ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Báwo Ni Eré Ìmárale Ṣe Lè Máa Wù Mí Ṣe?
Kí nìdí tó fi yẹ kí n máa ṣe eré ìmárale?
Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ọ̀dọ́ kì í lo àkókò tó pọ̀ tó lẹ́nu eré ìmárale, ìyẹn ò sì dáa tó. Ó dájú pé ó nídìí tí Bíbélì náà fi sọ pé ‘àǹfààní wà nínú eré ìmárale.’ (1 Tímótì 4:8) Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìdí náà yẹ̀ wò:
Eré ìmárale máa mú kára tù ẹ́. Eré ìmárale máa ń jẹ́ kí ọpọlọ tú àwọn èròjà endorphins jáde sínú ara, ìyẹn àwọn èròjà tó máa ń mára tuni, tó sì máa ń jẹ́ kára ẹni yá gágá. Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé egbòogi tí kì í jẹ́ kéèyàn sorí kọ́ ni eré ìmárale jẹ́.
“Tí mo bá ti lọ sáré láàárọ̀ kùtù, ó máa ń jẹ́ kí n ṣiṣẹ́ dáadáa, mo sì tún máa ń gbádùn ara mi ṣúlẹ̀. Eré sísá máa ń jẹ́ kára mi yá gágá.”—Regina.
Eré ìmárale máa jẹ́ kí ìrísí ẹ dára sí i. Tó o bá ń ṣe eré ìmárale níwọ̀ntúnwọ̀nsì, wàá lókun sí i, ara ẹ á jí pépé sí i, ọkàn ẹ á sì túbọ̀ balẹ̀.
“Lọ́dún kan sẹ́yìn, tí mo bá ń ṣe eré ìmárale kan tí wọ́n ń pè ní chin-ups, mi ò lè ṣe ju ẹyọ kan lọ, àmọ́ ní báyìí, mo ti lè ṣe mẹ́wàá. Inú mi dùn gan-an ni. Ohun tó múnú mi dùn jù lọ ni pé mo mọ̀ pé mò ń tọ́jú ara mi.”—Olivia.
Eré ìmárale máa jẹ́ kẹ́mìí ẹ gùn. Tára wa bá le, ó má jẹ́ ká lè mí dáadáa, á sì jẹ́ kí òpó ẹ̀jẹ̀ àti ọkàn wa máa ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Eré ìmárale tó máa ń jẹ́ kéèyàn lè mí dáadáa máa ń dènà àrùn inú òpó ẹ̀jẹ̀, àrùn yìí sì jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó sábà máa ń pa àwọn èèyàn.
“Tá a bá ń ṣeré ìmárale tó ń ṣara lóore déédéé, ṣe là ń fi han Ẹlẹ́dàá wa pé a mọyì ara tó fún wa.”—Jessica.
Ohun tó yẹ kó o fi sọ́kàn: Ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí nísinsìnyí tá a bá ń ṣeré ìmárale, bá a sì ṣe ń dàgbà sí i, ara wa á máa jí pépé. Ọ̀dọ́bìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tonya sọ pé, “O ò ní kábàámọ̀ rárá tó o bá ṣeré ìmárale, bóyá tó o lọ sáré. Kò sígbà kan rí tí mo kábàámọ̀ lẹ́yìn tí mo ṣeré ìmárale tán.”
Kí ló ń dí mi lọ́wọ́?
Àwọn ìṣòro tó lè yọjú nìyí:
Kò sídìí fún un. “Nígbà táwọn èèyàn bá ṣì kéré, wọ́n máa ń rò pé kò sí itú táwọn ò lè pa. Ó máa ń ṣòro fún wọn láti gbà pé ìgbà kan ń bọ tára ò ní le dáadáa mọ́. Wọ́n rò pé àwọn àgbàlagbà nìkan ló máa ń ṣàìsàn.”—Sophia.
Kò sáyè. “Ọwọ́ mi máa ń dí gan an torí náà mo ṣètò ara mi kí n lè máa ráyè jẹ oúnjẹ aṣaralóore kí n sì sùn, àmọ́ mi ò kí ń ráyè fún eré ìmárale.”—Clarissa.
