ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Èrò Tí Kò Tọ́?
Irú ojú wo lo fi ń wo ara rẹ?
Eni tó lérò tó dáa
“Mo ń sapá kí n lè láyọ̀ kí n má sì máa tètè bínú. Ó wù mí kí n máa rẹ́rìn-ín músẹ́, kínú mi sì máa dùn lójoojúmọ́.”—Valerie.
Ẹni tó lérò tí ò dáa
“Ohun tó kọ́kọ́ máa ń wá sí mi lọ́kàn nígbà tí nǹkan tó dáa bá ṣẹlẹ̀ ni pé, kò lè jóòótọ́ àbí pé bóyá èèṣì ni.”—Rebecca.
Ẹni tó fara mọ́ bí nǹkan bá ṣe rí gan-an
“Tí mo bá lérò tó dáa nípa nǹkan, tí kò sì rí bí mo ṣe fẹ́, ó máa ń dùn mí gan-an. Tí mo bá sì lérò tí kò dáa, àmọ́ tọ́rọ̀ ò rí bí mo ṣe rò, kò sígbà tí màá láyọ̀. Torí náà, bí mo ṣe jẹ́ ẹni tó máa ń fara mọ́ bí nǹkan bá ṣe rí gan-an máa ń jẹ́ kí n lè lóye bọ́rọ̀ bá ṣe rí gẹ́lẹ́.”—Anna.
Kí nìdìí tó fi ṣe pàtàkì?
Bíbélì sọ pé “ẹni tí inú rẹ̀ ń dùn máa ń jẹ àsè nígbà gbogbo.” (Òwe 15:15) Ó ṣe kedere pé ẹni tó bá ní èrò tó tọ́ nípa ìgbésí ayé máa ń láyọ̀ ju ẹni tó ń lérò tí kò dáa. Yàtọ̀ síyẹn, ẹni tó bá ń ronú lọ́nà tó tọ́ tètè máa ń lọ́rẹ̀ẹ́. Àmọ́, kò sẹ́ni tó máa fẹ́ ṣọ̀rẹ́ ẹni tínú ẹ̀ máa ń bà jẹ́, tó sì máa ń ro èrò tí kò tọ́ nígbà gbogbo .
Síbẹ̀, tó o bá tiẹ̀ máa ń lérò tó dáa, ìyẹn ò ní kó o má láwọn ìṣòro kan nígbèésí ayé. Bí àpẹẹrẹ:
Kò sígbà tó ò ní máa gbọ́ ìròyìn nípa ogun, ìpániláyà tàbí ìwà ọ̀daràn.
Ìṣòro ìdílé lè máa bá ẹ fínra.
Ìwọ náà máa ń ṣàṣìṣe, o sì láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó yẹ kó o borí.
Ọ̀rẹ́ ẹ lè sọ ohun kan tàbí kó ṣe ohun kan tó dùn ẹ́.
Dípò tí wàá fi gbọ́kàn kúrò lórí ìṣòro yìí tàbí tí wàá jẹ́ kó gbà ẹ́ lọ́kàn, ńṣe ni kó o ní èrò tó tọ́ nípa ẹ̀. Tó o bá ń ní èrò tó dáa, kò ní jẹ́ kó o máa ronú lọ́nà tí kò yẹ, wàá lè máa fojú tó tọ́ wo ìṣòro ìgbésí ayé, kò sì ní sú ẹ.
Ohun tó o lè ṣe
Gbà pé o lè ṣàṣìṣe.
Bíbélì sọ pé: “Kò sí olódodo kan láyé tí ń ṣe rere, tí kò lẹ́ṣẹ̀.” (Oníwàásù 7:20, Bibeli Ìròhìn Ayọ̀) Torí pé o máa ń ṣàṣìṣe kò túmọ̀ sí pé o ò wúlò, ńṣe nìyẹn ń jẹ́ kó o mọ̀ pé o ò kì í ṣẹni pípé.
Bó o ṣe lè ní èrò tó tọ́: Sapá kó o lè ṣàtúnṣe àwọn ibi tó o kù sí, àmọ́ má gbàgbé pé o ò kì í ṣẹni pípé. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Caleb sọ pé “Mo máa ń sapá kí n lè gbọ́kàn kúrò lórí àwọn àṣìṣe mi kí n má bàa rẹ̀wẹ̀sì, dípò ìyẹn ṣe ni mo máa ń kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn kí n lè ṣàtúnṣe.”
Má ṣe fara wé ẹlòmíì.
Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí á di agbéraga, kí a má ṣe máa bá ara wa díje, kí a má sì máa jowú ara wa.” (Gálátíà 5:26) Tó o bá ń wo àwọn fọ́tò ibi àpèjẹ tí wọn ò pè ẹ́ sí lórí ìkànnì àjọlò, ńṣe lá máa dùn ẹ́ tínú á sì máa bí ẹ gan-an. Inú tiẹ̀ lè bí ẹ débi pé wàá gbà pé àwọn ọ̀rẹ́ ẹ ò nífẹ̀ẹ́ ẹ.
Bó o ṣe lè ní èrò tó tọ́: Fi sọkàn pé gbogbo àpèjẹ kọ́ ni wọ́n á máa pè ẹ́ sí. Yàtọ̀ síyẹn, kì í ṣe gbogbo ohun tẹ́nì kan jẹ́ la máa ń rí nínú àwọn fọ́tò tí wọ́n máa ń gbé sórí ìkànnì àjọlò. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Alexis sọ pé “Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó dáa nígbésí ayé nìkan làwọn èèyàn sábà máa ń gbé sórí ìkànnì àjọlò, wọn ò kì í gbé àwọn ìṣẹlẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ lárinrin síbẹ̀.”
Jẹ́ kí àlàáfíà jọba nínú ìdílé rẹ.
Bíbélì sọ pé: “Tó bá ṣeé ṣe, nígbà tó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ló wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlááfíà.” (Róòmù 12:18) Kò sí bó o ṣe lè yí ìwà ẹlòmíì pa dà pátápátá, àmọ́ o lè yíwà tìẹ pa dà. O lè pinnu pé wà á jẹ́ ẹlẹ́mìí àlááfíà.
Bó o ṣe lè ní èrò tó tọ́: Má ṣe dá kún ìṣoro tó wà nínú ìdílé rẹ, àmọ́ jẹ́ kí àlááfíà jọba nínú ìdílé rẹ bó ṣe yẹ kó rí láàárín ìwọ àtọ̀rẹ́ ẹ. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Melinda sọ pé “Aláìpé ni gbogbo wa, kò sígbà tá ò ní máa ṣẹ ara wa, àmọ́ ọwọ́ wa ló wà bóyá a máa jẹ́ ẹlẹ́mìí àlááfíà tàbí a ò ní jẹ́ bẹ́ẹ̀.”
Jẹ́ ẹni tó moore.
Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa dúpẹ́.” (Kólósè 3:15) Tó o bá lẹ́mìí ìmoore, wàá lè pọkan pọ̀ sórí àwọn ohun rere tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ẹ dípò tí wàá fi máa ronú nípa àwọn ohun tó ò nífẹ̀ẹ́ sí.
Bó o ṣe lè ní èrò tó tọ́: Mọ ìṣòro tó o ní, àmọ́ máa ronú lórí àwọn ohun rere tó ń ṣẹlẹ̀ láyé ẹ. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Rebecca sọ pé “Mo ni ìwé kan tí mo máa ń kọ àwọn ohun rere tó ṣẹlẹ̀ sí mi lọ́joojúmọ́ sí, kí n lè máa rántí pé bí mo tiẹ̀ níṣòro, àwọn ohun rere wà tó yẹ kí n máa ronú nípa ẹ̀.”
Irú ọ̀rẹ́ wo lo ní?
Bíbélì sọ pé: “Ẹgbẹ́ búburú ń ba ìwà rere jẹ́.” (1 Kọ́ríntì 15:33) Tó bá jẹ́ pé ẹni tó máa ń ṣàríwísí, tó máa ń bú èèyàn tàbí tó máa ń bínú lo yàn lọ́rẹ̀ẹ́, kò sígbà tó ò ní máa hùwà bíi tiwọn.
Bó o ṣe lè ní èrò tó tọ́: Nígbà táwọn ọ̀rẹ́ ẹ bá níṣòro tó le koko, ó lè mú kí wọ́n banú jẹ́, wọ́n sì lè ní ẹ̀dùn ọkàn fúngbà díẹ̀. Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nírú àkókò bẹ́ẹ̀, àmọ́, má ṣe jẹ́ kí ìṣòro wọn bò ẹ́ mọ́lẹ̀. Ọ̀dọ́bìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Michelle sọ pé “Kò yẹ kọ́ jẹ́ àwọn tó máa ń ronú lọ́nà tí kò tọ́ làá máa bá kẹ́gbẹ́.”
Ka púpọ̀ sí i nípa ẹ̀
Bíbélì sọ pé “àkókò tí nǹkan le gan-an, tó sì nira” là ń gbé. (2 Tímótì 3:1) Kò rọrùn kéèyàn lérò tó dáa nínú àyé tó kún fún ìṣòro tá à ń gbé yìí. Ka orí kọkànlá nínú ìwé Bíbélì Kọ́ Wa tí àkórí rẹ̀ sọ pé “Kí Nìdí Tí Ìyà Fi Pọ̀ Láyé?” lórí ìkànnì jw.org.