ORIN 59
Jẹ́ Ká Yin Jáà
-
1. Jẹ́ ká yin Jáà;
Ká kọrin sí i.
Ó fún wa lẹ́mìí àtohun rere.
Ojoojúmọ́
Là ń fìyìn fún un.
Alágbára ni, ìfẹ́ rẹ̀ pọ̀ gan-an.
À ń kéde orúkọ rẹ̀ fáráyé.
-
2. Jẹ́ ká yin Jáà;
Olùpèsè
Tó ń gbọ́ àdúrà wa, tó ń tọ́jú wa.
A ó máa ròyìn
Agbára rẹ.
Ò ń fún àwọn aláìlera lókun.
Ò ń fẹ̀mí mímọ́ rẹ ràn wá lọ́wọ́.
-
3. Jẹ́ ká yin Jáà;
Olóòótọ́ ni.
Ó ńt ù wá nínú, a lè gbọ́kàn lé e.
Ìjọba rẹ̀
Yóò mú nǹkan tọ́.
Yóò mú ìtura bá gbogbo ayé.
Ẹ jẹ́ ká fayọ̀ àt’ìtara yìn ín.
(Tún wo Sm. 94:18, 19; 145:21; 147:1; 150:2; Ìṣe 17:25.)