Wọ́n Ń Fara Da Ìṣòro
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rí i pé kéèyàn jẹ́ aláìlera tàbí aláàbọ̀ ara kò ní kó má láyọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn.
“Jèhófà Gbà Wá Lọ́wọ́ Ikú”
Gbogbo nǹkan wá tojú sú Sowbhagya, ó pinnu pé òun máa para òun àti ọmọbìnrin òun. Kí ló jẹ́ kó yí ìpinnu ẹ̀ padà, tó sì jẹ́ kó ní nǹkan gidi tó ń fi ayé ẹ̀ ṣe?
DeJanerio Brown: Ẹ̀dùn Ọkàn Bá Mi àmọ́ Kò Borí Mi
Báwo ni Jèhófà ṣe ń ran àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí lọ́wọ́?
Kò Mọ Tara Ẹ̀ Nìkan Láìka Àìlera Tó Ní Sí
Báwo ní Maria Lúcia ṣe ran àwọn míì lọ́wọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó dití tó sì fọ́jú?
Wọ́n Ń Sin Jèhófà Láìka Bí Nǹkan Ṣe Le Tó Lórílẹ̀-Èdè Fẹnẹsúélà
Àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà ń fìtara wàásù, wọ́n sì jẹ́ “orísun ìtùnú” fún ara wọn.
Ó Ń Tu Àwọn Míì Nínú Láìka Àìlera Ẹ̀ Sí
Clodean ò ro ara ẹ̀ pin, ó sì bẹ Ọlọ́run pé kó fún òun lókun kóun lè tu àwọn míì nínú.
Kò Juwọ́ Sílẹ̀ Nígbà Àjálù
Ọdún kẹtàlélógún (23) rèé tí àìsàn ti mú kí ara Virginia rọ jọwọrọ. Àmọ́ ìrétí ọjọ́ iwájú tó ní ń tù ú nínú, ó sì ń jẹ́ kí ọkàn ẹ̀ balẹ̀.
Sísin Ọlọ́run Ni Oògùn Àìsàn Rẹ̀!
Wọ́n bí Onesmus pẹ̀lú àìsàn osteogenesis imperfecta tí kì í jẹ́ kí egungun lágbára. Báwo ni àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe tó wà nínú Bíbélì ṣe ràn án lọ́wọ́?
Bí Mo Tiẹ̀ Jẹ́ Aláìlera, Okun Inú Ń Gbé Mi Ró
Obìnrin kan tó wà lórí kẹ̀kẹ́ arọ máa ń rí “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀.
Jèhófà Fi Àánú Hàn Sí Mi Ju Bí Mo Ṣe Rò Lọ
Félix Alarcón rí nǹkan gidi fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe lẹ́yìn tí ìjàǹbá alùpùpù mú kó rọ lápá àtẹsẹ̀.
Sísún Mọ́ Ọlọ́run Dára fún Mi
Nígbà tí Sarah Maiga pé ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, kò ga ju bó ṣe wà lọ mọ́, àmọ́ ó ń dàgbà sí i nípa tẹ̀mí.
“Tí Kingsley Bá Lè Ṣe É, Èmi Náà Lè Ṣe É!”
Kingsley, tó wá láti orílẹ̀-èdè Siri Láńkà, borí ìṣòro tó ní kó lè ṣe iṣẹ́ tí kò ju ìṣẹ́jú díẹ̀ lọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.
Ọwọ́ Ni Mo Fi Ń Ṣe Gbogbo Nǹkan
Wọ́n bí James Ryan ní afọ́jú, nígbà tó yá, ó di adití. Kí ló mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ nítumọ̀?
Bí Mo Tiẹ̀ Jẹ́ Adití, Mò Ń Kọ́ Àwọn Mí ì Lẹ́kọ̀ọ́
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé adití ni Walter Markin, síbẹ̀ ó rí ayọ̀ àti ìbùkún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.
Oju Jairo—Mu Ko Le Sin Olorun
Inu Jairo maa n dun, igbesi aye re si nitumo laika pe arun inu opolo to le ju lo n ba a finra.
Mo Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Bó Tilẹ̀ Jẹ́ Pé Mi Ò Ní Apá
Ọkùnrin kan ṣèṣe gan-an nínú jàǹbá burúkú kan, síbẹ̀ ó rí ìdí tó fi yẹ kó gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà.