Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Nǹkan Bá Tojú Sú Mi?

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Nǹkan Bá Tojú Sú Mi?

 Àwọn kan gbà pé kò sóhun tó ń súni tó kí òjò ká èèyàn mọ́lé lọ́sàn-án ọjọ́ kan, kó má lè jáde nílé, kó má sì rí nǹkan kan ṣe. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Robert sọ pé, “Nírú àkókò yẹn, ṣe ni màá kàn jókòó sójú kan, tí mi ò ní mohun tí màá ṣe.”

 Ṣó ti ṣe ẹ́ rí? Tírú ẹ̀ bá ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, àpilẹ̀kọ yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́!

 Ohun tó yẹ kó o mọ̀

  •   Lílo ẹ̀rọ ìgbàlódé lè má ṣèrànwọ́.

     O lè lo Íńtánẹ́ẹ̀tì lóòótọ́ kí ọjọ́ lè tètè lọ, àmọ́ ó lè má jẹ́ kó o ronú dáadáa, á sì jẹ́ kí nǹkan túbọ̀ sú ẹ. Jeremy tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún (21) sọ pé, “Wàá rí i pé ṣe lo kàn ranjú mọ́ fóònù tàbí kọ̀ǹpútà ẹ lásán ni, o ò ní lè dánú rò.”

     Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Elena gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn. Ó ní, “Ó níbi táwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé lè ṣèrànwọ́ dé. Kì í jẹ́ kéèyàn ronú nípa àwọn nǹkan gidi tó ń lọ láyìíká ẹni, torí ẹ̀ ló fi jẹ́ pé tó o bá ṣe ń gbé fóònù ẹ sílẹ̀ báyìí, ṣe ni gbogbo ẹ̀ á túbọ̀ sú ẹ!”

  •   Ojú tó o bá fi wò ó ṣe pàtàkì.

     Ṣé ti pé èèyàn ní nǹkan púpọ̀ láti ṣe túmọ̀ sí pé nǹkan ò lè sú onítọ̀hún? Ó sinmi lórí bó o bá ṣe fẹ́ràn ohun tó ò ń ṣe tó. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń Karen rántí pé: “Iléèwé máa ń sú mi gan-an, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àtàárọ̀ dalẹ́ ni mo máa ń ríṣẹ́ ṣe. Tó ò bá fẹ́ kí nǹkan sú ẹ, àfi kí ọkàn ẹ wà níbi ohun tó ò ń ṣe.”

 Ǹjẹ́ o mọ̀ pé . . . Tó ò bá rí nǹkan ṣe, kì í ṣe ìṣòro, àǹfààní ló jẹ́ láti ronú oríṣiríṣi nǹkan gidi tó o lè ṣe.

Ṣe ni àkókò tó o ní dà bí ilẹ̀ tó lọ́ràá, tó o bá lò ó bó ṣe yẹ, wàá rí àwọn nǹkan tuntun fi ṣe

 Ohun tó o lè ṣe

 Nífẹ̀ẹ́ sí oríṣiríṣi nǹkan. O lè lọ́rẹ̀ẹ́ tuntun tàbí kó o bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ nǹkan tuntun. Ṣèwádìí lórí àwọn nǹkan kan tó ò mọ̀ tẹ́lẹ̀. Nǹkan kì í sábà sú àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sí oríṣiríṣi nǹkan tí wọ́n bá tiẹ̀ dá wà, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ àwọn míì!

 Ìlànà Bíbélì: “Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é.”​—Oníwàásù 9:​10.

 “Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè Mandarin Chinese, bí mo sì ṣe ń fi kọ́ra lójoojúmọ́ ti jẹ́ kí n rí i pé ọjọ́ pẹ́ tí mo ti ṣerú ẹ̀ gbẹ̀yìn. Ó máa ń wù mí kí n ní iṣẹ́ kan tí mò ń ṣe. Ó máa ń jẹ́ kí n pọkàn pọ̀, ó sì máa ń jẹ́ kí n fi àkókò mi ṣe nǹkan gidi.”​—Melinda.

 Mọ ìdí tó o fi ń ṣe nǹkan kan. Tó o bá mọ ìdí tó o fi ń ṣe nǹkan kan, á túbọ̀ wù ẹ́ láti máa ṣe é. Kódà, iṣẹ́ iléèwé ẹ là má fi bẹ́ẹ̀ sú ẹ tó o bá mọ ìdí tó o fi ń ṣe é.

 Ìlànà Bíbélì: “Fún ènìyàn, kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí ó . . . jẹ́ kí ọkàn òun rí ohun rere nítorí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.”​—Oníwàásù 2:​24.

 “Nígbà tó kù díẹ̀ kí n parí iléèwé, wákàtí mẹ́jọ ni mo fi ń kàwé lóòjọ́ torí pé mo ti jẹ gbèsè àwọn ìwé kan to yẹ kí n ti kà sílẹ̀. Àbẹ́ ẹ rò pó máa sú mi? Kò tiẹ̀ sú mi rárá torí mo mọ ohun tí mò ń lé. Ohun tó máa jẹ́ àbájáde ẹ̀ ni mo gbájú mọ́, ìyẹn ọjọ́ tí mo máa kẹ́kọ̀ọ́ yege, òun ló sì ṣí mi lórí tí mo fi tẹra mọ́ ìwé kíkà.”​—Hannah.

 Gba kámú àwọn nǹkan kan tó ò lè yí pa dà. Àwọn iṣẹ́ kan tó máa ń gbádùn mọ́ni pàápàá máa ń gba pé kó o ṣe àwọn nǹkan kan léraléra. Ìgbà míì sì wà táwọn ọ̀rẹ́ tó sún mọ́ ẹ gan-an máa yẹ àdéhùn, tí wọ́n á já ẹ sí kolobo. Dípò kó o wá jẹ́ kíyẹn kó ìbànújẹ́ bá ẹ, gbìyànjú láti fi ojú tó tọ́ wò ó.

 Ìlànà Bíbélì: “Ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ yá gágá a máa jẹ àsè nígbà gbogbo.”​—Òwe 15:15.

 “Ọ̀rẹ́ mi kan sọ fún mi pé kí n máa gbádùn àsìkò tí mo bá dá wà. Ó ní gbogbo wa ló ṣe pàtàkì ká mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà lèèyàn á máa wà láàárín àwọn míì, ìgbà míì máa wà téèyàn máa dá wà. Kì í ṣe torí òní nìkan, torí ọ̀la ni.”​—Ivy.