ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Ṣé Apá Mi Á Ká Àwọn Iṣẹ́ Àṣetiléwá Báyìí?
“Láago kan òru, kéèyàn má tíì sùn, kó máa ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá, kò rọrùn rárá. Bí oorun, bí oorun lá máa ṣèèyàn.”—David.
“Mo ṣì máa ń wà nídìí ìwé láago mẹ́rin ààbọ̀ ìdájí nígbà míì, mo sì gbọ́dọ̀ jí láago mẹ́fà àárọ̀ kí n lè múra ilé ìwé. Kò dẹrùn fún mi rárá!”—Theresa.
Ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá máa ń pọ̀ jù fún ẹ ni? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí máa kọ́ ẹ lọ́gbọ́n tó máa dáa sí i.
Kí nìdí táwọn olùkọ́ fi máa ń fún àwọn ọmọ iléèwé ní iṣẹ́ àṣetiléwá?
Díẹ̀ lára ẹ̀ ni pé, iṣẹ́ àṣetiléwá . . .
máa ṣí ojú àti ọpọlọ ẹ sí ọ̀pọ̀ nǹkan tó ò tíì mọ̀
máa jẹ́ kó o di ẹni tó ṣe é gbara lé
máa jẹ́ kó o lè ṣètò àkókò rẹ dáadáa
máa jẹ́ kó o lóye ohun tí olùkọ́ ń kọ́ ẹ a
“Àwọn olùkọ́ máa ń fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní iṣẹ́ àṣetiléwá torí kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè fi ohun tí wọ́n ti kọ́ dánra wò dípò kó kàn jẹ́ pé ńṣe làwọn ohun tí wọ́n ń kọ́ wọn gba etí ọ̀tún wọlé, tó sì ń gba tòsì jáde.”—Marie.
Ní pàtàkì, ẹ̀kọ́ ìṣirò àti sáyẹ́ǹsì máa jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè yanjú ìṣòro. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ pé, àwọn ẹ̀kọ́ yẹn máa jẹ́ kí ọpọlọ rẹ̀ ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ. Torí náà, iṣẹ́ àṣetiléwá dà bí eré ìmárale fún ọpọlọ rẹ!
Bóyá o gbà pé iṣẹ́ àṣetiléwá máa ṣe ẹ́ láǹfààní àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, o ní láti mọ̀ pé ohun tó yẹ kó o ṣe ni. Ohun kan tó o gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn rèé: Lóòtọ́, o kò lè pinnu bí iṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n máa fún ẹ ṣe máa pọ̀ tó, àmọ́ ó lè má gbà ẹ́ lákòókò tó pọ̀. Jẹ́ ká wo bó o ṣe lè ṣe é.
Ìmọ̀ràn to máa ràn ẹ́ lọ́wọ́
Tó bá jẹ́ pé kò rọrùn fún ẹ láti ṣe àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n ń fún ẹ, má ṣe rò pé òkè ìṣòrò tó ò lè borí ni. Àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Ìmọ̀ràn 1: Múra sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere.” (Òwe 21:5) Rí i dájú pé gbogbo nǹkan tó o fẹ́ ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, kó ní sídìí láti máa dìde káàkiri.
Tún wa ibi tó rọrùn fún ẹ tí wàá ti lè pọkàn pọ̀. Àwọn kan máa ń fẹ́ ibi tó pa rọ́rọ́ tí iná sì wà níbẹ̀. Àwọn míì sì máa ń kúrò nílè wọn, wọ́n tiẹ̀ le lọ sí ilé ìkówèésí.
“Tó o bá ní ìwé tàbí kàlẹ́ńdà tó o fi ń kọ àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá tó o fẹ́ ṣe àti déètì tó o fẹ́ parí wọ́n, wàá lè fọgbọ́n ṣètò àkókò rẹ lọ́nà tó dáa. Tó o bá ń fọkàn sí iṣẹ́ àṣetiléwá tó yẹ kó o ṣè àti ìgbà tó yẹ kó o ṣe é, àníyàn rẹ máa dín kù.”—Richard.
Ìmọ̀ràn 2: Ṣètò iṣẹ́ rẹ. Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ . . . létòlétò.” (1 Kọ́ríńtì 14:40) Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn rẹ̀, pinnu iṣẹ́ àṣetiléwá tó o máa kọ́kọ́ ṣe àtèyí tó máa ṣe tẹ̀ lé e.
Àwọn kan máa ń fẹ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú èyí tó nira. Ó sì máa ń yá àwọn míì lára tí wọ́n bá kọ́kọ́ ṣe àwọn èyí tó rọ̀. Èyí tó bá rọrùn fún ẹ ni kó o ṣe nínú méjèèjì.
“Ó máa ń ṣèrànwọ́ gan-an téèyàn bá níbi tó ń kọ àwọn ohun tó fẹ́ ṣe sí àti bí wọ́n ṣe tò tẹ̀ lé ara wọn. Ìyẹn máa jẹ́ kó o lè ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá lásìkò, kò sì ní kà ẹ́ láyà.”—Heidi.
