Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ÌGBÉYÀWÓ

Ẹ Máa Wáyè fún Ara Yín

Ẹ Máa Wáyè fún Ara Yín

 Ọ̀pọ̀ ọkọ àti aya ni kì í ráyè bára wọn sọ̀rọ̀, kódà bí wọ́n bá jọ wà níbì kan náà. Kí ló fà á tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀?

 Kí nìdí táwọn tọkọtaya kan kì í fi í ráyè bára wọn sọ̀rọ̀?

  •   Ó ti máa ń rẹ̀ wá jù

     “Nígbà tí àyè bá yọ fún èmi àti ọkọ mi láti bára wa sọ̀rọ̀, ó lè ti rẹ̀ ẹ́ tàbí kó ti rẹ̀ mí. Tó bá sì ti rẹ̀ mí, ara máa ń kan mí. Ó kúkú sàn ká máa wo tẹlifíṣọ̀n.”—Anna.

  •   Fóònù àtàwọn ìkànnì àjọlò

     “Ìkànnì àjọlò àti eré ìnàjú orí Íńtánẹ́ẹ̀tì máa ń gbani lákòókò. Èèyàn lè lo ọ̀pọ̀ wákàtí nídìí wọn, kó má sì bá ọkọ tàbí aya rẹ̀ sọ̀rọ̀ rárá. Nígbà míì, ẹ tiẹ̀ lè jọ wà nínú ilé kí kálukú sì máa tẹ fóònù ẹ̀.”—Katherine.

  •   Èyí-wù-mí-ò-wù-ọ́

     “Tí ọkọ mi bá ti ibi iṣẹ́ dé, ó láwọn nǹkan tó fẹ́ràn láti máa ṣe. Ó sì yẹ kó gbádùn ara ẹ̀ lóòótọ́ torí pé ó máa ń ṣiṣẹ́ gan-an. Ṣùgbọ́n ì bá wù mí káwa méjèèjì túbọ̀ máa lo àkókò pa pọ̀.”—Jane.

  •   Iṣẹ́

     “Ẹ̀rọ ìgbàlódé ò jẹ́ kéèyàn mọ ìyàtọ̀ láàárín ibi iṣẹ́ àti inú ilé mọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń fi àkókò tó yẹ kí n fi wà pẹ̀lú ìyàwó mi fèsì ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí mi lorí Íńtánẹ́ẹ̀tì.”—Mark.

 Ohun tó o lè ṣe

  •   Fi sọ́kàn pé ó ṣe pàtàkì kó o wáyè fún ẹnì kejì ẹ.

     Ìlànà Bíbélì: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:10.

     Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé ìwà rẹ fi hàn pé o ka ìgbéyàwó rẹ sí pàtàkì ju iṣẹ́ tàbí àwọn nǹkan tó o fẹ́ràn lọ? Ṣé ìgbà tí ọwọ́ ẹ bá dilẹ̀ lo tó máa ń rí ti ẹnì kejì ẹ rò?

     Ìmọ̀ràn: Ẹ má ṣe dúró dìgbà táyè bá yọ fún yín. Ṣètò àkókò tí ẹ̀yin méjèèjì nìkan á fi máa wà pa pọ̀.

     “Ó máa ń dùn mọ́ mi tí ọkọ mi bá ṣètò ohun tó máa pa èmi àti ẹ̀ nìkan pọ̀. Ó máa ń jẹ́ kí n mọ̀ pé ó kà mí sí gan-an àti pé ó wù ú láti wà pẹ̀lú mi. Ìyẹn ń mú kí emi náà túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”—Anna.

  •   Mọ ìgbà tó yẹ kó o pa kọ̀ǹpútà tàbí fóònù rẹ tì.

     Ìlànà Bíbélì: “Ohun gbogbo ni àkókò wà fún.”—Oníwàásù 3:1.

     Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé ọ̀pọ̀ ìgbà ni àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí ìsọfúnni tó ń wọlé sórí fóònù rẹ kì í jẹ́ kó o ráyè pọkàn pọ̀ tí ẹnì kejì ẹ bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀?

