ÀWỌN Ọ̀DỌ̀ BÉÈRÈ PÉ
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ìbàlágà?
“Ohun tí ojú àwọn obìnrin máa ń rí tí wọ́n bá ń bàlágà kì í ṣe kékeré. Wọ́n máa ń kojú ìnira, nǹkan ìdọ̀tí tí wọ́n máa ń rí sì máa ń tojú sún wọn. Lọ́rọ̀ kan ṣá, kì í rọrùn fún wọn!”—Oksana.
“Ìgbà míì inú mi á dùn, tó bá yá, inú mi á bà jẹ́. Mí ò mọ̀ bóyá bó ṣe ń ṣe gbogbo ọkùnrin nìyẹn, àmọ́ bó ṣe ń ṣe èmi nìyẹn.”—Brian.
Tó o bá ń bàlágà, ó lè máa dùn mọ́ ẹ, kó sì tún máa dẹ́rù bà ẹ́! Àmọ́ báwo lo ṣe lè kojú rẹ̀?
Kí ni ìbàlágà?
Ìbàlágà jẹ́ ìgbà kan ní ìgbésí ayé èèyàn téèyàn máa ń yára dàgbà di géńdé, tí ìmọ̀lára èèyàn á sì máa yí pa dà. Ìyípadà yìí máa ń lágbára, torí àwọn ẹ̀yà ara rẹ á máa yára dàgbà sí i, àwọn ohun kan á sì máa yí pa dà lára rẹ. Tó bá wá yá, wàá dẹni tó máa lè bímọ.
Àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ọmọ bíbí ló kàn o. Bó o ṣe ń bàlágà á kàn jẹ́ kó o mọ̀ pé o kì í ṣe ọmọdé mọ́ ni, ìyẹn sì lè jẹ́ kó o máa ronú ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ, tàbí kó máa bà ẹ́ nínú jẹ́ nígbà míì.
Ìbéèrè: Ọmọ ọdún wo lo rò pé ó yẹ kéèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí i bàlágà?
8
9
10
11
12
13
14
15
16
Ìdáhùn: Téèyàn bá ti pé ìkankan nínú àwọn ọdún yìí, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà.
A jẹ́ pé kò sídìí fún ẹ láti máa yọ ara ẹ lẹ́nu tó o bá ti ń sún mọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún, tó ò sì tíì máa bàlágà. Má sì jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu tó ò bá tíì pé ọmọ ọdún mẹ́wàá tó o sì ti ń bàlágà. Èèyàn ò lè pinnu ìgbà tóun máa bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà torí ara yàtọ̀ sára.
Ara ẹ máa yí pa dà
Téèyàn bá ti ń bàlágà, ohun tó sábà máa ń tètè kíyè sí ni pé àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ á máa yára dàgbà. Ìṣòro tó kàn wà níbẹ̀ ni pé àwọn ẹ̀yà ara ọ̀hún kì í dàgbà bákan náà, àwọn ibì kan máa ń yára dàgbà tàbí tóbi ju àwọn míì lọ. Torí náà, máà jẹ́ kó ṣàjèjì sí ẹ, bí àpẹẹrẹ, bó o ṣe ń rìn lè fẹ́ máa yí pa dà sí ti tẹ́lẹ̀ torí pé àwọn ẹ̀yà ara kan ti tóbi sí i tàbí gùn sí i. Fọkàn balẹ̀, gbogbo ẹ̀ ṣì máa wà bó ṣe yẹ kó wà.
Àwọn ohun míì tún máa yí pa dà lára ẹ bó o ṣe ń bàlágà.
Lára ọkùnrin:
Ẹ̀yà ìbímọ á máa tóbi sí i
Irun máa hù ní abíyá, abẹ́ àti ojú
Ohùn máa ki
Ara ẹ lè máa dédé dìde, kí àtọ̀ sì dà lára ẹ nígbà tó ò ń sùn lóru
Lára obìnrin:
Ọmú máa tóbi sí i
Irun máa hù ní abíyá àti abẹ́
Nǹkan oṣù á bẹ̀rẹ̀ sí í wá
Lára ọkùnrin àti obìnrin:
Ara ẹ lè fẹ́ máa rùn torí òógùn àti kòkòrò àrùn tó ń fa òórùn.
Àbá: Tó o bá ń wẹ̀ déédéé, tó o sì ń lo lọ́fíńdà tàbí ìpara tó ń dín òórùn kù, ara ẹ ò ní máa rùn.
Ìrorẹ́ á máa yọ sí ẹ lára torí kòkòrò tó ń wo ibi tí òróró ti ń sun lára.
Àbá: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìrorẹ́ kì í lọ bọ̀rọ̀, ó máa dín kù tó o bá ń fọ ojú ẹ déédéé, tó o sì ń lo ìpara ojú tó ń fọ ìdọ̀tí àti òróró.
Ìmọ̀lára àti ìṣesí ẹ máa yí pa dà
Báwọn ẹ̀yà ara ẹ ṣe ń dàgbà sí i, bó o ṣe ń ronú àti bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹ náà á máa yí pa dà. Ìṣesí rẹ tiẹ̀ lè ṣàdédé máa yí pa dà.
