Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì

A rọ̀ ẹ́ pé kó o wá ṣèbẹ̀wò sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bẹ́tẹ́lì la sábà máa ń pe àwọn ibí yìí. Àwọn kan lára àwọn ọ́fíìsì yìí ní àwọn àtẹ téèyàn lè wò fúnra ẹ̀.

A Lè Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣèbẹ̀wò Pa Dà: Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àti June 1, 2023 làwọn èèyàn ti láǹfààní láti ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wàá fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí. Jọ̀wọ́, má ṣe wá fún ìbẹ̀wò tí àyẹ̀wò bá fi hàn pé ó ní àrùn Kòrónà, tàbí tó ń ṣe ẹ́ bí òtútù tàbí ibà, tàbí tó o wà pẹ̀lú ẹnì kan tí àyẹ̀wò fi hàn pé ó ní àrùn náà.

Côte d’Ivoire

Rue J-58 - Lot 1758

Deux-Plateaux

3ème tranche, Vallon

ABIDJAN

CÔTE D’IVOIRE

+225 2241-3606

Wíwo Ọgbà Wa Yíká

Monday sí Friday

2:00 ọ̀sán sí 4:00 ìrọ̀lẹ́

Ó máa gba wákàtí kan

Àwọn iṣẹ́ tí à ń ṣe níbẹ̀

À ń túmọ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí èdè Abbey, Anyin (Indenie), Attié, Baoulé, Bété, Dida (Lakota), Gouro, Guéré, Èdè Adití ti Ivorian, èdè Senoufo (Cebaara) àti Yacouba. A tún máa ń sẹ àwọn ìwé pẹlẹbẹ àti àwọn eré Bíbélì, a sì ń gbà wọ́n sílẹ̀ ní oríṣiríṣí èdè.

Wa ìwé pẹlẹbẹ tó ń ṣàlàyé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa jáde.