.

    (ÀSOPỌ̀)

    Jọ̀ọ́, tẹra mọ́ iṣẹ́ Jèhófà.

    O ò ní kábàámọ̀; Jèhófà máa bù kún ẹ.

    (ÈGBÈ)

    Jèhófà mọyì rẹ, ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ;

    Yóò bù kún rẹ.

    Bó o ṣe ń fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ Jèhófà,

    Jèhófà rọ́kàn rẹ,

    Ó sì mọyì rẹ.

    (ÀSOPỌ̀)

    Jọ̀ọ́, tẹra mọ́ iṣẹ́ Jèhófà.

    O ò ní kábàámọ̀; Jèhófà máa bù kún ẹ.

    Jọ̀ọ́, tẹra mọ́ iṣẹ́ Jèhófà.

    O ò ní kábàámọ̀; Jèhófà máa bù kún ẹ.