ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Borí Àníyàn?
Kí ló máa ń mú kó o ṣàníyàn?
Ǹjẹ́ bọ́rọ̀ ṣe rí lára àwọn tó sọ̀rọ̀ nísàlẹ̀ yìí ló máa ń rí lára tìrẹ náà?
“Gbogbo ìgbà ni mo máa ń ronú pé: ‘Tó bá ṣẹlẹ̀ pé . . . ?’ ‘Tí jàǹbá ọkọ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí wa ńkọ́?’ ‘Àbí tí ọkọ̀ òfuurufú tí a wọ̀ bá lọ já ńkọ́?’ Mo máa ń ṣàníyàn nípa àwọn nǹkan táwọn èèyàn kì í ronú kàn rárá.”—Charles.
“Gbogbo ìgbà ni mo máa ń ṣàníyàn, ṣe lọ̀rọ̀ mi dà bí nǹkan tó ń yí tí kò kúrò lójú kan. Gbogbo ara ni mo fi ń ṣiṣẹ́ síbẹ̀ kò yọ!”—Anna.
“Táwọn èèyàn bá sọ pé Ọlọ́run bá mi ṣe é tí mo ṣì wà nílé ìwé, mo máa ń rò ó pé, ‘Wọn ò mọ̀ bí wàhálà tí mò ń dojú kọ nílé ìwé ṣe pọ̀ tó!’”—Daniel.
“Ṣe lọ̀rọ̀ mi dà bí iná ààrò tó ń jó tí kò tí ì mọ ìkòkò tí wọ́n máa gbé sórí òun. Mi ò kì í yé ronú lórí kí ló tún fẹ́ ṣẹlẹ̀ báyìí àbí kí ló tún kù tí mo fẹ́ ṣe.”—Laura.
Òótọ́ ọ̀rọ̀: Àsìkò tí Bíbélì pè ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” là ń gbé. (2 Tímótì 3:1) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé bí àwọn àgbàlagbà ṣe ń ṣàníyàn bẹ́ẹ̀ làwọn ọ̀dọ́ náà ń ṣàníyàn.
Ṣé ó burú kí èèyàn máa ṣàníyàn?
Rárá. Kódà, Bíbélì sọ pé ó tọ̀nà kí àwọn èèyàn máa ṣàníyàn nípa bí wọ́n ṣe lè tẹ́ ẹni tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ lọ́rùn.—1 Kọ́ríńtì 7:32-34; 2 Kọ́ríńtì 11:28.
Ká sòótọ́, àníyàn máa ń jẹ́ kéèyàn lè tètè gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o fẹ́ ṣe ìdánwò nílé ìwé lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀. Àníyàn ló máa jẹ́ kó o tètè bẹ̀rẹ̀ sí kàwé láti ọ̀sẹ̀ yìí, ìyẹn sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gba máàkì tó dáa!
Dé ìwọ̀n àyè kan àníyàn máa ń jẹ́ kí èèyàn lè sá fún ewu. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Serena sọ pé “o lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣàníyàn torí pé ohun tí kò tọ́ lò ń ṣe tó sì yẹ́ kó o ṣàtúnṣe kí ẹ̀rí ọkàn rẹ lè mọ́.”— Fi wé Jákọ́bù 5:14.
Òótọ́ ọ̀rọ̀: Ó dáa kó o máa ṣàníyàn tó bá ṣáà ti jẹ́ kó o lè gbé ìgbésẹ̀ lórí ohun tó tọ́.
Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé ohun tí kò tọ́ lò ń rò lọ́kàn bí o ṣe ń ṣàníyàn ńkọ́?
Àpẹẹrẹ: Richard tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] sọ pé: “Ọkàn mi ò kí ń balẹ̀ tí mo bá ronú lórí oríṣiríṣi ohun tó lè ṣẹlẹ̀ téèyàn bá wà lábẹ́ ipò tó nira, tí mi ò bá sì dáwọ́ ìrònú yìí dúró, màá bẹ̀rẹ̀ si ní ṣàníyàn.”
Bíbélì sọ pé, “ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara.” (Òwe 14:30) Àníyàn tún lè fa àìsàn sí èèyàn lára irú bíi, ẹ̀fọ́rí, òòyì, inú rírun, àti kí ọkàn èèyàn máa lù kìkì.
Kí lo lè se tó bá ṣẹlẹ̀ pé àníyàn kì í ṣe ẹ́ láǹfààní kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló ń pa ẹ́ lára?
Ohun tó o lè ṣe
Wò ó bóyá àníyàn tí ò ń ṣe tọ̀nà. “Ọ̀tọ̀ ni kí ojúṣe èèyàn jẹ ẹ́ lógún, ọ̀tọ̀ sì ni kí èèyàn máa ṣàníyàn jù bó ṣe yẹ lọ. Ṣe lọ̀rọ̀ ẹni tó ń ṣàníyàn dà bí ẹni tó ń pọn omi sínú apẹ̀rẹ̀, á kàn máa pọn ọ́n lọ náà ni kò ní kún. Wà á kan máa ṣàníyàn ṣá á ni kò ní yanjú ìṣòro rẹ.”—Katherine.
