Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?​—Apá 1: Ohun Tí Ìrìbọmi Túmọ̀ Sí

Ṣé Kí N Ṣèrìbọmi?​—Apá 1: Ohun Tí Ìrìbọmi Túmọ̀ Sí

 Lọ́dọọdún, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ táwọn òbí wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n sì kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ láti kékeré ló máa ń ṣèrìbọmi. Ṣé ìwọ náà ti ń ronú láti ṣèrìbọmi? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ ohun tí ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi túmọ̀ sí.

 Kí ni ìrìbọmi túmọ̀ sí?

 Nínú Bíbélì, ìrìbọmi túmọ̀ sí ríri èèyàn bọ inú omi pátápátá, kì í ṣe wíwọ́n omi séèyàn lára. Bí wọ́n sì ṣe ri ẹni náà bọ inú omi yẹn ní ìtumọ̀ tó ṣe pàtàkì gan-an.

  •   Bí wọ́n ṣe ri ẹni náà bọnú omi nígbà ìrìbọmi fi hàn pé, ẹni náà ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun ò tún ní gbé ìgbésí ayé òun láti ṣe ohun tó wu òun mọ́.

  •   Bí wọ́n ṣe gbé ẹni náà sókè nínú omi fi hàn pé ẹni náà ti bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ọ̀tun, ní ti pé bó ṣe máa ṣe ohun tó mú inú Ọlọ́run dùn ló gbájú mọ́.

 Tó o bá ṣèrìbọmi, ṣe lò ń jẹ́ kó ṣe kedere sí gbogbo èèyàn pé Jèhófà ló láṣẹ láti pinnu ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, o sì ń jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé gbogbo ohun tí Jèhófà fẹ́ ni wàá máa ṣe láìjẹ́ pé ẹnikẹ́ni fipá mú ẹ.

 Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Kí nìdí tó o fi fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé o fẹ́ máa ṣègbọràn sí Jèhófà jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ? Wo 1 Jòhánù 4:19 àti Ìfihàn 4:11.

 Kí ni ìyàsímímọ́ túmọ̀ sí?

 Kó o tó ṣèrìbọmi, ó yẹ kó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Báwo lo ṣe máa ṣe é?

 Gbàdúrà sí Jèhófà níwọ nìkan, ṣèlérí fún un pé títí ayé ni wàá máa sìn ín, wàá sì ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́ kó o ṣe láìka ohun táwọn ẹlòmíì bá ṣe tàbí ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀ sí.

 Ìrìbọmi lo fi ń sọ fáwọn èèyàn pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ìyẹn sì máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ìwọ kọ́ lo ni ara rẹ mọ́ àti pé Jèhófà ló ni ẹ́.​—Mátíù 16:24.

 Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Kí nìdí tí ayé ẹ fi máa dáa sí i tó bá jẹ́ pé Jèhófà ló ni ẹ́? Wo Àìsáyà 48:17, 18 àti Hébérù 11:6.

 Kí nìdí tí ìrìbọmi fi ṣe pàtàkì?

 Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì káwọn tó bá fẹ́ di ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣèrìbọmi. (Mátíù 28:19, 20) Nítorí náà, àìgbọ́dọ̀máṣe ni ìrìbọmi jẹ́ fáwọn Kristẹni. Kódà, Bíbélì sọ pé ó ṣe pàtàkì ká ṣèrìbọmi ká tó lè rí ìgbàlà.​—1 Pétérù 3:21.

 Àmọ́, ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà ló yẹ kó mú kó o ṣèrìbọmi. Ó yẹ kí èrò tìẹ náà rí bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Kí ni màá san pa dà fún Jèhófà lórí gbogbo oore tó ṣe fún mi? . . . Màá ké pe orúkọ Jèhófà. Màá san àwọn ẹ̀jẹ́ mi fún Jèhófà.”​—Sáàmù 116:12-14.

 Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Oore wo ni Jèhófà ti ṣe fún ẹ, báwo lo sì ṣe lè san án pa dà fún un? Wo Diutarónómì 10:12, 13 àti Róòmù 12:1.