Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Fínfín Àmì sí Ara?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni Bíbélì mẹ́nu kan fínfín àmì sí ara ẹni, inú ìwé Léfítíkù 19:28, ló ti sọ ọ́, ó ní: “Ẹ kò . . . gbọ́dọ̀ fín àmì sí ara yín.” Ọlọ́run ló pàṣẹ yìí fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, àṣẹ náà ló mú kí wọ́n yàtọ̀ sí àwọn èèyàn tó wà láyìíká wọn tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n fín orúkọ àtàwọn àmì àwọn ọlọ́run tí wọ́n ń bọ sí ara wọn. (Diutarónómì 14:2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Òfin tí Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì yìí kò de àwọn Kristẹni, síbẹ̀ ó yẹ kí wọ́n tẹ̀ lé ìlànà tó wà nínú òfin yìí.
Ǹjẹ́ ó yẹ kí Kristẹni fín àmì tàbí ya àwòrán sára?
Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí á jẹ́ kó o ronú lórí ọ̀rọ̀ yìí:
“Kí àwọn obìnrin máa . . . ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà.” (1 Tímótì 2:9) Bí ìlànà yìí ṣe kan àwọn obìnrin náà ló kan àwọn ọkùnrin. Ó yẹ ká máa ro bí ohun tá a bá ṣe ṣe máa rí lára àwọn ẹlòmíì, kò yẹ ká máa pe àfiyèsí tí kò tọ́ sí ara wa.
Àwọn kan máa ń fín ara kí wọ́n lè fi irú ẹni tí wọ́n jẹ́ hàn tàbí torí pé wọ́n lè ṣe ohun tó bá wù wọ́n, nígbà tí àwọn míì ń fín àmì sára nítorí wọ́n gbà pé àwọn làwọn ni ara àwọn. Àmọ́, Bíbélì rọ̀ àwọn Kristẹni pé: “Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín.” (Róòmù 12:1) Lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ láti pinnu bóyá ó yẹ kó o fín àmì sí ara. Tó o bá fín àmì sí ara rẹ torí pé àṣà tó wà lòde nìyẹn tàbí torí pé o fẹ́ fi hàn pé ìwọ náà wà nínú ẹgbẹ́ kan, rántí pé ara fínfín lè má wù ọ́ mọ́ tó bá yá, àmọ́ o kò ní lè pa ohun tó o ti fín sára rẹ́ mọ́. Ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu ni wàá ṣe tí o bá ń ronú nípa ìdí tó o fi fẹ́ fín àmì sára rẹ.—Òwe 4:7.
“Àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní, ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.” (Òwe 21:5) Ìkánjú làwọn tó ń fín ara fi máa ń pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì máa ní ipa tí kì í tán bọ̀rọ̀ lórí àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn míì àti lórí iṣẹ́ wọn. Ọ̀pọ̀ ìrora ni àwọn tó bá fẹ́ pa ohun tí wọ́n fín sára rẹ́ máa ń ní, ó sì máa ń ná wọn lówó gan-an. Ìwádìí tí àwọn kan ṣe àti bí owó ṣe túbọ̀ ń wọlé fún àwọn ilé iṣẹ́ tó ń pa ohun tí àwọn èèyàn fín sára rẹ́ fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn tó fín àmì sára ló kábàámọ̀ pé àwọn ṣe é.