ORIN 51
A Ti Ya Ara Wa sí Mímọ́ fún Ọlọ́run!
-
1. Ọlọ́run ló fà wá sọ́dọ̀ Jésù Kristi.
A dọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ látòní.
Jáà tan ìmọ́lẹ̀ òótọ́
Láti orí ìtẹ́ rẹ̀.
Ìgbàgbọ́ wa ń lágbára;
A dé láti ṣèfẹ́ Jáà.
(ÈGBÈ)
A yàn láti yara wa sí mímọ́ fún Jáà.
À ń yọ̀ torí a ní Jésù pẹ̀lú.
-
2. A gbàdúrà sí Jèhófà pé a ó máa sìnín.
Aó máa gbọ́ràn sí i títí ayé.
Ayọ̀ tí kò lẹ́gbẹ́ ni.
À ń forúkọ Jáà pè wá.
A ó fayọ̀ sọ fáráyé,
A ó wàásù Ìjọba náà.
(ÈGBÈ)
A yàn láti yara wa sí mímọ́ fún Jáà.
À ń yọ̀ torí a ní Jésù pẹ̀lú.