Ṣé Bíbélì Kọ́ni Pé ‘Téèyàn Bá Ti Rígbàlà Lẹ́ẹ̀kan, Ó Ti Rígbàlà Títí Ayé Nìyẹn’?
Ohun tí Bíbélì Sọ
Rárá o, Bíbélì ò kọ́ni pé ‘téèyàn bá ti rígbàlà lẹ́ẹ̀kan, ó ti rígbàlà títí ayé nìyẹn’. Ẹni kan tó ti rígbàlà torí ó nígbàgbọ́ nínú Jésù lè pàdánù ìgbàgbọ́ tó ní kó má sì rígbàlà mọ́. Bíbélì sọ pé ó gba pé kéèyàn ja “ìjà líle” kó tó lè di ìgbàgbọ́ rẹ̀ mú. (Júúdà 3, 5) Wọ́n sọ fún àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n ti gba Kristi gbọ́ pé: “Ẹ máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà yín yọrí pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì.”—Fílípì 2:12.
Àwọn ẹsẹ Bíbélì tí kò fọwọ́ sí i pé ‘téèyàn bá ti rí ìgbàlà lẹ́ẹ̀kan, ó ti rí ìgbàlà títí ayé nìyẹn’
Bíbélì kìlọ̀ pé ká sá fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì tí kò ní jẹ́ ká jogún Ìjọba Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11; Gálátíà 5:19-21) Tó bá wá jẹ́ pé èèyàn ò lè pàdánù ìgbàlà tó ti ní, á jẹ́ pé ìkìlọ̀ yẹn ò wúlò nìyẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni tó ti ní ìgbàlà tẹ́lẹ̀ lè pàdánù rẹ̀ tó bá lọ ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì. Bí àpẹẹrẹ, Hébérù 10:26 sọ pé: “Bí a bá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà lẹ́yìn rírí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ gbà, kò tún sí ẹbọ kankan tí ó ṣẹ́ kù fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.”—Hébérù 6:4-6; 2 Pétérù 2:20-22.
Jésù jẹ́ ká mọ bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn má sọ ìgbàgbọ́ rẹ̀ nù nígbà tó fi ara ẹ̀ wé àjàrà, tó sì fi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wé àwọn ẹ̀ka àjàrà náà. Èso táwọn kan nínú wọn bá so tàbí àwọn ohun tí wọ́n bá ṣe ló máa fi hàn pé wọ́n nígbàgbọ́ nínú rẹ̀, àmọ́ tí ìgbàgbọ́ ọmọlẹ́yìn kan bá jó rẹ̀yìn, tí kò sì so èso mọ́, ṣe ní “a ó ya á dà nù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kan [tí kò léso],” kò sì ní rígbàlà. (Jòhánù 15:1-6) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà tún lo àpèjúwe tó jọ ìyẹn, ó sọ pé àwọn Kristẹni tí kò di ìgbàgbọ́ wọ́n mú “ni a óò ké kúrò.”—Róòmù 11:17-22.
Bíbélì pàṣẹ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” (Mátíù 24:42; 25:13) Àwọn tí wọ́n bá sùn lọ nípa tẹ̀mí máa pàdánù ìgbàlà wọn, bóyá torí wọ́n ṣe “àwọn iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti òkùnkùn” tàbí wọ́n ò ṣe gbogbo ohun tí Jésù pàṣẹ pé ká ṣe.—Róòmù 13:11-13; Ìṣípayá 3:1-3.
Ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tí wọ́n ti rí ìgbàlà ṣì gbọ́dọ̀ fara dà á títí dé òpin. (Mátíù 24:13; Hébérù 10:36; 12:2, 3; Ìṣípayá 2:10) Inú àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ dùn nígbà tí wọ́n gbọ́ pé àwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ bíi tiwọn ń fi ìgbàgbọ́ fara dà á. (1 Tẹsalóníkà 1:2, 3; 3 Jòhánù 3, 4) Ṣé ó wá bọ́gbọ́n mu láti sọ pé ẹni tí kò bá fara dà á máa rí ìgbàlà, tó sì jẹ́ pé Bíbélì tẹnu mọ́ ọn pé ó pọn dandan kèèyàn fara dà á?
Ìgbà tó kù díẹ̀ kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kú ló tó lè sọ pé ìgbàlà òun ti dájú. (2 Tímótì 4:6-8) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, ó mọ̀ pé ìgbàlà lè bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́ tóun bá gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara láyè. Ó kọ̀wé pé: “Mo ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú, pé, lẹ́yìn tí mo bá ti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, kí èmi fúnra mi má bàa di ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà lọ́nà kan ṣáá.”—1 Kọ́ríńtì 9:27; Fílípì 3:12-14.