Mi ò lówó ti màá san níbi tí wọ́n ti ń ṣeré ìmárale (gym). “Owó kékeré kọ́ lèèyàn máa ná kó tó lè nílera tó dáa, o gbọ́dọ̀ sanwó kó o tó lè lọ síbi tí wọ́n ti ń ṣeré ìmárale!”—Gina.
Ohun tó yẹ kó o ronú lé:
Kí ló mú kó ṣòro fún ẹ jù lọ láti ṣeré ìmárale? O máa gba ìsapá kó o tó lè borí ìṣòro náà, àmọ́ àǹfààní tó o máa rí níbẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Báwo ni mo ṣe lè mọ eré ìmárale tá a jẹ́ kí ìlera mi dáa?
Àwọn àbá díẹ̀ rè é:
Ìwọ fúnra ẹ̀ ni kó o sapá kí ìlera rẹ lè dáa sí i.—Gálátíà 6:5.
Má ṣàwáwí. (Oníwàásù 11:4) Bí àpẹẹrẹ, kò dìgbà tó o bá forúkọ sílẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń ṣeré ìmárale (gym) kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣeré ìmárale. Wá eré ìmárale tó wù ẹ́, kó o sì máa ṣe é déédéé.
Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, o lè béèrè lọ́wọ́ ẹlòmíì nípa eré ìmárale tí wọ́n máa ń ṣe.—Òwe 20:18.
Ó yẹ kó o ní ìṣètò kan pàtó. Ní àfojúsùn, kó o sì máa kọ àṣeyọrí tó o ṣe sílẹ̀ kíyẹn lè fún ẹ níṣìírí.—Òwe 21:5.
Wá ẹni tí ẹ̀ẹ́ jọ máa ṣeré ìmárale. Tó o bá ní “irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀” á fún ẹ níṣìírí láti máa ṣe é déédéé.—Oníwàásù 4:9, 10.
Fi sọ́kàn pé ìfàsẹ́yìn lè ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ má jẹ́ kó sú ẹ.—Òwe 24:10.
Jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì
Bíbélì gba àwọn ọkùnrin àti obìnrin níyànjú pé kí wọ́n “má ṣe jẹ́ aláṣejù.” (1 Tímótì 3:2, 11) Tórí náà, jẹ́ oníwọ̀ntúnwọ̀nsì tó o bá ń ṣeré ìmárale. Àwọn tó máa ń ṣàṣejù nídìí eré ìmárale sábà máa ń pa ara wọn lára, àṣedànù ló sì máa ń jẹ́. Ọ̀dọ́bìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Julia sọ pé; “Tí ọkùnrin kan bá ní igẹ̀ tó tóbi gan-an, àmọ́ tí kò ní làákàyè, ó burẹ́wà ni.”
Ó tún yẹ kó o yẹra fáwọn ìmọ̀ràn tó máa ń mú kéèyàn túbọ̀ tẹra mọ́ eré ìmárale lọ́nà tó gbòdì, wọ́n lè sọ pé: “Tó bá ti dà bíi pé o fẹ́ kú, ṣe mẹ́wàá sí i.” Irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ lè pani lára, ó sì lè mú kéèyàn má fọkàn sí “àwọn ohun tó se pàtàkì jù” nígbèésí ayé.—Fílípì 1:10.
Láfikún síyẹn, ìmọ̀ràn tó ń mú kéèyàn túbọ̀ tẹra mọ́ eré ìmárale tún lè fa ìrẹ̀wẹ̀sì. Ọ̀dọ́bìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Vera ṣàkíyèsí pé: “Àwọn ọ̀dọ́bìnrin kan máa ń ní fọ́tò àwọn èèyàn tó wù wọ́n kí wọ́n jọ, wọ́n sì máa ń tún fọ́tò náà wò nígbà tí wọ́n bá rẹ̀wẹ̀sì. Àmọ́ tí wọ́n bá wá ríi pé ìrísí àwọn ò jọ tẹni tó wà nínú fọ́tò náà, ìrẹ̀wẹ̀sì máa dé. Ìlera rẹ ló yẹ kó ṣe pàtàkì sí ẹ ju ìrísí rẹ lọ.”