Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
Nínú ìtàn táwọn èèyàn fẹnu ara wọn sọ yìí, wàá rí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe yí ìgbésí ayé àwọn èèyàn pa dà sí rere káàkiri ayé.
Ayé Tó Nítumọ̀
Jèhófà Ló Bá Wa Tún Ìdílé Wa Tò
Tí àwọn tọkọtaya bá fi ìlànà Bíbélì sílò, wọ́n á lè yanjú ìṣòro èyíkéyìí tí wọ́n ní.
Mo Rí Ọrọ̀ Tòótọ́
Báwo ni ọ̀gá oníṣòwò kan tó rí tajé ṣe ṣe rí ohun kan tó túbọ̀ níye lórí ju ọrọ̀ àti owó lọ?
Juan Pablo Zermeño: Jèhófà Ti Jẹ́ Káyé Mi Nítumọ̀
Ìnira máa ń tánni lókun kì í sì í rọrùn láti gbàgbé bó ṣe muni lómi tó. Láìka ìnira tí Juan Pablo ní nígbà tó wà lọ́mọdé sí, wo bí ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe wá nítumọ̀, tí ìtura dé bá a, tó sì ń láyọ̀.
Ìgbà Wo Ni Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Máa Ṣẹ́gun Ìkórìíra?
Kò rọrùn láti fa ẹ̀tanú tu kúrò lọ́kàn. Wo bí Júù kan àti ará Palẹ́sínì kan ṣe ṣàṣeyọrí.
Awon Idahun Taara Ti Mo Ri Ninu Bibeli Wu Mi Lori Gan-an
Ernest Loedi ri idahun si awon ibeere pataki nigbeesi aye. Awon idahun to se taara ti Bibeli fun un mu ko ni ireti nipa ojo ola.
Ibeere Meta Lo Yi Igbesi Aye Mi Pa Da
Doris Eldred to je oluko ri idahun si awon ibeere re nipa igbesi aye nigba ti akekoo re kan ko o lekoo Bibeli.
Mi Ò Fẹ́ Kú O!
Yvonne Quarrie máa ń bi ara rẹ̀ pé, “Kí nìdí tí mo fi wà láyé?” Ìdáhùn ìbéèrè yìí ló yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà.
Ọ̀pọ̀ Nǹkan Ni Jèhófà Ti Ṣe fún Mi
Ẹ̀kọ́ Bíbélì wo ló ran obìnrin kan tó ń jẹ́ Crystal tí ẹnì kan fipá bá lòpọ̀ nígbà tó wà ní kékeré lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run, tó sì jẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ̀ nítumọ̀?
Ojú Kì í Tì Mí Mọ́
Wo ohun tó jẹ́ kí Israel Martínez lè borí èrò tó ti gbà á lọ́kàn pé òun ò já mọ́ nǹkan kan, tó sì wá dẹni tó níyì.
Èmi àti Bàbá Mi Pa Dà Rẹ́
Mọ ìdí tí Renée fi bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró, tó sì ń mutí àti ohun tó ràn án lọ́wọ́ tó fi jáwọ́, táyé ẹ̀ sì dáa.
Mo Ti Lè Ran Àwọn Míì Lọ́wọ́ Báyìí
Ìjàǹbá burúkú kan ṣẹlẹ̀ sí Julio Corio, ó sì rò pé Ọlọ́run kò rí tòun rò. Ẹ́kísódù 3:7 ràn án lọ́wọ́ láti tún èrò rẹ̀ ṣe.
Mo Fẹ́ Jà fún Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn
Rafika wọ ẹgbẹ́ ajàfẹ́ẹ̀tọ́-ọmọnìyàn kó lè gbógun ti ìwà ìrẹ́jẹ. Àmọ́, ó wá kọ́ nípa ìlérí tó wà nínú Bíbélì nípa àlááfíà àti ìdájọ́ òdodo lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.
“Kò Ṣe Mí Mọ́ Bíi Pé Mo Gbọ́dọ̀ Yí Ayé Yìí Pa Dà”
Báwo ni ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe jẹ́ kí ọ̀gbẹ́ni kan tó máa ń jà fẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn rí ohun tó lè yí ayé yìí pa dà pátápátá?
