Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Gbígbé Pọ̀ Láìṣègbéyàwó?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì sọ pé Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn “ta kété sí ìṣekúṣe.” (1 Tẹsalóníkà 4:3) Nínú Bíbélì, lára ohun tí “ìṣekúṣe” túmọ̀ sí ni panṣágà, kí ọkùnrin àti ọkùnrin tàbí obìnrin àti obìnrin máa ní ìbálòpọ̀ àti ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin àti obìnrin tí kì í ṣe tọkọtaya.
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi sọ pé káwọn èèyàn ṣègbéyàwó kí wọ́n tó lè di tọkọtaya?
Ọlọ́run ló dá ètò ìgbéyàwó sílẹ̀. Ó dá a sílẹ̀ nígbà tó so tọkọtaya àkọ́kọ́ pọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:22-24) Torí náà, kò fẹ́ kí ọkùnrin àti obìnrin jọ máa gbé pọ̀ láìṣègbéyàwó.
Ọlọ́run mọ ohun tó máa ṣe àwa èèyàn láǹfààní. Ó fẹ́ kí ìgbéyàwó jẹ́ àjọṣe tó máa wà títí láé láàárín ọkùnrin àti obìnrin, torí pé ìyẹn ló máa ṣe àwọn tó wà nínú ìdílé láǹfààní, táá sì dáàbò bò wọ́n. Wo àpèjúwe yìí ná. Bí ìwé atọ́nà ṣe máa ń bá ohun èlò tuntun wá kéèyàn lè mọ bí á ṣe tò ó pọ̀ tàbí béèyàn á ṣe lò ó, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọlọ́run ṣe sọ àwọn ohun tá a lè ṣe táá jẹ́ kí ìgbéyàwó wa yọrí sí rere. Ó sì dájú pé gbogbo àwọn tó bá ń tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run ló máa jàǹfààní.—Àìsáyà 48:17, 18.
Ohun tó máa ń gbẹ̀yìn ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó kì í dáa. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń yọrí sí oyún ẹ̀sín, èèyàn lè kó àrùn ìbálòpọ̀, ó sì máa ń fa ìdààmú ọkàn. a
Ọlọ́run fọwọ́ sí i pé kí tọkọtaya ní ìbálòpọ̀, torí ẹ̀ ló sì ṣe fún wọn ní agbára ìbímọ. Ẹ̀mí ṣeyebíye lójú Ọlọ́run, ẹ̀bùn iyebíye sì ni ọmọ bíbí. Torí náà, Ọlọ́run fẹ́ ká fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀bùn yẹn, a sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá tẹ̀ lé ìlànà tó fi lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó.—Hébérù 13:4.
Ṣó bójú mu kí ọkùnrin àti obìnrin jọ máa gbé pọ̀ láìṣègbéyàwó kí wọ́n lè mọ̀ bóyá àwọn bára mu?
Àwọn kan máa ń kọ́kọ́ gbé pọ̀ kí wọ́n lè mọ̀ bóyá àwọn bára mu àbí àwọn ò bára mu. Tí wọ́n bá sì pinnu pé àwọn ò bára mu, ṣe ni wọ́n máa ń pín gaàrí. Àmọ́ “àkókò tí wọ́n fi yẹ ara wọn wò” yìí kọ́ ló máa ní kí ìgbéyàwó wọn yọrí sí rere. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó lè mú kí tọkọtaya bára wọn kalẹ́ ni pé káwọn méjèèjì ṣe ara wọn lọ́kàn, kí wọ́n sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti yanjú ìṣòro. b Ìgbéyàwó máa ń mú kó rọrùn láti ṣera ẹni lọ́kan.—Mátíù 19:6.
Báwo làwọn tọkọtaya ṣe lè ṣe ara wọn lọ́kan?
Kò sí ìgbéyàwó tí kò ní ìṣòro tiẹ̀. Ṣùgbọ́n, tọkọtaya lè ṣera wọn lọ́kan tí wọ́n bá ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò. Àpẹẹrẹ díẹ̀ rèé:
Fi ire ọkọ tàbí aya rẹ ṣáájú tìẹ.—1 Kọ́ríńtì 7:3-5; Fílípì 2:3, 4.
Máa fìfẹ́ hàn, kó o sì máa bọ̀wọ̀ fún ẹnì kejì rẹ.—Éfésù 5:25, 33.
Máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.—Òwe 12:18.
Máa ní sùúrù kó o sì tètè máa dárí jini.—Kólósè 3:13, 14.
a Wo àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Tí Wọ́n Bá Sọ Pé Dandan Ni Kí N Ní Ìbálòpọ̀ Ńkọ́?”
b Wo àpilẹ̀kọ náà “Ìdílé Aláyọ̀—Jẹ́ Olóòótọ́.”