Kí Ló Lè Fún Mi Ní Ìrètí?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì sọ pé Ọlọ́run fẹ́ fún wa ní “ọjọ́ ọ̀la kan àti ìrètí kan.” a (Jeremáyà 29:11) Lóòótọ́, ara ohun tó mú kí Ọlọ́run fún wa ní Bíbélì ni pé “kí a lè ní ìrètí . . . nípasẹ̀ ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́.” (Róòmù 15:4) Bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì máa fi wá lọ́kàn balẹ̀ lójoojúmọ́, àwọn ìlérí tó wà nínú rẹ̀ sì màa jẹ́ ká nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.
A máa sọ̀rọ̀ nípa
Báwo ni Bíbélì ṣe ń fọkàn wa balẹ̀?
Bíbélì máa ń fi wá lọ́kan balẹ̀ ní ti pé ó sọ àwọn ohun pàtó tá a lè ṣe táá mú kí ayé wa dáa sí i. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn àpẹẹrẹ yìí.
Máa jẹ́ kí Bíbélì tọ́ ẹ sọ́nà. Sáàmù 119:105 sọ pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi àti ìmọ́lẹ̀ fún ọ̀nà mi.” Àwọn ohun méjì kan wà tí fìtílà tó mọ́lẹ̀ dáadáa lè ṣe. Ó lè jẹ́ ká rí nńkan tó wà níwájú wa kedere, ó sì lè jẹ́ ká róhun tó wà lọ́ọ̀ọ́kán tààrà. Lọ́nà kan náà, àwọn ìlànà Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tó wà níwájù wa, ìyẹn sì máa ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé kò sí bí nǹkan ṣe burú tó, ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì lè sọ agbára wa dọ̀tun, kó sì ‘mú ọkàn wa yọ̀.’ (Sáàmù 19:7, 8) Kò tán síbẹ̀ o, Bíbélì tún jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan àgbàyanu tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún àwa èèyàn àti ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ iwájú. Ìrètí yìí lè fún wa ní ayọ̀, ko sì jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀.
Jẹ́ kí àwọn míì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tá a bá ní ìṣòro tó lágbára, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká yẹra fún àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kò bọ́gbọ́n mu ká ṣe bẹ́ẹ̀, torí ìyẹn lè jẹ́ ká ṣe àwọn ohun tí ò mọ́gbọ́n dání. (Òwe 18:1) Àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ á ràn wá lọ́wọ́ ká lè fiyè dénú. Wọ́n lè fún wa nímọ̀ràn tó máa jẹ́ ká lè kojú ìṣòro. (Òwe 11:14) Kò mọ síbẹ̀ o, wọ́n lè tù wá nínú, wọ́n lè mú ká túra ká, kí wọ́n sì fún wa lókun láti fara dà á títí dìgbà tí nńkan á fi sunwọ̀n sí i.—Òwe 12:25.
Gbàdúrà sí Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Ju ẹrù rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà, yóò sì gbé ọ ró. Kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú láé.” b (Sáàmù 55:22) Torí náà, ó bá a mu wẹ́kú bí Bíbélì ṣe pe Jèhófà ní “Ọlọ́run tó ń fúnni ní ìrètí.” (Róòmù 15:13) O lè gbàdúrà sí i nípa ‘gbogbo ohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn,’ jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ó máa bójú tó ẹ. (1 Pétérù 5:7, àlàyé ìsàlẹ̀) Kódà, Bíbélì sọ pé: ‘Ó máa fún ẹ lókun, ó máa sọ ẹ́ di alágbára, ó sì máa fẹsẹ̀ ẹ múlẹ̀ gbọn-in.’—1 Pétérù 5:10.
Jẹ́ kí àdánwò tó ò ń kojú mú kí ìrètí rẹ túbọ̀ lágbára. Bíbélì ṣèlèrí pé: “Ẹni tó ń fetí sí [Ọlọ́run] á máa gbé lábẹ́ ààbò, ìbẹ̀rù àjálù kò sì ní yọ ọ́ lẹ́nu.” (Òwe 1:33) Ìjì kan tó jà ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà ba ilé obìnrin kan tó ń jẹ́ Margaret jẹ́, ọ̀pọ̀ nǹkan ìní rẹ̀ ló sì ṣòfò. Àmọ́ dípò kó kárísọ, ó kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan pé àwọn nǹkan ìní tara kì í tọ́jọ́. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, ó pinnu pé àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù ni òun á gbájú mọ́, ìyẹn àwọn ẹbí àtọ̀rẹ́, àjọṣe ẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run àti ìrètí tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.—Sáàmù 37:34; Jémíìsì 4:8.
Ìrètí wo ni Bíbélì fún àwa èèyàn?
Bíbélì ṣèlèrí pé láìpẹ́ nǹkan á máa lọ dáadáa fún àwa èèyàn, ilẹ̀ ayé á sì di Párádísè. Ọjọ́ ọ̀la yẹn ò sì ní pẹ́ mọ́. Àwọn ìṣòró tí àwa èèyàn ń kojú lónìí jẹ́ ká mọ̀ pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ayé yìí là wà. (2 Tímótì 3:1-5) Láìpẹ́, Ọlọ́run máa tún ayé ṣe, á sì fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ àti ìyà. Bíbélì sọ pè Ìjọba Ọlọ́run tó máa kárí gbogbo ayé ni Ọlọ́run máa lò. (Dáníẹ́lì 2:44; Ìfihàn 11:15) Ìjọba ọ̀run yìí ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú àdúrà tá a mọ̀ sí àdúra Olúwa níbi tó ti sọ́ pé: “Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé.”—Mátíù 6:9, 10.
Bíbélì sọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run fún àwa èèyàn. Wo díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú kúrò:
Kò ní sí ebi mọ́. “Ilẹ̀ yóò mú èso jáde.”—Sáàmù 67:6.
Kò ní sí àìsàn mọ́. “Kò sí olùgbé kankan tó máa sọ pé: ‘Ara mi ò yá.’”—Àìsáyà 33:24, àlàyé ìsàlẹ̀.
Kò ní sí ikú mọ́. Ọlọ́run “máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìfihàn 21:3, 4.
a Tí nǹkan bá wù wá, a máa retí ẹ̀ torí a gbà pé ọwọ́ wa máa tẹ̀ ẹ́. Bákan náà, ìrètí ni nǹkan tí à ń fojú sọ́nà fún tàbí ohun tí à ń retí.
b Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.