ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ
Ìfihàn 21:1—“Ọ̀run Tuntun Kan àti Ayé Tuntun Kan”
“Mo rí ọ̀run tuntun àti ayé tuntun; torí ọ̀run tó wà tẹ́lẹ̀ àti ayé tó wà tẹ́lẹ̀ ti kọjá lọ, kò sì sí òkun mọ́.”—Ìfihàn 21:1, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
“Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ayé tuntun kan: nítorí pé ọ̀run ti ìṣáájú àti ayé ìṣáájú ti kọjá lọ; òkun kò sì sí mọ́.”—Ìfihàn 21:1, Bíbélì Mímọ́.
Ìtumọ̀ Ìfihàn 21:1
Èdè àpèjúwe tí ẹsẹ yìí lò jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run tó wà ní ọ̀run máa tó fòpin sí gbogbo àwọn ìjọba èèyàn. Ìjọba yìí máa mú àwọn èèyàn burúkú kúrò, á sì máa ṣàkóso àwọn èèyàn tó ń ṣègbọràn sí àṣẹ rẹ̀.
Àwọn ohun tó wà nínú ìwé Ìfihàn jẹ́ “àmì” tàbí àfiwé. (Ìfihàn 1:1) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé àfiwé ni ọ̀run ati ayé tí ẹsẹ yìí mẹ́nu kàn kì í ṣe ọ̀run àti ayé ní ti gidi. Bákan náà, àwọn ẹsẹ Bíbélì míì lo “ọ̀run tuntun” àti “ayé tuntun” lọ́nà àfiwé. (Àìsáyà 65:17; 66:22; 2 Pétérù 3:13) Torí náà, tá a bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí, ó máa jẹ́ ká lóye ohun táwọn ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí.
“Ọ̀run tuntun.” Bíbélì sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ọ̀run” làti fi tọ́ka sí ìṣàkóso tàbí ìjọba. (Àìsáyà 14:12-14; Dáníẹ́lì 4:25, 26) Ìwé ìwádìí kan sọ pé tó bá kan ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀, ọ̀rọ̀ náà “ọ̀run dúró fún àgbára ìṣàkóso tàbí ìjọba.” a “Ọ̀run tuntun” tó wà nínú ìwé Ìfihàn 21:1 ń tọ́ka sí Ìjọba Ọlọ́run. Ìjọba yìí fara hàn jálẹ̀ inú ìwé Ìfihàn àti àwọn ẹsẹ Bíbélì míì, wọ́n sì tún máa ń pè é ní “ìjọba ọ̀run” láwọn ìgbà míì. (Mátíù 4:17; Ìṣe 19:8; 2 Tímótì 4:18; Ìfihàn 1:9; 5:10; 11:15; 12:10) Gbogbo ìjọba tí àwọn èèyàn aláìpé dá sílẹ̀ pátá, ìyẹn “ọ̀run tó wà tẹ́lẹ̀” ni Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run máa pa rún.—Dáníẹ́lì 2:44; Lúùkù 1:31-33; Ìfihàn 19:11-18.
“Ayé tuntun.” Bíbélì sọ pé ayé tá a wà yìí ò ní pa run láé. (Sáàmù 104:5; Oníwàásù 1:4) Kí ni ayé tó máa pa run náà wá ń ṣàpẹẹrẹ? Lọ́pọ̀ ìgbà, tí Bíbélì bá lo ọ̀rọ̀ náà “ayé,” àwọn èèyàn ló ń tọ́ka sí. (Jẹ́nẹ́sísì 11:1; 1 Kíróníkà 16:31; Sáàmù 66:4; 96:1) Torí náà, “ayé tuntun” tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ dúró fún àwùjọ àwọn èèyàn tuntun, tí wọ́n fi ara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run. “Ayé tó wà tẹ́lẹ̀,” ìyẹn àwùjọ àwọn èèyàn tí kò fi ara wọn sábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa pa run.
“Kò sì sí òkun mọ́.” Àfiwé ni “òkun” tó wà ní apá tó gbẹ̀yìn nínú ìwé Ìfihàn 21:1 jẹ́. Bí òkun ṣe máa ń ru gùdù, tí kì í sinmi, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń fa wàhálà àti ìdàrúdàpọ̀ ṣe wa torí wọn ò fẹ́ mọ Ọlọ́run, wọn ò sì fẹ́ tẹ̀ lé òfin rẹ̀. (Àìsáyà 17:12, 13; 57:20; Ìfihàn 17:1, 15) Irú àwọn èèyàn yìí ò ní sí mọ́. Sáàmù 37:10 sọ pé: “Láìpẹ́, àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́; wàá wo ibi tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀, wọn ò ní sí níbẹ̀.”
Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Ìfihàn 21:1
Ìwé Ìfihàn sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní “ọjọ́ Olúwa.” (Ìfihàn 1:10) Àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì fi hàn pé ọjọ́ Olúwa bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914, nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run. b Àmọ́ kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ayé. Kódà àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì míì jẹ́ ká mọ̀ pé nǹkan máa le gan-an ní apá ìbẹ̀rẹ̀ “ọjọ́ Olúwa.” Apá ìbẹ̀rẹ̀ yìí ni Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (2 Tímótì 3:1-5, 13; Mátíù 24:3, 7; Ìfihàn 6:1-8; 12:12) Tí àkókò tí nǹkan le gan-an, tó sì nira yẹn bá dópin, Ìjọba Ọlọ́run máa fòpin sí àwọn ìjọba tí èèyàn dá sílẹ̀ tó dúró fún ọ̀run tó wà tẹ́lẹ̀ àti àwùjọ àwọn èèyàn tí kò fi ara wọn sábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tó dúró fún ayé tó wà tẹ́lẹ̀. Á sì mú kí àlàáfíà àti ìṣọkan gbilẹ̀. Àwọn tó fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn “ayé tuntun,” máa gbádùn ìgbésí ayé tó tura àti ìlera tó jí pépé.—Ìfihàn 21:3, 4.
Wo fídíò kékeré yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Ìfihàn.
a McClintock and Strong’s Cyclopedia (1891), Volume IV, ojú ìwé 122.
b Wo àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Àwọn Ìtàn Inú Bíbélì Tó Tẹ̀ Léra Fi Hàn Nípa Ọdún 1914?”