Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ

Fi Iṣẹ́ Sílẹ̀ “Síbi Iṣẹ́“

Fi Iṣẹ́ Sílẹ̀ “Síbi Iṣẹ́“

 Níbi tí ìmọ̀ ẹ̀rọ ti mú kí nǹkan ṣeé ṣe dé lónìí, àwọn agbanisíṣẹ́, àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni àtàwọn oníbàárà máa ń retí pé ó yẹ kéèyàn lè ṣiṣẹ́ nígbàkigbà àti níbikíbi. Àmọ́, èyí ń mú kí iṣẹ́ pa àwọn nǹkan míì lára, ó sì ń mú kó ṣòro láti bójú tó àwọn ohun tó ṣe pàtàkì títí kan ìgbéyàwó.

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀

  •   Ẹ̀rọ ìgbàlóde lè mú kéèyàn máa lo àkókò tó yẹ kó lò pẹ̀lú ìdílé rẹ̀ láti fi ṣiṣẹ́. Tí iṣẹ́ ọjọ́ kan bá tiẹ̀ ti parí, tí ìpè tàbí àtẹ̀jíṣẹ́ láti ibi iṣẹ́ sì wọlé sorí fóònù, ó lè dà bí ohun tó o gbọ́dọ̀ bójú tó lójú ẹsẹ̀.

     “Tẹ́lẹ̀, téèyàn bá ti parí iṣẹ́ ọjọ́ kan, á lọ sílé lọ sinmi, á sì lo àkókò pẹ̀lú ìdílé rẹ̀. Àmọ́ ńṣe ni ìpè àti àtẹ̀jíṣẹ́ láti ibi iṣẹ́ ti ń mú kí ìyẹn ṣòro láti ṣe báyìí, ìgbéyàwó sì ń di ohun tí ọ̀pọ̀ ń fi ọwọ́ rọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.”​—Jeanette.

  •   Tí o kò bá fẹ́ kí iṣẹ́ ṣàkóbá fún ìdílé rẹ, àfi kó o wá nǹkan ṣe nípa ẹ̀. Tí o kò bá ṣètò ara ẹ, iṣẹ́ lè ṣàkóbá fún ìgbéyàwó rẹ.

     “Kó o tó mọ, o ti pa ẹni kejì ẹ tì, torí ńṣe ni wàá máa rò ó lọ́kàn ẹ pé, ‘ó máa yé e, kò ní bínú, á dárí jì mí. Màá wáyè fún un lọ́jọ́ míì.’”​—Holly.

 Àbá lórí bá a ṣe lè fi iṣẹ́ sí àyè rẹ̀

  •   Ka ìgbéyàwó rẹ sí pàtàkì. Bíbélì sọ pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí èèyàn kankan má ṣe yà á.” (Mátíù 19:6) Bí oò ṣe ní gbà kí ẹnì kankan ya ìwọ àtẹni tó o fẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ kó o sapá tó láti má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ da ìgbéyàwó rẹ rú.

     “Àwọn kan tí mo ṣiṣẹ́ fún máa ń rò pé, torí pé àwọn ń sanwó iṣẹ́ mi, mo gbọ́dọ̀ dá wọn lóhùn nìgbàkígbà tí wọ́n bá ń wá mi. Àmọ́ torí pé mo ka ìgbéyàwó mi sí pàtàkì, mo jẹ́ kó yé wọn pé mi ò ní lè dá wọn lóhùn láwọn ọjọ́ tí mi ò bá sí níbi iṣẹ́, àti pé màá kàn sí wọn láìpẹ́.”​—Mark.

     Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé bí mo ṣe ń ṣe fi hàn pé mo ka ìgbéyàwó mi sí pàtàkì ju iṣẹ́ mi lọ?’

  •   Kọ àwọn iṣẹ́ kan, tó bá máa dí ẹ lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n wà lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n mọ̀wọ̀n ara wọn.” (Òwe 11:2) Ẹni tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀ kì í gba gbogbo iṣẹ́, ó lè gbé iṣẹ́ náà fún ẹlòmiì láti ṣe láwọn ìgbà tó bá pọndandan.

     “Iṣẹ́ púlọ́ńbà ni mò ń ṣe, torí náà tí nǹkan kan bá bà jẹ́ nílé àwọn èèyàn tí wọ́n sì nílò mi ní kíákíá, ara wọn kìí balẹ̀ rárá. Ohun tí mo máa ń ṣe ni pé, tí mo bá ti rí i pé mi ò ní lè débẹ̀ láàárín àkókó tí ẹni náà fẹ́, màá darí wọn sọ́dọ̀ púlọ́ńbà míì tó lè bá wọn ṣe é.”​—Christopher.

     Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo ṣe tán láti kọ iṣẹ́ kan tí mo bá rí i pé ó lè mú kí n pa ẹni kejì mi tì? Ṣé ẹni kejì mi jẹ́rìí mi pé màá ṣe bẹ́ẹ̀?’

  •   Ẹ ṣètò láti lo àkókò pa pọ̀. Bíbélì sọ pé: “Ohun gbogbo ni àkókò wà fún.” (Oníwàásù 3:1) Tí iṣẹ́ bá pọ̀, tí ọwọ́ rẹ sì dí, ìgbà yẹn gan-an ló yẹ kó o ṣètò àkókò pàtó tó o máa lò pẹ̀lú ẹni kejì rẹ, kó o sì rí i dájú pé o ṣe bẹ́ẹ̀.

     “Tí iṣẹ́ bá pọ̀ tí ọwọ́ wa sì dí gan-an, a máa ń fẹnu kò lórí àkókò kan pàtó tí a máa lò pa pọ̀, kódà bí ò tiẹ̀ ju pé ká jọ jẹun alẹ́ pọ̀ tàbí ká rìn lọ sí etíkun níbi tí kò sí ẹni tó máa dí wa lọ́wọ́.”​—Deborah.

     Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo máa ń ṣètò àkókò kan pàtó tí màá lò pẹ̀lú ẹnì kejì mi láìsí ìdíwọ́ kankan? Ṣé ẹni kejì mi gbà pé mo máa ń ṣe bẹ́ẹ̀?’

  •   Gbé àwọn ẹ̀rọ alágbèéká rẹ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Bíbélì sọ pé: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:10) Nígbà míì, ṣé o lè pa àwọn ẹ̀rọ alágbèéká rẹ, kí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ má bàa ṣèdíwọ́ fún ẹ?

     “Mo ti pinnu àkókò tí màá ṣíwọ́ iṣẹ́ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan. Tó bá sì ti di àkókò yẹn, mo máa ń pa ètò ìṣiṣẹ́ tó lè gbé ìsọfúnni wọlé sórí fóònù mi.”​—Jeremy.

     Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ó máa ń ṣe mi bíi pé kí n ṣì tan íńtánẹ́ẹ̀tì mi sílẹ̀ kí n lè mọ̀ tí ọ̀gá mi tàbí oníbàárà mi bá fẹ́ kí n bá òun ṣe nǹkan kan? Kí ni ẹni kejì máa sọ nípa mi lórí ọ̀rọ̀ yìí?’

  •    Fọgbọ́n ṣe é. Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.” (Fílípì 4:5) Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, iṣẹ́ lè gba pé kéèyan yááfì àkókò tó fẹ́ lò nílé pẹ̀lú ẹnì kejì rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, irú iṣẹ́ tẹ́nì kan ń ṣe lè gba pé kó wà lárọ̀ọ́wótó láti dáhùn ìpè tàbí àtẹ̀jíṣẹ́ lẹ́yìn àkókò iṣẹ́. Ní irú ipò bẹ́ẹ̀, kò bọ́gbọn mu kó o má retí pé kí ẹnì kejì rẹ lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú rẹ ju ohun tó lè yọ̀ǹda lọ.

     “Iṣẹ́ àdáni ni ọkọ mi ń ṣe, ìgbà míì sì wà tó ní láti bójú tó àwọn nǹkan kan ní pàjáwìrì lẹ́yìn iṣẹ. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó máa ń dùn mí, àmọ́ torí pé a ṣì máa ń lo àkókò to pọ̀ pa pọ̀, nǹkan ń lọ bó ṣe yẹ.”​—Beverly.

     Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo máa ń gba ti ẹnì kejì mi rò tí ọwọ́ bá dí? Ṣé mi ò sì kí ń béèrè ju ohun tí agbára ẹ gbé láti ṣe lọ? Báwo ni ẹni kejì mi ṣe máa dáhùn ìbéèrè yìí?’

 Ẹ jọ sọ ọ́

 Lákọ̀ọ́kọ́, kí ẹ̀yin méjéèjì ka àwọn ìbéèrè yìí lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Lẹ́yìn náà, ẹ jọ jíròrò ìdáhùn yín pa pọ̀.

  •   Ṣé ẹnì kejì ẹ ti sọ fún ẹ rí pé ò ń lo àkókò tó yẹ kó o lò nílé fún iṣẹ́? Ṣé o gbà bẹ́ẹ̀ lóòótọ́?

  •   Àwọn nńkan wo lo rò pé o lè ṣe kí iṣẹ́ má bàá ṣàkóbá fún ìdílé rẹ?

  •   Ṣé o rò pé ó ṣòro fún ẹnì kejì ẹ láti fi iṣẹ́ sí “àyè iṣẹ́”? Àwọn àpẹẹrẹ wo lo rí tó o fi rò bẹ́ẹ̀?

  •   Àwọn àyípadà wo lo fẹ́ kí ẹnì kejì rẹ ṣe lórí ọ̀rọ̀ àkókò tó ń lò fún iṣẹ́ àti èyí tó ń lò pẹ̀lú rẹ?