Mi Ò Gbé Ìbọn Mọ́
Wo bí ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínu Bíbélì ṣe jẹ́ kí Cindy yíwà pa dà kúrò ní tẹni tó máa ń bínú.
Ní Tèmi O, Kò Sí Ọlọ́run
Báwo lẹnì kan tí kò gbà pé Ọlọ́run wà tó sì fara mọ́ ìjọba orí-ò-jorí nígbà ọ̀dọ́ rẹ̀ ṣe wá dẹni tó fẹ́ràn Bíbélì?
Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà—November 2012
Báwo ni obìnrin kan tó ti rọ́wọ́ mú nínú ayé àti onítẹ́tẹ́ kan pẹ̀lú ọkùnrin kan táyé ti sú, ṣe rí ayọ̀ àtọkànwá?
Yí Ẹ̀sìn Pa Dà
“Ohun Tí Ò Yé Mi Pọ̀ Ju Èyí Tó Yé Mi Lọ”
Kí ló jẹ́ kí Mario tó jẹ́ pásítọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì tẹ́lẹ̀ gbà pé òtítọ́ inú Bíbélì làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ni?
Bibeli Dahun Gbogbo Ibeere Mi
Igbagbo ti Mayli Gündel ni ninu Olorun mehe nigba ti baba re ku. Bawo ni igbagbo re se soji to fi wa ni ibale okan?
Bíbélì ni Wọ́n fi Dáhùn Gbogbo Ìbéèrè Mi!
Isolina Lamela jẹ́ mọdá ní ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, ó pa dà dí Kọ́múníìsì, ṣùgbọ́n méjèèjì tojú sú u. Ó pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó fi Bíbélì ràn lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí ayé tó dáá.
Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn Yọ Lọ́kàn Mi
Ó wu Tom pé kó nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó bà á nínú jẹ́ láti rí i pé irọ́ làwọn onísìn fi ń kọ́ni. Báwo ni ohun tó kọ́ nínú Bíbélì ṣe jẹ́ kó ní ìrètí?
“Jèhófà Kò Tíì Gbàgbé Mi”
Obìnrin kan tí kì í fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ṣeré rí ìdáhùn sí ìbéèrè rẹ̀ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí èèyàn bá kú. Kà nípa bí òtítọ́ ṣe yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà.
“Ó Wù Mí Kí N Di Àlùfáà”
Láti ìgbà tí Roberto Pacheco ti jẹ́ ọ̀dọ́ ló ti ń wù ú pé kó di àlùfáà nínú ìjọ Kátólí ìkì. Wo ohun tó yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà.
“Wọ́n Fẹ́ Kí Èmi Fúnra Mi wádìí Láti Mọ Ohun Tí Bíbélì Sọ”
Ó wu Luis Alifonso pé kó di míṣọ́nnárì ẹ̀sìn Mormon. Báwo ni ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe yí ayé rẹ̀ àti àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe ní ìgbésí ayé pa dà?
Oogùn àti Ọtí Líle
“Mi Ò Kì Í Ṣe Ẹrú Ìwà Ipá Mọ́”
Lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, ẹnì kan bi Michael Kuenzle pé, “Ṣé o rò pé Ọlọ́run ló lẹ̀bi ìyà tó ń jẹ aráyé?” Ọjọ́ yẹn layé ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí lójútùú.
Ńṣe Layé Mi Túbọ̀ Ń Bà Jẹ́ Sí I
Solomone ṣí lọ sórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ó rò pé ayé òun á dáa sí i níbẹ̀. Àmọ́ ńṣe ló bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn nílòkulò, ó sì dèrò ẹ̀wọ̀n. Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà?
Mo Di Ọmọọ̀ta
Antonio máa ń hùwà ipá, ó máa ń lo oògùn olóró ó sì máa ń mutí lámujù, àmọ́ nígbà tó yá ó rí i pé ayé òun ò nítumọ̀. Kí ló yí i lọ́kàn pa dà?
