Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Hébérù 11:1—“Ìgbàgbọ́ Ni Ìdánilójú Ohun Tí À Ń Retí”

Hébérù 11:1—“Ìgbàgbọ́ Ni Ìdánilójú Ohun Tí À Ń Retí”

 “Ìgbàgbọ́ ni ìdánilójú ohun tí à ń retí, ẹ̀rí tó dájú nípa àwọn ohun gidi tí a kò rí.”—Hébérù 11:1, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Njẹ igbagbọ́ ni idaniloju ohun ti a nreti, ijẹri ohun ti a kò ri.”—Hébérù 11:1, Bibeli Mimọ.

Ìtumọ̀ Hébérù 11:1

 Ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe àlàyé ṣókí nípa ohun tí ìgbàgbọ́ túmọ̀ sí, ó sì tún jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ kọjá kééyàn kàn gba nǹkan gbọ́.

 “Ìgbàgbọ́ ni ìdánilójú ohun tí à ń retí.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó wà ní Hébérù 11:1, tí wọ́n tú sí “ìgbàgbọ́” nínú Bíbélì tó wà ní èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ túmọ̀ sí ìdánilójú, ìgbẹ́kẹ̀lé tàbí ìyíniléròpadà tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Irú ìgbàgbọ́ yìí kì í ṣe èrò lásán, ohun tó dájú téèyàn ń retí ni. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ìdánilójú ohun tí à ń retí” a tún lè túmọ̀ sí “ìwé ẹ̀rí jíjẹ́ oníǹkan,” èyí tó fi hàn pé ohun tó dájú tàbí tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé ni wọ́n fún ẹnì kan.

 “Ìgbàgbọ́ ni . . . ẹ̀rí tó dájú [tàbí, “ẹ̀rí tó ṣe kedere,” àlàyé ìsàlẹ̀] nípa àwọn ohun gidi tí a kò rí.” Ìgbàgbọ́ ò lè wà láìsí ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ẹ̀rí yìí á lágbára gan-an débi pé ó máa dá èèyàn lójú pé tí kò bá tiẹ̀ fojú rí ohun kan, ó gbà pé ohun náà wà lóòótọ́.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáajú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Hébérù 11:1

 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ló kọ ìwé Hébérù sí àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù àti àyíká rẹ̀. Ọ̀rọ̀ nípa bí ìgbàgbọ́ ti ṣe pàtàkì tó ni Pọ́ọ̀lù ń sọ ní apá yìí nínú lẹ́tà rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run dáadáa, torí ẹnikẹ́ni tó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó wà àti pé òun ló ń san èrè fún àwọn tó ń wá a tọkàntọkàn.” (Hébérù 11:6) Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù sọ ìtumọ̀ ìgbàgbọ́ ní Hébérù 11:1, ó wá sọ àpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tí ìtàn wọn nínú Bíbélì fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́. Ó sọ bí wọ́n ṣe lo ìgbàgbọ́, tí wọ́n sì ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—Hébérù 11:4-38.

a Wọ́n túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a lò níbí, ìyẹn hy·poʹsta·sis sí “ìdánilójú ohun tí à ń retí.” Tí a bá túmọ̀ rẹ̀ ní olówuuru, ó lè túmọ̀ sí “èyí tó dúró lórí ìpìlẹ̀ kan.” Ní èdè Latin, wọ́n tú ọ̀rọ̀ yìí sí sub·stanʹti·a, inú ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò ní èdè Gẹ̀ẹ́sì nínú Bibeli Mimọ ti jáde, ìyẹn “substance” tó túmọ̀ sí ohun tó nípọn.