ORIN 82
Ẹ Jẹ́ “Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn”
-
1. Àṣẹ Jésù ni pé
Kí ‘mọ́lẹ̀ wa tàn.
Kí ìmọ́lẹ̀ wa hàn
Gbangba sáráyé.
Ìwé Mímọ́ ńkọ́ wa
Ní ìwà rere
Tá a gbọ́dọ̀ máa mú dàgbà
Nínú ayé wa.
-
2. Bá a ṣe ń wàásù fáwọn
Èèyàn tá à ń pàdé,
Ẹ̀kọ́ ọ̀r’Ọlọ́run
Máa ràn wọ́n lọ́wọ́.
Kí wọ́n lè ṣàtúnṣe
Nínú ayé wọn;
Kí wọ́n lè yàn fúnra wọn
Láti wá sin Jáà.
-
3. Ìwà rere tá à ń hù
Ń tàn bí ìmọ́lẹ̀.
Ọ̀rọ̀ ẹnu wa náà
Sì tún ń gbéni ró.
Bí a tiẹ̀ ń gbé nínú
Ayé Sátánì,
Ìmọ́lẹ̀ wa tó ń tàn yòò
Ń fògo f’Ọ́lọ́run.
(Tún wo Sm. 119:130; Mát. 5:14, 15, 45; Kól. 4:6.)