     Ìmọ̀ràn: Ẹ gbìyànjú kẹ́ ẹ jọ máa jẹun pọ̀, ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́, kẹ́ ẹ sì máa fi fóònù yín sínú yàrá míì. Bẹ́ ẹ ṣe ń jẹun, ẹ lè jọ máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tí kálukú yín ṣe lọ́jọ́ yẹn.

  •   Tó bá ṣeé ṣe, ẹ jọ lọ sọ́jà tàbí kẹ́ ẹ jọ ṣiṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ilé.

     Ìlànà Bíbélì: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan lọ, nítorí pé wọ́n ní èrè púpọ̀ fún iṣẹ́ àṣekára wọn.”—Oníwàásù 4:9, àlàyé ìsàlẹ̀.

     Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé ọ̀pọ̀ ìgbà ni kálukú yín máa ń dá lọ ra àwọn nǹkan tẹ́ ẹ nílò nílé?

     Ìmọ̀ràn: Ẹ jọ pawọ́ pọ̀ ṣiṣẹ́, kódà kó jẹ́ ohun tí ẹnì kan lè dá ṣe.

     “Dípò kẹ́ ẹ máa wo ríra oúnjẹ sílé, fífọ abọ́, kíká aṣọ àti ṣíṣiṣẹ́ nínú ọgbà bí ara iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ téèyàn ń ṣe nínú ilé, ẹ rí wọn bí ohun tó máa mú kẹ́ ẹ jọ wà pa pọ̀.”—Nina.

  •    Ẹ máa gba tara yín rò

     Ìlànà Bíbélì: “Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.”—Fílípì 4:5.

     Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Báwo ni ohun tó ò ń retí látọ̀dọ̀ ọkọ tàbí aya rẹ ṣe lè fi hàn pé ò ń fòye báni lò?

     Ìmọ̀ràn: Ẹ jọ sọ̀rọ̀, kẹ́ ẹ lè mọ ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan yín fẹ́. Ẹ pinnu bẹ́ ẹ ṣe máa lo àkókò yín lọ́nà táá mú kí ẹ̀yin méjèèjì máa láyọ̀.

     “Ara ọkọ mì le dáadáa, ṣùgbọ́n àìlera ò jẹ́ kára tèmi fi bẹ́ẹ̀ gbé kánkán. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń ní kí ọkọ mi lọ dára yá níta, tí màá sì sọ fún un pé àá máa ríra tó bá dé. Èmi á dúró sílé torí pé mo nílò ìsinmi, òun á sì lọ síta torí eré ìmárale tó nílò. Ara máa ń tu àwa méjèèjì torí pé a fún ara wa ní ohun tá a fẹ́.”—Daniela.

 Ohun tẹ́ ẹ lè jọ jíròrò

 Kálukú yín lè kọ́kọ́ dá ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí. Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ jọ jíròrò ìdáhùn sáwọn ìbéèrè náà.

  •    Ṣé o lè sọ pé ìwọ àti ẹnì kejì rẹ jọ ń lo àkókò tó pọ̀ tó ní báyìí?

  •   Kí ni ọkọ tàbí aya rẹ ti ṣe kó lè lo àkókò tó pọ̀ tó pẹ̀lú rẹ tí wàá sì fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún?

  •   Ọ̀nà wo lo máa fẹ́ kí ọkọ tàbí aya rẹ gbà sunwọ̀n sí i?

  •   Ṣé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ẹ̀rọ ìgbàlódé kì í jẹ́ kó o ráyè pọkàn pọ̀ sórí ohun tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ ń sọ?

  •   Báwo ni ohun tí ẹ̀yin méjèèjì ń retí látọ̀dọ̀ ara yín ṣe lè fi hàn pé ẹ̀ ń fòye bára yín lò?

  •   Àtúnṣe wo ni kálukú yín lè ṣe lọ́sẹ̀ yìí kẹ́ ẹ lè jọ lo àkókò pa pọ̀?