ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Fara Da Ẹ̀dùn Ọkàn Téèyàn Mi Bá Kú?
Ṣé ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí ẹ kan kú láìpẹ́ yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fara da àdánù náà.
Nínú àpilẹ̀kọ yìí
Ṣé ẹ̀dùn ọkàn mi ò ti máa pọ̀ jù báyìí?
Ẹ̀dùn ọkàn táwọn kan máa ń ní tí èèyàn wọn bá kú máa ń pọ̀ gan-an.
“Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti pé ọdún méjì tí bàbá mi àgbà ti kú, ọjọ́ kan ò lè lọ kí n máa rántí wọn. Gbogbo ìgbà tí mo bá ń sọ̀rọ̀ nípa wọn ni mo máa ń sunkún.”—Olivia.
“Ìyá mi àgbà máa ń fún mi níṣìírí kí ọwọ́ mi lè tẹ àwọn ohun tí mò ń lé, àmọ́ wọ́n kú kí ọwọ́ mi tó tẹ̀ ẹ́. Gbogbo ìgbà tí ọwọ́ mi bá tẹ ohun kan tí mò ń lé ni ẹ̀dùn ọkàn máa ń bá mi torí ìyá mi àgbà tó ti kú.”—Alison.
Bí kálukú ṣe máa ń ṣọ̀fọ̀ máa ń yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ:
“Ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tí ọkọ ẹ̀gbọ́n bàbá mi kú, ṣe ló dà bí àlá lójú mi. Ìgbà àkókó nìyẹn tí ẹni tó sún mọ́ mi máa kú, ṣe ló bá mi lójijì, ó sì dùn mí gan-an.”—Nadine.
“Inú bí mi sí bàbá mi àgbà nígbà tí wọ́n kú torí pé wọn ò tọ́jú ara wọn bó tiẹ̀ jẹ́ pé a máa ń tẹnu mọ́ ọn pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀.”—Carlos.
“Èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin nìkan ni mọ̀lẹ́bí tí kò sí níbẹ̀ nígbà tí bàbá wa àgbà kú. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í dá ara mi lẹ́bi pé mi ò sí níbẹ̀ nígbà tí wọ́n kú.”—Adriana.
“Tọkọtìyàwọ́ kan tó sún mọ́ ìdílé wa kú nínú jàǹbá ọkọ̀. Lẹ́yìn ìgbà náà, ẹ̀rù máa ń bà mí tí ẹnì kan nínú ìdílé wa bá kúrò nílé, torí ó máa ń ṣe mí bíi pé òun náà máa kú.”—Jared.
“Nígbà tí ìyá mi àgbà kú ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, mo kábàámọ̀ pé mi ò lo àkókò tó pọ̀ tó pẹ̀lú wọn kí wọ́n tó ku.”—Julianna.
Téèyàn wa bá kú, ó lè yà wá lẹ́nu, inú lè bí wa, a lè dá ara wa lẹ́bi, ẹ̀rù lè bà wá tàbí kó máa ṣe wá bí àbámọ̀. Kò sóhun tó burú tó bá ń ṣe wá bẹ́ẹ̀. Tọ́rọ̀ tiẹ̀ náà bá rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ẹ̀dùn ọkàn náà á máa dín kù. Ní báyìí ná, kí lo lè ṣe tí ẹ̀dùn ọkàn ẹ bá pọ̀?
Ohun tó o lè ṣe tí ẹ̀dùn ọkàn ẹ bá pọ̀
Sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún ọ̀rẹ́ rẹ kan. Bíbélì sọ pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ dà bí “ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.” (Òwe 17:17) Tó o bá sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ fún ẹnì kan, ìyẹn lè jẹ́ kára tù ẹ́.
“Kò sóhun tó burú téèyàn bá ń ṣọ̀fọ̀ èèyàn ẹ̀ tó kú. Àmọ́, téèyàn bá ń bò ó mọ́ra, ẹ̀dùn ọkàn náà lè má tètè lọ. Ìdí nìyẹn tó fi dáa kéèyàn sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ fún ẹnì kan.”—Yvette.
