TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?
Bí Àwọn Sẹ́ẹ̀lì Ṣe Ń Pín Tí Wọ́n sì Ń Ṣiṣẹ́ Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
Tí obìnrin bá ṣẹ̀ṣẹ̀ lóyún, oyún inú ẹ̀ kì í ju bíńtín bí orí abẹ́rẹ́, kódà a ò lè fojú lásán rí i. Síbẹ̀ láàárín oṣù mélòó kan, oyún ọjọ́sí tó jẹ́ sẹ́ẹ̀lì kékeré á di ọmọ làǹtì-lanti. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé sẹ́ẹ̀lì kékeré yìí máa ń pín ara ẹ̀ sí kéékèèké títí tó fi máa pín ara ẹ̀ sí onírúurú sẹ́ẹ̀lì tó lé ní igba (200). Àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí yàtọ̀ síra, wọn tóbi ju ara wọn lọ, iṣẹ́ wọn sì yàtọ̀ síra.
Rò ó wò ná: Sẹ́ẹ̀lì kékeré yìí máa ń ṣe ẹ̀dà DNA ara ẹ̀, á wá pín sí méjì. Sẹ́ẹ̀lì náà á wá máa ṣe bẹ́ẹ̀ léraléra. Gbogbo àwọn sẹ́ẹ̀lì tuntun yìí máa ń kọ́kọ́ jọra wọn. Àmọ́ nínú DNA wọn, sẹ́ẹ̀lì kọ̀ọ̀kan ti láwọn ìsọfúnni tó nílò láti ṣe onírúurú sẹ́ẹ̀lì tó máa para pọ̀ di ọmọ náà.
Láàárín ọ̀sẹ̀ kan tí obìnrin bá lóyún, àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí á pín sí oríṣi méjì. Àwọn kan á para pọ̀ di ọmọ, àwọn kan á sì di ibi ọmọ àtàwọn iṣan ara míì tó máa jẹ́ kí ọmọ náà dàgbà nínú ikùn.
Tó bá fi máa di ọ̀sẹ̀ kẹta, àwọn sẹ́ẹ̀lì ọmọ náà máa kóra jọ sí ipele mẹ́ta. Ipele àkọ́kọ́ máa di àwọn iṣan, ọpọlọ, ẹnu àti awọ ara àtàwọn sẹ́ẹ̀lì míì. Ipele kejì máa di ẹ̀jẹ̀, egungun, kíndìnrín àtàwọn iṣan míì. Àwọn sẹ́ẹ̀lì ipele kẹta máa di àwọn ẹ̀yà ara míì bí ẹ̀dọ̀fóró, àpò ìtọ̀ àtàwọn ẹ̀yà tó ń jẹ́ kí oúnjẹ dà lára.
Ní gbogbo ìgbà tí ọmọ náà fi wà nínú ikùn ìyá rẹ̀, àwọn sẹ́ẹ̀lì kan máa ń kúrò lápá ibì kan lọ sí ibòmíì. Àwọn míì máa kóra jọ pọ̀ di ẹ̀yà ara. Káwọn nǹkan tó díjú yìí tó lè ṣẹlẹ̀, ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ gbọ́dọ̀ máa darí wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn sẹ́ẹ̀lì kan máa ń lọ́ ara wọn pọ̀, wọ́n á sì di túùbù tín-ín-rín. Èyí sì máa ń ṣẹlẹ̀ káàkiri nínú gbogbo ara ọmọ náà. Tó bá yá, àwọn túùbù tín-ín-rín yìí á bẹ̀rẹ̀ sí í gùn, wọ́n á sì máa so kọ́ra títí táá fi di èyí tó ń gbé ohun tára nílò káàkiri.
Tí wọ́n bá fi máa bí ọmọ náà, ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù sẹ́ẹ̀lì tó wà lára ẹ̀ á ti níṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe, wọ́n á sì ti wà níbi tó yẹ kí wọ́n wà lákòókò tó yẹ.
Kí lèrò ẹ? Ṣé bí àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí ṣe ń pín tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kàn ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló dá a?