ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ
Máàkù 1:15—‘Ìjọba Ọlọ́run Ti Sún Mọ́lé’
Àkókò tí a yàn ti pé, Ìjọba Ọlọ́run sì ti sún mọ́lé. Ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere.”—Máàkù 1:15, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
“ Akokò na de, ijọba Ọlọrun si kù si dẹ̀dẹ: ẹ ronupiwada, ki ẹ si gba ihinrere gbọ́.”—Máàkù 1:15, Bíbélì Mímọ́.
Ìtumọ̀ Máàkù 1:15
Jésù Kristi sọ fáwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run a ti “sún mọ́lé” tàbí pé ó ti “kù sí dẹ̀dẹ̀” torí pé òun ló máa jẹ́ Ọba Ìjọba yẹn, òun fúnra ẹ̀ sì wà pẹ̀lú wọn.
Jésù ò sọ pé Ìjọba náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Kódà lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé Ìjọba náà kò tíì dé. (Ìṣe 1:6, 7) Síbẹ̀, àkókò tó yẹ kó dé náà ló dé, ìyẹn ọdún tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé Ọba Ìjọba náà máa dé. b Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé: “Àkókò tí a yàn ti pé”—ìyẹn àkókò tó máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere nípa Ìjọba náà fún gbogbo èèyàn.—Lúùkù 4:16-21, 43.
Káwọn èèyàn lè jàǹfààní látinú ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà, ìyẹn ni pé, kí wọ́n kábàámọ̀ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti dá sẹ́yìn, kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Àwọn tó bá ronú pìwà dà fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere Ìjọba tó ń bọ̀ yẹn.
Ohun tó yí ọ̀rọ̀ inú Máàkù 1:15 ká
Ìgbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní Gálílì ló sọ àwọn ọ̀rọ̀ yìí. Nígbà tí Mátíù ń sọ ìtàn kan náà nínú Mátíù 4:17, ó sọ pé: “Àtìgbà yẹn lọ” ni Jésù ti ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ìjọba náà ni ọ̀rọ̀ pàtàkì tí Jésù wàásù rẹ̀. Kódà, ó lé ní ọgọ́rùn-ún ìgbà tí àwọn Ìwé Ìhìn Rere c mẹ́rẹ̀ẹ̀rin mẹ́nu kan Ìjọba Ọlọ́run, Jésù ló sì sọ èyí tó pọ̀ jù níbẹ̀. Nínú Bíbélì, Jésù sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ju ohunkóhun míì lọ.
Ka Máàkù orí 1 àti àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tí wọ́n fi ṣàlàyé ọ̀rọ̀, àwọn atọ́ka etí ìwé, àwọn àwòrán àti àwòrán ilẹ̀.
a Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àkóso kan tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ ní ọ̀run kí ìfẹ́ rẹ̀ lè ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé. (Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:10) Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i, wo àpilẹ̀kọ náà, “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?”
b Jésù gbọ́dọ̀ di ọba kó lè mú àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà náà ṣẹ kó sì fi ara rẹ̀ hàn ní aṣojú pàtàkì fún Ọlọ́run. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìṣirò àwọn ọjọ́ àti ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ ọdún tí Mèsáyà máa fara hàn, wo àpilẹ̀kọ náà, “Bí Dáníẹ́lì Ṣe Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìgbà Tí Mèsáyà Yóò Dé.”
c Ìwé Ìhìn Rere ni àwọn ìwé mẹ́rin àkọ́kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, Májẹ̀mú Tuntun làwọn èèyàn sì sábà máa ń pè é. Àwọn ìwé yìí ló sọ ìtàn nípa ìgbésí ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù.