Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Òmìnira Láti Yan Ohun Tó Wuni? Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Darí Gbogbo Nǹkan?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Òmìnira Láti Yan Ohun Tó Wuni? Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Darí Gbogbo Nǹkan?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ọlọ́run fún wa ní òmìnira láti yan ohun tó wù wá, ó gbà wá láyè láti dá ṣèpinnu dípò tí a ó fi máa retí pé kí Ọlọ́run tàbí kádàrá pinnu ohun tá a fẹ́ ṣe. Wo ohun tí Bíbélì sọ.

  •   Ọlọ́run dá èèyàn ní àwòrán rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Àwa èèyàn yàtọ̀ sí àwọn ẹranko, torí pé ọgbọ́n àdámọ́ni ló ń darí wọn, àmọ́ àwa èèyàn jọ Ẹlẹ́dàá torí pé a ní àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo. Bíi ti Ẹlẹ́dàá wa, a ní òmìnira láti yan ohun tó wù wá.

  •   Dé ìwọ̀n àyè kan, a lè pinnu bí ọjọ́ ọ̀la wa ṣe máa rí. Bíbélì rọ̀ wá pé ká “yan ìyè . . . nípa fífetí sí ohùn [Ọlọ́run],” ìyẹn ni pé ká máa ṣègbọràn sí àwọn òfin rẹ̀. (Diutarónómì 30:19, 20) Ohun tí Bíbélì sọ yìí kò ní já mọ́ nǹkan kan, kò sì ní nítumọ̀ tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run kò fún wa láǹfààní láti yan ohun tó wù wá. Dípò kó máa fipá mú ká ṣe ohun tó sọ, ńṣe ni Ọlọ́run ń fi ìfẹ́ rọ̀ wá pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò.”—Aísáyà 48:18.

  •   Torí náà, kádàrá kọ́ ló máa pinnu bóyá a ó ṣàṣeyọrí tàbí a kò ní ṣàṣeyọrí. A gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára tí a bá fẹ́ ṣàṣeyọrí nínú ohun tá a dáwọ́ lé. Bíbélì sọ pé “Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é.”(Oníwàásù 9:10) Ó tún sọ pé: “Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.”—Òwe 21:5.

 Òmìnira tá a ní láti ṣe ohun tó wù wá jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Torí náà, ńṣe ló yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú “gbogbo ọkàn” wa torí pé ohun tó wù wá láti ṣe nìyẹn.—Mátíù 22:37.

Ṣé kì í ṣe Ọlọ́run ló ń darí gbogbo nǹkan ni?

 Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ni Olódùmarè àti pé kò sí ẹni tó lágbára tó o. (Jóòbù 37:23; Aísáyà 40:26) Àmọ́, kì í ṣe gbogbo nǹkan ló ń fi agbára rẹ̀ darí. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Ọlọ́run lo “ìkóra-ẹni-níjàánu” fún àwọn ará Bábílónì to jẹ́ ọ̀tá àwọn èèyàn rẹ̀. (Aísáyà 42:14) Bákan náà lónìí, ó yàn láti fàyè gba àwọn tó ń ṣi òmìnira wọn lò tí wọ́n sì ń ṣe ìpalára fáwọn ẹlòmíì. Àmọ́, Ọlọ́run kò ní fàyè gbà wọ́n títí láé.—Sáàmù 37:10, 11.