Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Jẹ́ Kí Àlàáfíà Máa Wà Láàárín Èmi àti Àbúrò Tàbí Ẹ̀gbọ́n Mi?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Jẹ́ Kí Àlàáfíà Máa Wà Láàárín Èmi àti Àbúrò Tàbí Ẹ̀gbọ́n Mi?

 “Àwọn ọ̀rẹ́ tí ò lè ṣe kí wọ́n má jà”

 Wọ́n máa ń sọ pé “àwọn ọ̀rẹ́ tí ò lè ṣe kí wọ́n má jà” ni àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò. Òótọ́ ni pé wọ́n máa ń nífẹ̀ẹ́ ara wọn, síbẹ̀, ọ̀rọ̀ wọn kì í wọ̀. Ọmọbìnrin ọlọ́dún méjìdínlógún (18) kan tó ń jẹ́ Helena sọ pé, “Àbúrò mi ọkùnrin máa ń múnú bí mi. Ó mọ ohun tó lè ṣe tó máa mú kí orí mi kanrin, ó sì mọ ìgbà tí òun lè ṣe é!”

 Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ làwọn ìṣòro kan, kò tó ohun tá à ń yọ àdá bẹ́. Táwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò bá jọ jókòó sọ̀rọ̀, tí kálukú mọ àyè ẹ̀, kò ní sí ìṣòro. Bí àpẹẹrẹ:

  •   Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò méjì tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin lè máa bára wọn jà torí pé wọ́n jọ ń lo yàrá. Kí ni wọ́n lè ṣe? Kí wọ́n máa fara dà á fúnra wọn, kí kálukú ní àyè tiẹ̀, kó má sì kọjá àyè ẹ̀. Kí wọ́n tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì tó wà nínú Lúùkù 6:​31.

  •   Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò méjì tí wọ́n jẹ́ obìnrin lè máa “yá” aṣọ ara wọn wọ̀ láìgba àṣẹ lọ́wọ́ ara wọn. Kí ni wọ́n lè ṣe? Kí wọ́n jọ jókòó sọ ọ́, kí wọ́n sì jẹ́ kí kálukú mọ àyè ẹ̀. Kí wọ́n tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì tó wà nínú 2 Tímótì 2:​24.

 Láwọn ìgbà míì, ìṣòro àárín tẹ̀gbọ́n-tàbúrò máa ń le jùyẹn lọ, ohun tó sì máa ń yọrí sí kì í dáa. Wo àpẹẹrẹ méjì látinú Bíbélì:

  •   Míríámù àti Áárónì ń jowú Mósè àbúrò wọn, ohun tó sì tìdí ẹ̀ yọ ò dáa. Ka ohun tó wà nínú Númérì 12:​1-​15. Wá bi ara ẹ pé: ‘Kí ni mo lè ṣe kí n má bàa máa jowú àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n mi?’

  •   Inú ń bí Kéènì sí Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀, ìbínú ọ̀hún sì le débi pé Kéènì pa dà pa àbúrò rẹ̀. Ka ohun tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 4:​1-​12. Wá bi ara ẹ pé: ‘Tí ọ̀rọ̀ bá pa èmi àti àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n mi pọ̀, kí ni mo lè ṣe tí inú ò fi ní bí mi ju bó ṣe yẹ lọ?’

 Ìdí méjì tó fi yẹ kó o máa wá àlàáfíà

 Kò sí bó ṣe nira tó fún ìwọ àti àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n rẹ láti gbọ́ ara yín yé, ó kéré tán, ìdí méjì ṣì wà tó fi yẹ kó o máa sapá kí ọ̀rọ̀ yín lè wọ̀.

  1.   Ó fi hàn pé o kì í ṣe ọmọdé mọ́. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Alex sọ pé, “Inú máa ń tètè bí mi sí àwọn àbúrò mi obìnrin méjèèjì. Àmọ́ ní báyìí, mo máa ń ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ pẹ̀lú wọn, mo sì ń ní sùúrù fún wọn. Àgbà ti dé sí mi nìyẹn o.”

     Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá lọ́ra láti bínú pọ̀ yanturu ní ìfòyemọ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́ aláìnísùúrù ń gbé ìwà òmùgọ̀ ga.”​—Òwe 14:29.

  2.   Ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní lọ́jọ́ iwájú. Tó ò bá lè fara da ohun táwọn àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n ẹ ń ṣe sí ẹ, báwo lo ṣe máa wá ṣe é tó o bá níyàwó tàbí tó o lọ ilé ọkọ? Báwo ni wàá ṣe máa ṣe sí ẹni tẹ́ ẹ bá jọ ń ṣiṣẹ́, ọ̀gá ẹ níbi iṣẹ́ tàbí ẹlòmíì tí nǹkan ṣáà pa yín pọ̀?

     Òótọ́ kan rèé: Lọ́jọ́ iwájú, tó ò bá fẹ́ níṣòro pẹ̀lú àwọn èèyàn, ó máa sinmi lórí bó o bá ṣe ń ṣe sí wọn, tẹ́ ẹ sì jọ ń jókòó sọ ohun tó bá ṣẹlẹ̀ láàárín yín. Ìgbà tó o bá sì wà lọ́dọ̀ àwọn òbí ẹ àtàwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò ẹ lo lè fi irú ẹ̀ kọ́ra dáadáa, torí ilé la ti ń kó ẹ̀ṣọ́ ròde.

 Bíbélì sọ pé: “Níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà.”​—Róòmù 12:18.

 Ṣé o fẹ́ ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ọ̀rọ̀ àárín ìwọ àti àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n ẹ lè gún? Ka “Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ,” kó o wá wo ibi tó o lè kọ èrò ẹ sí tó bá àpilẹ̀kọ yìí rìn, a pe àkòrí ẹ̀ ní “Bí Ìwọ àti Àbúrò Tàbí Ẹ̀gbọ́n Ẹ Ṣe Lè Máa Gbọ́ Ara Yín Yé.”