Bíbélì sọ pé: “Ta ni nínú yín, nípa ṣíṣàníyàn, tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀?”—Mátíù 6:27.
Ohun tí èyí túmọ̀ sí: Kàkà kí àníyàn yanjú ìṣòro rẹ ṣe ló tún máa dá kún un tàbí kó di ìṣòro rẹ.
Má kó ohun tó pọ̀ jù sọ́kàn. “Rò ó wò ná. Ṣé ọ̀la ni ohun tí ò ń ṣàníyàn lé máa yanjú? ṣé oṣù kan ni? ṣé ọdún kan ni? àbí ọdún márùn ún sí ìsinyìí?”—Anthony.
Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Búburú ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó fún un.”—Mátíù 6:34.
Ohun tí èyí túmọ̀ sí: Kò bọ́gbọ́n mu láti máa ronú lórí àwọn ìṣòro tá a lè kojú lọ́jọ́ iwájú tó sì jẹ́ pẹ́ èyí tó pọ̀ jù nínú rẹ̀ ló lè má wáyé.
Kọ́ bí o kò ṣe ní máa ṣe kọjá agbára rẹ. “Ohun tó dára jù ni pé dé ìwọ̀n àyè kan máa múra sílẹ̀ fún àwọn ipò kan pàtó, ṣùgbọ́n máa ní in lọ́kàn pé àwọn ipò míì wà tó kọjá agbára rẹ.”—Robert.
Bíbélì sọ pé: “Eré ìje kì í ṣe ti ẹni yíyára, . . . bẹ́ẹ̀ ni ojú rere kì í ṣe ti àwọn tí ó ní ìmọ̀ pàápàá; nítorí pé ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.”—Oníwàásù 9:11.
Ohun tí èyí túmọ̀ sí: Àwọn ìgbà míì wà tó jẹ́ pé o kò ní lè ṣe nǹkankan sí àwọn ìṣòro rẹ, ṣùgbọ́n o lè yí ojú tó o fi ń wò wọ́n padà.
Máa ronú lórí ohun tó ṣe pàtàkì jù. “Mo ti wá rí i pé ohun tí ìṣòro mi jẹ́ ló yẹ kí n kọ́kọ́ mọ̀ kì í ṣe àwọn nǹkan míì tí kò pọn dandan. Ó yẹ kí n mọ àwọn ìgbésẹ̀ tí mo fẹ́ gbé àti àwọn ohun tí màá fi ṣíwájú.”—Alexis.
Bíbélì sọ pé: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:10.
Ohun tí èyí túmọ̀ sí: Àníyàn kì í bo àwọn kan mọ́lẹ̀ torí wọ́n mọ èyí tó yẹ kí wọ́n fi ṣíwájú nínú àwọn àníyàn wọn.
Bá ẹnì kan sọ̀rọ̀. “Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mọ́kànlá, àníyàn ni mo máa bá délé láti ilé ìwé, àníyàn yìí kan náà ni màá tún gbé lọ sí ilé ìwé lọ́jọ́ kejì. Àwọn òbí mi máa ń fetí sílẹ̀ bí mo bá ṣe ń sọ ohun tó ń ṣe mí. Inú mi ń dùn pé mo wọ́n wà nítòsí mi. Mo lè fọkàn tán wọn ki n sì bá wọn sọ̀rọ̀ fàlàlà. Ó máa ń jẹ́ kí n lè gbara dì fún ọjọ́ kejì.”—Marilyn.
Bíbélì sọ pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.”—Òwe 12:25.
Ohun tí èyí túmọ̀ sí: Àwọn òbí ẹ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ kan lè sọ àwọn ohun tó o lè ṣe láti dín bí o ṣe ń ṣàníyàn kù.
Gbàdúrà. “Bí mo ṣe máa ń gbàdúrà tí mo sì máa ń sọ̀rọ̀ sókè débi tí màá máa fetí ara mi gbọ́ ti ràn mí lọ́wọ́. Ó jẹ́ kì n lè sọ ohun tí àníyàn mi jẹ́ síta dípò tí màá fi ma máa dáa rò lọ́kàn. Ó tún jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà lágbára ju àwọn àníyàn mi lọ.”—Laura.
Bíbélì sọ pé: “Ẹ . . . kó gbogbo àníyàn yín lé [Ọlọ́run], nítorí ó bìkítà fún yín.”—1 Pétérù 5:7.
Ohun tí èyí túmọ̀ sí: Àdúrà gbígbà kìí ṣe ọ̀nà tí a lè gbà yanjú ìṣòro wa fúnra wa. Ó jẹ́ ọ̀nà tí a gbà ń bá Jèhófà Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ní tààràtà, ẹni tó ṣèlérí pé: “Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́.”—Aísáyà 41:10.