ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Kí Ni Mo Lè Ṣe Táwọn Òbí Mi Bá Kọra Wọn Sílẹ̀?
Ọ̀kan lára ìṣòro tó nira fáwọn ọ̀dọ́ láti fara dà ni káwọn òbí wọn kọra wọn sílẹ̀. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, kí lo lè ṣe láti fara da ìṣòro yìí?
Nínú àpilẹ̀kọ yìí
Àwọn ohun mẹ́ta tí kò yẹ kó o ṣe
1. Má ṣe dá ara ẹ lẹ́bi
“Mọ́mì mi sọ fún mi pé àtìgbà táwọn ti bí mi láàárín àwọn àti dádì mi ti dàrú, ìyẹn ló mú kí n gbà pé èmi ni mo fà á tí wọ́n fi kọra wọn sílẹ̀.”—Diana.
Fi sọ́kàn pé: Ìwọ kọ́ lo fà á táwọn òbí ẹ fi kọra wọn sílẹ̀, àárín àwọn méjèèjì nìṣòro náà wà. Torí náà, àwọn ló lè yanjú ìṣòro náà, kì í ṣe ìwọ. Ọwọ́ wọn ló wà tí wọ́n bá fẹ́ kí ìṣòro náà yanjú.
2. Má ṣe di àwọn òbí ẹ sínú
“Ohun tí dádì mi ṣe fún mọ́mì mi dùn mí gan-an, á pẹ́ kí n tó lè fọkàn tán wọn.”—Rianna.
Fi sọ́kàn pé: Ó ṣeé ṣe kí ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn òbí ẹ máa múnú bí ẹ. Ó ṣe tán, kò sẹ́ni tírú ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ sí tínú ẹ̀ máa dùn. Àmọ́, kò dáa kó o máa di èèyàn sínú torí ó lè dá àìsàn sí ẹ lára, ó sì lè mú kó o máa bínú lódìlódì. Abájọ táwọn kan fi sọ pé téèyàn bá ń bínú sí ẹnì kan, ṣe ló dà bí ìgbà téèyàn mu májèlé tó wá ń retí pé kẹ́ni tóun ń bínú sí máa ṣàìsàn. a
3. Má ṣe rò pé o ò lè ní ìdílé aláyọ̀
“Ṣe ló ń ṣe mí bíi pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí dádì mi máa ṣẹlẹ̀ sí èmi náà. Ọkàn mi ò balẹ̀, torí gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi ni pé témi náà bá lọ́kọ, tí mo sì bímọ ìdílé mi máa túká bíi tàwọn òbí mi.”—Jessica.
Fi sọ́kàn pé: Ti pé àwọn òbí ẹ kọra wọn sílẹ̀ ò túmọ̀ sí pé ìdílé tìẹ náà máa dàrú. Kódà, ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn òbí ẹ. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ kó o túbọ̀ fara balẹ̀ wo ìwà tẹ́nì kan ní kó o tó pinnu láti fẹ́ ẹni náà. Bákan náà, ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn òbí ẹ lè jẹ́ kó o túbọ̀ láwọn ìwà tó dáa kó o lè di ọkọ tàbí aya rere.
Àwọn ohun mẹ́ta tó yẹ kó o ṣe
1. Sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ. Àwọn tí kì í sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn fáwọn èèyàn sábà máa ń ṣe àwọn nǹkan tó lè wu wọ́n léwu, bíi kí wọ́n máa lo oògùn olóró tàbí mu ọtí lámujù. Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tiẹ̀ le tó yẹn, kàkà bẹ́ẹ̀ gbìyànjú láti tẹ̀ lé àwọn àbá yìí:
Bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀. Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni dádì ẹ tàbí mọ́mì ẹ àbí àwọn méjèèjì máa ń sọ àwọn ìṣòro tí wọ́n ní nínú ìgbéyàwó wọn fún ẹ, fi sùúrù ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún wọn. Tó ò bá lè bá wọn sọ ọ́ lójúkojú, o lè kọ lẹ́tà sí ọ̀kan nínú wọn tàbí àwọn méjèèjì.
Sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ fún ọ̀rẹ́ ẹ tó o fọkàn tán. Tó o bá sọ gbogbo bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ fún ẹnì kan, ara máa tù ẹ́. Bíbélì sọ pé “ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”—Òwe 17:17.
Gbàdúrà sí Ọlọ́run. “Olùgbọ́ àdúrà” ni Jèhófà Ọlọ́run, ó sì ṣe tán láti tẹ́tí sí ẹ. (Sáàmù 65:2) Bíbélì sọ pé kó o ‘kó gbogbo àníyàn ẹ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, torí ó ń bójú tó ẹ.’—1 Pétérù 5:7.
Nínú dádì àti mọ́mì ẹ, ta ló rọrùn fún ẹ láti bá sọ̀rọ̀?
Èwo nínú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ bóyá tẹ́ ẹ jọ wà lọ́jọ́ orí tàbí tó jù ẹ́ lọ lo lè máa fọ̀rọ̀ lọ̀?
Àwọn ọ̀rọ̀ wo lo lè máa fi sádùúrà?
2. Gbà pé nǹkan ti yí pa dà
Bí àwọn òbí ẹ ṣe kọra wọn sílẹ̀ lè jẹ́ káwọn nǹkan kan yí pa dà irú bí, ilé tẹ́ ẹ̀ ń gbé, ilé-ìwé ẹ, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ títí kan iye tó ń wọlé fún yín. Òótọ́ ni pé ó lè má rọrùn fún ẹ láti ṣe àwọn àyípadà yìí, kódà ó lè mú kí gbogbo nǹkan tojú sú ẹ. Àmọ́, tó o bá gbà pé nǹkan ti yí pa dà, ìyẹn á jẹ́ kó o lè ṣe àwọn àyípadà tó yẹ nínú ipò tuntun tó o bá ara ẹ.
Àyípadà wo ló ṣòro jù fún ẹ láti ṣe nígbà táwọn òbí ẹ kọra wọn sílẹ̀?
Kí làwọn nǹkan tó o lè ṣe táá jẹ́ kó o gbà pé nǹkan ti yí pa dà?
3. Máa kíyè sí àwọn ìwà rere tó o ní
Ká sòótọ́ ọkàn ẹ lè má balẹ̀ táwọn òbí ẹ bá kọra wọn sílẹ̀. Àmọ́ tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ kó o mọ ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe. Kódà ó tún lè jẹ́ kó o lè ṣe àwọn nǹkan tó o rò pé o ò ní lè ṣe. Jeremy, táwọn òbí ẹ̀ kọra wọn sílẹ̀ nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá (13) sọ pé “Nígbà táwọn òbí mi kọra wọn sílẹ̀, mo wá rí i pé ó pọn dandan kí n kọ́ àwọn nǹkan tí mi ò mọ̀ ọ́ ṣe tẹ́lẹ̀. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo wá ń bá mọ́mì mi ṣe torí pé èmi ni àkọ́bí, mo tún máa ń tọ́jú àbúrò mi.”
Àwọn nǹkan wo lo ti wá kíyè sí pé o lè ṣe látìgbà táwọn òbí ẹ ti kọra wọn sílẹ̀?
Àwọn ìwà wo ló wù ẹ́ kó o ní?
a Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i ka àpilẹ̀kọ náà “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàkóso Ìbínú Mi?”