Ǹjẹ́ Bíbélì Ta Ko Ìbálòpọ̀?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì ò ka ìbálòpọ̀ léèwọ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún àwọn tó ṣègbéyàwó ni ìbálòpọ̀ jẹ́. Ọlọ́run dá àwa èèyàn ní “akọ àti abo,” nígbà tó sì wo àwọn ohun tí ó dá, ó rí i pé “ó dára gan-an.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 31) Nígbà tó so ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ pọ̀ nínú ìgbéyàwó, ó sọ pé, “wọ́n á sì di ara kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Ìgbádùn ìbálòpọ̀ àti ìsúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí láàárín tọkọtaya wà lára ohun tó jẹ́ kí wọ́n di ara kan.
Ẹ gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa ayọ̀ tí ọkùnrin tó ti ṣègbéyàwó máa ń ní, ó ní: “Máa yọ̀ pẹ̀lú aya ìgbà èwe rẹ, . . . Jẹ́ kí ọmú rẹ̀ máa dá ọ lọ́rùn nígbà gbogbo.Kí ìfẹ́ rẹ̀ máa gbà ọ́ lọ́kàn ní gbogbo ìgbà.” (Òwe 5:18, 19) Ọlọ́run fẹ́ kí ìyàwó náà gbádùn ìbálòpọ̀. Ó sọ pé: “Ki ọkọ máa fun aya rẹ̀ ni ẹ̀tọ́-ìgbéyàwó rẹ̀: bẹẹ gẹ́gẹ́ sì ni aya pẹ̀lú si ọkọ.”—1 Kọ́ríńtì 7:3, Bibeli Yoruba Atọ́ka.
Ibi tí ìgbádùn ìbálòpọ̀ mọ
Àwọn tọkọtaya nìkan ni Ọlọ́run fẹ́ kó máa ní ìbálòpọ̀. Ìwé Hébérù 13:4 sọ pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo èèyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó má sì ní ẹ̀gbin, torí Ọlọ́run máa dá àwọn oníṣekúṣe àti àwọn alágbèrè lẹ́jọ́.” Àwọn tọkọtaya ní láti fọkàn tán ara wọn, kí wọ́n sì ṣera wọn lọ́kan. Àwọn tọkọtaya máa láyọ̀ gan-an tí kì í bá ṣe pé bí oníkálukú ṣe máa tẹ́ ìfẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn ló gbájú mọ́, wọ́n á láyọ̀ tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì tó sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.