ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Ìfẹ́sọ́nà—Apá Kìíní: Ṣó Ti Yẹ Kí N Lẹ́ni Tí Mò Ń Fẹ́?
Nínú àpilẹ̀kọ yìí
Kí ni ìfẹ́sọ́nà?
Àwọn kan máa ń wo ìfẹ́sọ́nà bí ohun ṣeréṣeré. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́sọ́nà” túmọ̀ sí àkókò tí ọkùnrin àti obìnrin kan tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn máa ń wò ó bóyá àwọn máa lè fẹ́ra wọn sílé. Ìdí pàtàkì nìyẹn táwọn méjì kan fi gbọ́dọ̀ máa fẹ́ra sọ́nà, kì í ṣe torí kí wọ́n kàn lè gbádùn ara wọn lásán.
Àkókò ìfẹ́sọ́nà jẹ́ àkókò táwọn méjèèjì máa pinnu bóyá kí wọ́n ṣègbéyàwó tàbí kí wọ́n fòpin sí ìfẹ́sọ́nà náà. Torí náà, fi sọ́kàn pé ọ̀kan nínú ohun tá a sọ yìí ló máa ṣẹlẹ̀ tó o bá ti ń fẹ́ ẹnì kan sọ́nà.
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Tó o bá gbà pé o ti ṣe tán láti lẹ́ni tí wàá máa fẹ́ sọ́nà, á jẹ́ pé o ti ṣe tán láti ṣègbéyàwó nìyẹn.
Ṣó yẹ kó o ti lẹ́ni tí wàá máa fẹ́?
Ìfẹ́sọ́nà lè yọrí sí ìgbéyàwó, torí náà ó yẹ kó o ronú lórí àwọn ìwà tó dáa tó o ní àtàwọn ìwà tí ò dáa tó yẹ kó o ṣàtúnṣe ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí àwọn kókó tó tẹ̀ lé e yìí:
Àjọṣe ìwọ àti ìdílé rẹ. Bó o ṣe ń ṣe sí àwọn òbí, ẹ̀gbọ́n àtàwọn àbúrò ẹ nígbà tínú bá ń bí ẹ náà ni wàá ṣe ṣe sí ẹni tó o bá fẹ́.
Ìlànà Bíbélì: “Ẹ mú gbogbo inú burúkú, ìbínú, ìrunú, ariwo àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín, títí kan gbogbo ohun tó lè ṣeni léṣe.”—Éfésù 4:31.
Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé àwọn òbí, ẹ̀gbọ́n àtàwọn àbúrò mi lè sọ pé mò ń bọ̀wọ̀ fáwọn? Tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín èmi àtàwọn ará ilé mi, ṣé mo máa ń fi sùúrù bá wọn sọ̀rọ̀ àbí ṣe ni mo máa ń gbaná jẹ tí màá sì máa báwọn jiyàn?’
Ìgbatẹnirò. Tẹ́ ẹ bá ṣègbéyàwó, o máa ní láti yááfì àwọn ohun kan kó o lè fi hàn pé o gba ti ẹnì kejì ẹ rò.
Ìlànà Bíbélì: “Kí kálukú máa wá ire ti ẹlòmíì, kì í ṣe ti ara rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 10:24.
Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mi ò kì í rin kinkin mọ́ èrò tèmi nìkan ṣáá? Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ mí sí ẹni tó máa ń gba tàwọn míì rò? Awọn nǹkan wo ni mo ti ṣe tó fi hàn pé mò ń fi ire àwọn míì ṣáájú tèmi?’
Ìrẹ̀lẹ̀. Ọkọ tàbí aya rere máa ń gbà pé òun ṣàṣìṣe, ó sì máa ń tọrọ àforíjì.
Ìlànà Bíbélì: “Gbogbo wa ni a máa ń ṣàṣìṣe lọ́pọ̀ ìgbà.”—Jémíìsì 3:2, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.
Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mo máa ń tètè gbà pé mo ṣàṣìṣe àbí ṣe ni mo máa ń ṣàwáwí? Ṣé mo máa ń gbaná jẹ tí wọ́n bá tọ́ mi sọ́nà?’
Ìnáwó. Tẹ́nì kan bá mọ bí wọ́n ṣe ń ṣọ́wó ná, á mú kí àìgbọ́ra-ẹni-yé dín kù nínú ìdílé.
Ìlànà Bíbélì: “Èwo nínú yín ló máa fẹ́ kọ́ ilé gogoro, tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kó ṣírò ohun tó máa ná an, kó lè mọ̀ bóyá àwọn ohun tó ní máa tó parí ilé náà?”—Lúùkù 14:28.
Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mo máa ń ṣọ́wó ná, àbí ṣe ni mo sábà máa ń jẹ gbèsè? Àwọn nǹkan wo ni mo ti ṣe tó fi hàn pé mo máa ń ṣọ́wó ná?’
Ìjọsìn Ọlọ́run. Tó o bá jẹ́ Ẹlẹ́riì Jèhófà, ó yẹ kó o ní ètò tó o ṣe kó o lè máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì máa lọ sí ìpàdé déédéé.
Ìlànà Bíbélì: “Aláyọ̀ ni àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run.”—Mátíù 5:3.
Bi ara ẹ pé: ‘Ṣé mo máa ń rí i dájú pé mo fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run? Ṣé àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn ni mo fi sípọ̀ àkọ́kọ́, àbí mo máa ń jẹ́ kí àwọn nǹkan míì dí mi lọ́wọ́?’
Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Ọkọ tàbí aya rere ló yẹ kó o jẹ́ sí ẹni tó o bá fẹ́. Tó bá jẹ́ pé irú ẹni tó ò ń sapá láti jẹ́ nìyẹn, ó ṣeé ṣe kíwọ náà pàdé ẹni tó ń wá ọkọ rere àbí aya rere bíi tìẹ.