“Lọ́jọ́ míì, ẹkún ni màá sun, lọ́jọ́ kejì báyìí, ara mi á yá gágá. Inú lè bí mi nísìnyí o, tó bá fi máa ṣe díẹ̀, inú yàrá ni màá lọ ti ara mi mọ́, tí màá máa ronú.”—Oksana.
Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó ń bàlágà ló máa ń bẹ̀rù tí wọ́n á sì máa ṣọ́ra ṣe, àfi bíi pé gbogbo èèyàn ló ń wò wọ́n tó sì ń ṣọ́ wọn. Èyí tó wá máa ń bọ̀rọ̀ jẹ́ fún wọn ni pé ìrísí wọn ti ń yàtọ̀, àwọn èèyàn á sì máa tètè kíyè sí i!
“Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà, ṣe ni mo máa ń mọ̀ọ́mọ̀ wọ aṣọ tó tóbi, màá wá máa ṣe bí ẹni tó rẹ̀. Lóòótọ́, mo mọ ohun tó fà á tí ara mi fi ń yí pa dà, àmọ́ kò bá mi lára mu rárá, ó máa ń tì mí lójú nígbà míì. Torí bí ara mi ṣe rí látilẹ̀ kọ́ nìyẹn.”—Janice.
Èyí tó ṣeé ṣe kó wá fọba lé e ni ojú tí wàá máa fi wo ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ.
“Mi kì í rò ó pé ṣe làwọn ọkùnrin ń da èèyàn láàmú mọ́. Ọ̀pọ̀ wọn tiẹ̀ ti wá ń wù mí báyìí, kéèyàn yófẹ̀ẹ́ ẹnì kan kì í kúkú ṣe nǹkan bàbàrà. Kódà, ‘ta lò ń fẹ́’ lọ̀pọ̀ èèyàn wá ń sọ kiri.’”—Alexis.
Àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń kíyè sí i pé bí àwọn ṣe ń bàlágà, ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tàwọn lọkàn àwọn máa ń fà sí. Tó bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ ni ẹ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í pẹ́ tírú ìmọ̀lára yẹn fi máa ń pòórá.
“Ọkàn mi bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí àwọn ọkùnrin bíi tèmi torí mo máa ń rí àwọn tó rẹwà jù mí lọ dáadáa nínú wọn. Ìgbà tí mo fi máa dàgbà díẹ̀ sí i ni mo bá tún kíyè sí i pé àwọn obìnrin lọkàn mi ń fà sí. Tọkùnrin tobìnrin lọkàn mi wá ń fà sí. Ìyẹn ti di ìtàn báyìí ṣá!”—Alan.
Ohun tó o lè ṣe
Gbìyànjú láti fi ojú tó tọ́ wò ó. Ká sòótọ́, àwọn ohun kan máa yí pa dà lára ẹ bó o ṣe ń bàlágà, ojú tó o fi ń wo nǹkan àti bọ́rọ̀ ṣe máa ń rí lára ẹ náà máa yí pa dà, àmọ́ ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní. Ọ̀rọ̀ tí onísáàmù náà, Dáfídì sọ tiẹ̀ lè mú kó dá ẹ lójú, ó sọ pé: “Lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu.”—Sáàmù 139:14.
Má fi ara ẹ wé ti ẹlòmíì, kó o sì gbìyànjú láti máà jẹ́ kí bó o ṣe rí gbà ẹ́ lọ́kàn jù. Bíbélì sọ pé: “Ènìyàn . . . ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.”—1 Sámúẹ́lì 16:7.
Máa ṣe eré ìmárale dáadáa, kó o sì máa sinmi. Tó o bá ń sùn dáadáa, o ò ní máa tètè bínú, kò ní máa rẹ̀ ẹ́ jù, o ò sì ní máa fi gbogbo ìgbà sorí kọ́.
Má kàn gbà pé òótọ́ ni gbogbo èrò òdì tó ń wá sí ẹ lọ́kàn.’ Rò ó dáadáa, ṣé lóòótọ́ ni gbogbo èèyàn ń ṣọ́ ẹ? Táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń sọ oríṣiríṣi nǹkan nípa ìrísí ẹ tó ń yí pa dà, ìwọ ronú nípa àǹfààní tó wà nínú bí ìrísí ẹ ṣe ń yí pa dà. Bíbélì sọ pé: “Má fi ọkàn-àyà rẹ sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn lè máa sọ.”—Oníwàásù 7:21.
Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi kó o ní ìbálòpọ̀, kọ́ bó o ṣe lè séra ró. Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa sá fún àgbèrè. . . . Ẹni tí ó bá ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 6:18.
Bá òbí ẹ tàbí àgbàlagbà kan tó ṣe é fọkàn tán sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Lóòótọ́ ó lè kọ́kọ́ ṣe ẹ́ bákàn láti bá wọn sọ̀rọ̀. Àmọ́ o ò ní kábàámọ̀ pé o ṣe é, torí wọ́n máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an.—Òwe 17:17.
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Kì í rọrùn téèyàn bá ń bàlágà. Àmọ́ lásìkò yẹn, wàá dàgbà sí i, bó o ṣe ń ronú àti bí nǹkan ṣe ń rí lára ẹ máa dáa sí i, wàá sì tún lè sún mọ́ Ọlọ́run—1 Sámúẹ́lì 2:26.