Ìmọ̀ràn 3: Jára mọ́ṣẹ́. Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa ṣiṣẹ́ kára, ẹ má ṣọ̀lẹ.” (Róòmù 12:11) Má ṣe jẹ́ kí àwọn nǹkan míì gba àsìkò tó yẹ kó o fi ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá mọ́ ẹ lọ́wọ́, láìka bó ti wù kó wù ẹ́ tó.
Àwọn tó ti mọ́ lára láti máa fòní-dónìí-fọ̀la-dọ́la kì í parí iṣẹ́ wọn lásìkò àbí kó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n máa kánjú parí ẹ̀, ìyẹn sì máa ń ṣàkóbá fún ẹ̀kọ́ àti ìṣẹ́ wọn. Ohun tó o lè ṣe tó ò bá fẹ́ kí irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí ẹ ni pé kó o máa tètè ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ.
“Tí mo bá tètè ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá mi ní gbàrà tí mo bá dé láti ilé ìwé tàbí tí mo bẹ̀rẹ̀ sí i ṣiṣẹ́ lórí ohun kan tí wọ́n ní kí ń ṣe láìpẹ́ sígbà tí wọ́n fún mi, ṣe ni ọkàn mi máa ń balẹ̀, ó sì máa ń fún mi láyè láti ṣe àwọn nǹkan míì.”—Serina.
ÀBÁ: Àkókò kan náà ni kó o máa ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ lójoojúmọ́. Ìyẹn máa jẹ́ kó o kóra rẹ níjàánu, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó máa mọ́ ẹ lára.
Ìmọ̀ràn 4: Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn rẹ níyà. Bíbélì sọ pé: “Iwájú rẹ gan-an ni kí o tẹjú mọ́.” (Òwe 4:25) Tó o bá fẹ́ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun, ní pàtàkì àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé, pín ọkàn rẹ níyà nígbà tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́.
Tó bá jẹ́ pé ṣe ló ń ti orí ìkànnì kan bọ́ sí òmíì, tó sì ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́, ó máa gba ìlọ́po méjì àkókò tó yẹ kó o fi parí iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ. Àmọ́ tó o bá pọkàn pọ́, wàá rí i pé o kò ní ṣe wàhálà tó pọ̀, wàá sì tún ráyé ṣeré.
“Ọkàn rẹ̀ ò ní pa pọ̀ tó o bá tan fóònù, kọ̀ǹpútà, àwọn ohun tó o fi ń gbá géèmù àti tẹlifíṣọ̀n sílẹ̀. Ohun tó máa ń ràn mí lọ́wọ́ ni pé mo máa ń pa fóònù, máa sì pa gbogbo ohun èlò ìgbàlódé tó lè pín ọkàn mi níyà tó bá wà nítòsí.”—Joel.
Ìmọ̀ràn 5: Wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí i pé ẹ̀ ń fòye báni lò.” (Fílípì 4:5) Máa fún ara rẹ ní ìsinmi kí iṣẹ́ náà má bàá mú ẹ lómi kọjá bó ṣe yẹ. O lè rìn jáde, o lè gun kẹ̀kẹ́ tàbí kó o sáré.
Lẹ́yìn tó o bá ti ṣe gbogbo ohun tá a gbé yẹ̀ wó yìí, tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ ṣì pọ̀ jù fún ẹ, bá àwọn olùkọ́ rẹ sọ̀rọ̀. Tí wọ́n bá rí i pé, ò ń gbìyànjú lóòótọ́, wọ́n lè pinnu láti dín iṣẹ́ tí wọ́n ń gbé fún ẹ kù.
“Má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ àṣetiléwá sọ ẹ di ẹni tí kò láyọ̀ àtẹni tí gbogbo nǹkan sú. Sa gbogbo ipá rẹ. Àwọn nǹkan kan wà tí kò yẹ kó sọ ẹ́ dìdàkudà, ọ̀kan lára ẹ̀ ni iṣẹ́ àṣetiléwá.”—Julia.
Bi ara rẹ láwọn ìbéèrè yìí:
Àwọn ohun wo ni mo nílò fún iṣẹ́ àṣetiléwá mi?
Àkókò wo ló dáa jù tó yẹ kí ń fi ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá mi?
Ibo ló dáa jù tí màá ti lè pọkàn pọ̀?
Báwo ni mi ò ṣe ní máa fòní-dónìí-fọ̀la-dọ́la?
Àwọn ohun wo ló lè pín ọkàn mi níyà?
Báwo ni mi ò ṣe ní jẹ́ kí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé tàbí àwọn nǹkan míì pín ọkàn mi níyà?
Báwo ni màá ṣe rí i dájú pé mo tètè ń ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá mi láìsì pé ó ń kó mi lọ́kàn sókè?
ÌRÀNNÍLÉTÍ PÀTÀKÌ: Rí i dájú pé o mọ ohun tí olùkọ́ rẹ fẹ́ kó o ṣe nínú iṣẹ́ àṣetiléwá tó fún ẹ. Tí kò bá yé ẹ, béèrè lọ́wọ́ olùkọ́ rẹ kó o tó kúrò nílé ìwé.
a Inú ìwé náà, School Power, látọwọ́ Jeanne Schumm la ti mú àwọn kókó yìí.