ORIN 65
Ẹ Tẹ̀ Síwájú!
-
1. Ẹ máa tẹ̀ síwájú, nínú òtítọ́.
Ká tan ìmọ́lẹ̀ òótọ́ fún gbogbo aráyé.
Jẹ́ kíṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ máa sunwọ̀n sí i;
Kó o gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run.
Gbogbo wa ló yẹ ká ṣiṣẹ́ yìí.
Rántí pé Jésù náà ṣiṣẹ́ yìí.
Máa bẹ Ọlọ́run pé kó dúró tì ọ́,
Kó o lè jẹ́ olódodo.
-
2. Ẹ máa tẹ̀ síwájú, fìgboyà wàásù.
Ká sọ ìròyìn ayọ̀ fún gbogbo aráyé.
Ẹ jẹ́ ká máa wàásù látilé délé,
Ká fi yin Jáà, Ọba wa.
Báwọn ọ̀tá tiẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ wa,
Má bẹ̀rù, ṣáà máa fòótọ́ kọ́ni.
Ká jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé láìpẹ́,
’Jọba Ọlọ́run máa dé.
-
3. Ẹ máa tẹ̀ síwájú, ẹ má ṣe yẹsẹ̀.
Ká sì máa sunwọ̀n sí i,
Iṣẹ́ ṣì pọ̀ láti ṣe.
Jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí rẹ,
Yóò sì máa fún ọ láyọ̀.
Nífẹ̀ẹ́ àwọn tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́.
Kọ́ wọn kí òótọ́ lè dọ́kàn wọn.
Ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè dàgbà dénú,
Kí ‘mọ́lẹ̀ òótọ́ lè tàn.
(Tún wo Fílí. 1:27; 3:16; Héb. 10:39.)