Ǹjẹ́ Èṣù Lè Darí Àwọn Èèyàn?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ipa tí Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù ń ní lórí aráyé pọ̀ gan-an débi pé Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ayé patapata wà lábẹ́ Èṣù.” (1 Jòhánù 5:19, Bíbélì Ìròhìn Ayọ̀) Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn ọ̀nà tí Èṣù gbà ń nípa lórí àwọn èèyàn.
Ẹ̀tàn. Bíbélì rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “kọ ojú ìjà sí àrékérekè Èṣù.” (Éfésù 6:11, Bíbélì Mímọ́) Ọ̀kan lára àwọn àrékérekè Èṣù ni bó ṣe ń lo ẹ̀tàn láti mú kí àwọn èèyàn gbà pé ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 11:13-15.
Ìbẹ́mìílò. Èṣù máa ń lo àwọn abókùúsọ̀rọ̀, àwọn tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ oríire, àwọn woṣẹ́woṣẹ́ àti àwọn awòràwọ̀ láti ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. (Diutarónómì 18:10-12) Lílo oògùn tó ní agbára òkùnkùn nínú, ìmúnimúyè àti ṣíṣe àṣàrò tí kò ní láárí wà lára àwọn nǹkan tó ń jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí èṣù máa darí àwọn èèyàn.—Lúùkù 11:24-26.
Ìsìn èké. Ìsìn tó bá ń fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ àwọn èèyàn ń ṣì wọ́n lọ́nà, ó sì ń mú kí wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 10:20) Bíbélì pe irú àwọn ẹ̀kọ́ èké bẹ́ẹ̀ ní “àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù.”—1 Tímótì 4:1.
Ẹ̀mí èṣù. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn kan tí ẹ̀mí èṣù ń darí. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹ̀mí yìí máa ń fọ́ àwọn tó ní i lójú, ó máa ń sọ wọ́n di odi tàbí kó jẹ́ kí wọ́n máa ṣe ara wọn léṣe.—Mátíù 12:22; Máàkù 5:2-5.
Bí a kò ṣe ní jẹ́ kí Èṣù darí wa
Kò yẹ kó o máa bẹ̀rù pé àwọn ẹ̀mí èṣù á máa darí rẹ torí Bíbélì sọ àwọn nǹkan tí o lè ṣe láti kọjú ìjà sí Èṣù, tí wàá sì ṣẹ́gun rẹ̀:
Kọ́ bí wàá ṣe mọ àwọn ọ̀nà tí Èṣù ń lò, kí o lè mọ “àwọn ète-ọkàn rẹ̀.”—2 Kọ́ríńtì 2:11.
Kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì kí o sì máa fi àwọn ohun tí ò ń kọ́ ṣèwà hù. Tí o bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, wàá lè dáàbò bò ara rẹ lọ́wọ́ ìdarí Èṣù.—Éfésù 6:11-18.
Kó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìbẹ́mìílò dà nù. (Ìṣe 19:19) Tó fi mọ́ orin, ìwé, àwòrán ara ògiri tàbí fídíò tó ń gbé ìbẹ́mìílò lárugẹ.