Mo Kọ́ Láti Bọ̀wọ̀ fún Àwọn Obìnrin Kí N Sì Mọyì Ara Mi
Joseph Ehrenbogen ka ohun kan nínú Bíbélì tó mú kó yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà pátápátá.
“Mo Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ronú Gidigidi Nípa Ibi Tí Mo Ń Bọ́rọ̀ Ayé Mi Lọ”
Ka bí àwọn ìlànà inú Bíbélì ṣe ran ọkùnrin kan lọ́wọ́ kó lè jáwọ́ nínú àṣà tó ti mọ́ ọn lára, tó sì yí èrò rẹ̀ pa dà kó lè máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.
Ọ̀rọ̀ Ara Mi Sú Mi
Ọ̀mùtí paraku ni Dmitry Korshunov, àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì déédéé. Kí ló mú kó yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà?
Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà—October 2012
Báwo ni àwọn méjì, tí ìwà burúkú bí ọtí àmujù àti lílo òògùn olóró kún ọwọ́ wọn, ṣe jáwọ́ tí wọ́n sì wá di ẹni tó ń láyọ̀?
“Ní Gbẹ̀yìn Gbẹ́yín Mo Ti Wá Ní Ojúlówó Òmìnira”
Wo bí ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe mú kí ọ̀dọ́kùnrin kan jáwọ́ nínú sìgá mímu, lílo oògùn olóró àti ọtí àmujù.
Ìwà Ọ̀daràn àti Ìwà ipá
“Bí Mo Ṣe Ń Hùwà Ọ̀daràn, Tí Mo Sì Lépa Owó Ṣàkóbá fún Mi”
Lẹ́yìn tí wọ́n dá Artan sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, ó wá rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ohun tí Bíbélì sọ nípa ìfẹ́ owó.
“Mi Ò Kì Í Ṣe Òǹrorò Èèyàn Mọ́”
Kí ló mú kí Sébastien Kayira fi ìwà ipá àti òǹrorò tó ń hù tẹ́lẹ̀ sílẹ̀?
“Mò Ń Fi Ẹ̀mí Ara Mi Tàfàlà”
Kí ló mú kí ẹnì kan tó wá láti El Salvador, tó sì wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ìta tẹ́lẹ̀ yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà?
Mo Ti Wá Ní Èrò Tó Dáa Nípa Àwọn Èèyàn
Sobantu kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì, ó sì fi ìgbé ayé oníjàgídíjàgan sílẹ̀. Báyìí, ó ń lọ káàkiri ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn kó lè kọ́ wọn nípa ayé kan tí ò ní sí ìwà ọ̀daràn àtàwọn ọmọọ̀ta mọ́.
Mo Máa Ń Tètè Bínú Gan-an
Ẹnì kan tó wà nínú ẹgbẹ́ ọ̀daràn tẹ́lẹ̀ gbà pé agbára tí Bíbélì ní láti yí ìgbésí ayé ẹni pa dà ló tún ayé òun ṣe dòní. Ó ti wá sún mọ́ Ọlọ́run gan-an.
Inú Mi Kì Í Dùn, Mo Sì Máa Ń Hùwà Ìpáǹle
Kí ló mú kí ọmọ ìta ìlú Mẹ́síkò kan fẹ́ láti yí ìwà rẹ̀ pa dà?
Fún Mi Ní Ayọ̀ àti Ìbàlẹ̀ Ọkàn fún Ọdún Kan Péré
Ohun tó wà nínú 1 Jòhánù 1:9 wọ Alain Broggio lọ́kàn gan-an.
Mo Rò Pé Mò Ń Jayé Orí Mi Ni
Pawel Pyzara máa ń hùwà ipá, ó ń lo oògùn olóró, ó tún ń wá bó ṣe máa dọlọ́rọ̀ nídìí iṣẹ́ amòfin. Ọjọ́ tó bá èèyàn mẹ́jọ jà ni ìgbésí ayé rẹ̀ yí pa dà.
