ORIN 36
À Ń Dáàbò Bo Ọkàn Wa
(Òwe 4:23)
-
1. Ká máa dáàbò bo ọkàn wa
Tí a bá fẹ́ ríyè.
Ọlọ́run ń yẹ ọkàn wa wò,
Ó mọ ẹni tá a jẹ́.
Tá a bá jẹ́ kọ́kàn wa tàn wá,
Ó lè ṣì wá lọ́nà.
Ká jẹ́ kí èrò inú wa
Bá ti Jèhófà mu.
-
2. À ń gbàdúrà tó tọkàn wá,
À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jáà.
Ìgbà gbogbo là ń fìyìn fún un
Torí pó ń tọ́jú wa.
À ń ṣègbọràn sáwọn ẹ̀kọ́
Tí Jèhófà ń kọ́ wa.
Tọkàntọkàn là ń ṣèfẹ́ rẹ̀;
A dúró ṣinṣin sí i.
-
3. Ohun tó tọ́ là ń fọkàn rò,
À ń sá féròkerò.
À ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,
Ayé wa ń dára sí i.
Ọkàn wa balẹ̀ torí pé
Jáà fẹ́ràn olóòótọ́.
A ó máa fi tọkàntọkàn sìn ín
Títí ayérayé.
(Tún wo Sm. 34:1; Fílí. 4:8; 1 Pét. 3:4.)