ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ò Bá Rọrùn fún Mi Láti Máa Bá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀?
Àpilẹ̀kọ yìí máa sọ̀rọ̀ nípa
Ìdí tó fi yẹ ká máa sọ̀rọ̀ lójúkojú
Àwọn kan máa ń sọ pé kéèyàn fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù rọrùn ju kẹ́èyàn máa sọ̀rọ̀ lójúkojú lọ.
“Ẹyin lohùn, tó bá ti já bọ́, kò ṣe é kó mọ́. Òótọ́ sì ni, torí pé ọ̀rọ̀ téèyàn bá ti sọ, ó ti sọ ọ́ nìyẹn kò dà bí torí ẹ̀rọ tó ṣe é parẹ. Ìyẹn ló sì ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ojúkojú nira.”—Anna.
“Tí mo bá ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀, ohun tó máa ń wá sí mi lọ́kan ni bí mi ò ṣe ní ṣàṣìṣe nínú ohun tí mò ń sọ, àmọ́ mi ò kì í da ara mi láàmú tí mo bá ń fí ọ̀rọ̀ ránṣẹ́, torí mo mọ̀ pé mo lè tún ọ̀rọ̀ náà ṣe tí mo bá ṣàṣìṣe!”—Jean.
Bópẹ́ bóyá, kò sígbà tó ò ní bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣe pàtàkì kó o mọ bí wọ́n ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú tó o bá fẹ́ ní ọ̀rẹ́, tó o bá ń wáṣẹ́ àti tó o bá fẹ́ ní àfẹ́sọ́nà tí àkókò bá tó.
Ká sòótọ́, kò sídìí tó fi yẹ kẹ́rù máa bà ẹ́ láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú. O lè kọ́ bó o ṣe lè máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú, kódà tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ojú máa ń tì ẹ́.
“A kì í mọ̀ ọ́n rìn kí orí má mì, torí náà kò sí bá ò ṣe ní ṣàṣìṣe. Tó o bá ṣàṣìṣe, má sọ ọ́ di bàbàrà.”—Neal.
Bó o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀
Máa béèrè ìbéèrè. Ronú nípa ohun táwọn èèyàn lè nífẹ̀ẹ́ sí, kó o sì fìyẹn bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ. Bí àpẹẹrẹ:
“Ìgbà wo lo gbúròó àwọn ará ilé kẹ́yìn?”
“Ṣé o ti wo fídíò tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde yìí?”
“Ṣé o ti gbọ́ nípa . . . ?”
Ohun míì tún ni pé, o lè ronú nípa nǹkan tíwọ àti ẹni náà jọ máa ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ilé ìwé kan náà lẹ jọ lọ, àbí ibi kan náà lẹ ti jọ ń ṣiṣẹ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, béèrè ìbéèrè tó dá lórí ohun tí ẹ jọ máa ń ṣe.
“Ronú nípa àwọn ìbéèrè tó o nífẹ̀ẹ́ sí tó o má fẹ́ káwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀.”—Maritza.
Ohun tó yẹ kó o ṣọ́ra fún: Má ṣe da ìbéèrè bo ẹni náà tàbí kó o máa bi í láwọn ọ̀rọ̀ ara ẹni. Bí àpẹẹrẹ, kò ní dáa kéèyàn máa béèrè pé, “Kí lohun tó burú jù tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ?” tàbí “Kí nìdí tó fi jẹ́ pé irú aṣọ yìí lo máa ń wọ̀ ní gbogbo ìgbà?” Ìbéèrè kejì yìí lè ṣe ẹni náà bíi pé ṣe lò ń rí sí i.
Má jẹ́ kí ìbéèrè ẹ dà bíi pé ṣe lò ń fọ̀rọ̀ wá ẹni náà lẹ́nu wò. Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni pé tó o bá ti béèrè ìbéèrè, á dáa kíwọ náà sọ èrò ẹ ṣáájú tàbí lẹ́yìn tẹ́ni náà bá dáhùn. Ìyẹn á jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín dà bí ìjíròrò dípò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò.
Ìlànà Bíbélì: “Èrò ọkàn eniyan dàbí omi jíjìn, ẹni tí ó bá ní ìmọ̀ ló lè fà á jáde.”—Òwe 20:5, Yoruba Bible.
Máa fara balẹ̀ tẹ́tí sáwọn èèyàn. Tó o bá fẹ́ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ tó o sì fẹ́ kí ìjíròrò náà tẹ̀ síwájú, ó ṣe pàtàkì kó o máa tẹ́tí sí wọn ju kó o máa sọ̀rọ̀ lọ.
“Mo máa ń rí i pé mo mọ ohun tuntun kan nípa ẹni tí mò ń bá sọ̀rọ̀. Màá sì rí i pé mí ò gbà gbé ohun tá a jọ sọ kí n lè mọ ohun tá a jọ máa sọ nígbà míì.”—Tamara.
Ohun tó yẹ kó o ṣọ́ra fún: Má ṣe da ara ẹ láàmù nípa ohun tó máa sọ. Tó o bá fara balẹ̀ tẹ́tí sí ẹni náà, wàá mọ ohun tó yẹ kó o sọ.
Ìlànà Bíbélì: “Yára láti gbọ́rọ̀ . . . lọ́ra láti sọ̀rọ̀.”— Jémíìsì 1:19.
Jẹ́ káwọn míì rí i pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ ẹ́ lógún. Tí ọ̀rọ̀ ẹni tẹ́ ẹ jọ ń sọ̀rọ̀ bá jẹ ẹ́ lógún, wàá gbádùn ìjíròrò náà.
“Tó o bá jẹ́ kí ẹni tẹ́ ẹ jọ ń sọ̀rọ̀ rí i pé ohun tó ń bá ẹ sọ ṣe pàtàkì sí ẹ, ẹ̀ẹ́ gbádùn ọ̀rọ̀ yín, kódà tójú bá ń tì ẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.”—Marie.
Ohun tó yẹ kó o ṣọ́ra fún: Má tojú bọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀. Tó o bá sọ pé “Aṣọ yìí rẹwà, èló lo rà á?” Irú ìbéèrè yìí lè bí ẹni náà nínú.
Ìlànà Bíbélì: Ẹ máa “wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.”—Fílípì 2:4.
Kí lo lè sọ tó o bá fẹ́ parí ọ̀rọ̀ tíwọ àti ẹnì kan ń sọ? Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Jordan sọ pé, “Sọ ohun tó máa mára tu ẹni náà tẹ́ ẹ bá fẹ́ parí ọ̀rọ̀ yín. O lè sọ pé ‘Inú mi dùn pé a jọ sọ̀rọ̀’ tàbí ‘Mo gbádùn àkókò tá a jọ lò pa pọ̀.’ Àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún yín láti sọ̀rọ̀ nígbà míì tẹ́ ẹ bá ríra.”