Ìwà Burúkú Ọwọ́ Mi Ń Peléke Sí I
Oníjàgídíjàgan èèyàn ni Stephen McDowell, àmọ́ bí kó ṣe sí níbi tí àwọn ọ̀rẹ́ ti lu èèyàn pa mú kó yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà.
Mo Kekoo Pe Jehofa Je Alaaanu O si N Dari Jini
O ti di baraku fun Normand Pelletier lati maa lu awọn eeyan ni jibiti. Amo nigba to ka ese Bibeli kan to wo o lara, o bu sekun.
Mo Fẹ́ Gba Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Ìwà Ìrẹ́jẹ àti Ìwà Ipá
Antoine Touma gbóná nínú ìjà Kọnfú, àmọ́ Ìwé 1 Tímótì 4:8 tún ayé rẹ̀ ṣe.
Ìbọn Máa Ń Wà Lára Mi Níbikíbi Tí Mo Bá Lọ
Annunziato Lugarà wà nínú ẹgbẹ́ ọmọọ̀ta kan, àmọ́ lílọ tó lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba yí ayé rẹ̀ pa dà.
“Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ló Kórìíra Mi”
Kà nípa bí ọkùnrin oníwà ipá kan ṣe kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì di èèyàn àlàáfíà.
Eré Ìdárayá, Orin àti Eré Ìtura
Jason Worilds: Èèyàn Ò Lè Pàdánù Ohunkóhun Tó Bá Fayé Ẹ̀ Sin Jèhófà
A ò ní kábàámọ̀ láé tá a bá fayé wa sin Jèhófà.
Ó Ṣe Mí Bíi Pé Gbogbo Ohun Tí Mo Fẹ́ Lọwọ́ Mi Ti Tẹ̀
Ọ̀dọ́ ni Stéphane, ọwọ́ ẹ̀ ti mókè, gbajúmọ̀ sì ni, síbẹ̀ náà, kò láyọ̀, ọkàn ẹ̀ ò sì balẹ̀. Báwo ló ṣe wá di ẹni tó ní ayọ̀ tòótọ́, tí ìgbésí ayé ẹ̀ sì nítumọ̀?
Ẹ̀bùn Tó Dáa Jù Tí Mo Gbà Láyé Mi
Kí ló sún ẹni tó jẹ́ ọ̀gá nídìí tẹníìsì gbígbá tó fi di ẹni tó ń wàásù nípa Bíbélì?
“Mo Fẹ́ràn Ìjà Kọnfú Gan-an”
Erwin Lamsfus bi ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan pé: Ǹjẹ́ o ti ronú nípa ìdí tá a fi wà láyé? Ìbéèrè yẹn ló yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà.
Mo Ṣàṣìṣe Lọ́pọ̀ Ìgbà àmọ́ Mo Ṣàṣeyọrí
Báwo ni ọ̀gbẹ́ni kan ṣe jáwọ́ nínú àwòrán ìṣekúṣe tó ti di bárakú fún un, tó sì wá ní ìbàlẹ̀ ọkàn?
Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà—April 2013
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Esa rọ́wọ́ mú láàárín àwọn olórin, ó mọ̀ pé ìgbé ayé ire kọ́ ni òun ń gbé. Wo bí olórin rọ́ọ̀kì onílù dídún kíkankíkan ṣe rí ojúlówó ayọ̀.
Kéèyàn Sin Jìófà Ló Ń Sọni Di Alágbára
Ẹsẹ Bíbélì kan tí Hércules kà ló mú kó dá a lójú pé ó lè yí ìwà ìbínú fùfù rẹ̀ pa dà, kó wá di ẹni tó ń kó èèyàn mọ́ra, tó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn.
Mo Fẹ́ràn Baseball Gan-an!
Eré ìdíje ló gba Samuel Hamilton lọ́kàn jù, àmọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà.
“Ìlérí Párádísè Yí Ìgbésí Ayé Mi Pa Dà”
Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ Ivars Vigulis gbádùn òkìkí àti ògo tó wà nínú fifi alùpùpù díje. Báwo ni ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe tún ayé rẹ̀ ṣe?