Máa rántí èèyàn ẹ tó kú. Bíbélì sọ pé “ènìyàn rere láti inú yàrá ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá.” (Lúùkù 6:45, Bíbélì Mímọ́) O lè kọ àwọn nǹkan rere tó o rántí nípa ẹni náà síbì kan tàbí kó o kó àwọn fọ́tò rẹ̀ jọ sínú ìwé kan.
“Mo kọ gbogbo àwọn nǹkan tí ọ̀rẹ́ mi kọ́ mi kó tó kú sílẹ̀, nípa bẹ́ẹ̀ àwọn nǹkan tó ṣe ṣì ń ṣe mí láǹfààní. Bí mo ṣe kọ wọ́n sílẹ̀ ò jẹ́ kí n máa ṣàárò ẹ̀ jù.”—Jeffrey.
Máa tọ́jú ara ẹ. Bíbélì sọ pé ó dáa kéèyàn máa ṣe eré ìmárale. (1 Tímótì 4:8) Rí i pé ò ń jẹ oúnjẹ tó ṣaralóore, ó ń ṣe eré ìmárale, ó sì ń sinmi dáadáa.
“Ìbànújẹ́ lè mú kéèyàn má lè ronú bó ṣe tọ́. Torí náà, o gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ò ń tọ́jú ara ẹ. Máa jẹun, kó o sì máa sùn dáadáa.”—Maria.
Máa ran àwọn míì lọ́wọ́. Bíbélì sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.
“Máa ran àwọn míì lọ́wọ́, pàápàá àwọn tí èèyàn wọn náà ti kú. Ìyẹn á jẹ́ kó o mọ̀ pé àwọn míì náà ní ẹ̀dùn ọkàn tí wọ́n ń bá yí.”—Carlos.
Máa sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ tó o bá ń gbàdúrà. Bíbélì pe Jèhófà Ọlọ́run ní “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Ó tún sọ pé Jèhófà “ń mú àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn lára dá; ó ń di àwọn egbò wọn.”—Sáàmù 147:3.
“Bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó sì fún ẹ lókun. Àwọn ìgbà kan máa wà tí ẹ̀dùn ọkàn ẹ máa pọ̀ gan-an, àmọ́ fọkàn balẹ̀ torí pé Jèhófà kì í fi wá sílẹ̀.”—Jeanette.
Má bọkàn jẹ́ tí ẹ̀dùn ọkàn ẹ kò bá tètè lọ. Rántí pé bí ẹ̀dùn ọkàn ṣe ń rí lára kálukú máa ń yàtọ̀ síra. Bíbélì sọ pé nígbà tí Jékọ́bù rò pé ọmọ òun ti kú, “kò gbà” kí àwọn míì tu òun nínú. (Jẹ́nẹ́sísì 37:35) Torí náà, má jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu tí ẹ̀dùn ọkàn ẹ ò bá tètè lọ.
“Oríṣiríṣi nǹkan ló máa ń mú kí n rántí ẹ̀gbọ́n màmá màmá mi, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) tí wọ́n ti kú.”—Taylor.
Ká sọ pé ẹnì kan kán lẹ́sẹ̀. Kò sí àní-àní pé ìrora yẹn máa pọ̀, ó sì lè pẹ́ díẹ̀ kó tó jiná. Àmọ́, dókítà lè sọ àwọn ohun tẹ́nì náà lè ṣe táá jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ̀ tètè jiná.
Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ náà nìyẹn tẹ́nì kan tó sún mọ́ wa bá kú. Ó máa ń dunni gan-an, ẹ̀dùn ọkàn náà sì lè gba àkókò díẹ̀ kó tó lọ. Torí náà, ṣe sùúrù. Ronú nípa àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, kó o sì ṣiṣẹ́ lórí àwọn èyí tó bá ipò rẹ mù jù lọ.